Ni ayé àtijọ́, òbi ni o nfẹ iyàwó fún ọmọ ọkùnrin wọn. Bi òbi bá ri ọmọ obinrin ti o dára ni idile ti o dára, wọn á lọ fi ara hàn lati tọrọ rẹ fún ọmọ wọn ọkunrin. Àṣà yi ti yàtọ̀ ni ayé òde òni, nitori awọn ọmọ igbàlódé kò wo idile tabi gbà ki òbi fẹ́ iyàwó tabi ọkọ fún wọn. Ọkùnrin àti obinrin ti lè má bára wọn gbé – wọn ti lè bi ọmọ, tabi jẹ ọ̀rẹ́ fún igbà pipẹ́ tabi ki wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé, wọn yio fi tó òbi leti bi wọn bá rò pé awọn ti ṣetán lati ṣe ìgbéyàwó.
Mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, jẹ ikan ninu ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ninu ètò igbeyawo ibilẹ̀. Yorùbá ni “Ẹni tó lọ si ilé àna, lọ sọ èdè oyinbo, ni yio túmọ̀ rẹ”, nitori eyi ẹbi ọkọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ìgbéraga ni ilé àna bi ó ti wù ki wọn ni ọlá tó. Ẹbi ọkọ yio tọ ẹbi iyàwó lọ lati fi ara hàn ati lati ṣe àlàyé ohun ti wọn ba wa fún ẹbi obinrin.
Yorùbá ni “A ki lọ si ilé arúgbó ni ọ̀fẹ́”, nitori eyi, ẹbi ọkọ yio gbé ẹ̀bùn lọ fún ẹbi ìyàwó. Ọpọlọpọ igbà, apẹ̀rẹ̀ èso ni ẹbi ọkọ ma ngbé lọ fún ẹbi ìyàwó ṣugbọn láyé òde òni, wọn ti fi pãli èso olómi dipo apẹ̀rẹ̀ èso, ohun didùn, àkàrà òyinbó tabi ọti òyinbó dipò. Kò si ináwó rẹpẹtẹ ni ètò mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, nitori ohun ti ẹbi ọkọ ba di dani ni ẹbi ìyàwó yio gba, ẹbi ìyàwó na yio ṣe àlejò nipa pi pèsè ounjẹ.
Mọ̀ mí, nmọ̀ ẹ́, o yẹ ki o fa ariwo, nitori ki ṣe gbogbo ẹbi lo nlọ fi ara hàn ẹbi àfẹ́-sọ́nà. A ṣe akiyesi pé awọn ti ó wá ni ilú nlá tabi awọn ọlọ́rọ̀ ti sọ di nkan nla. Èrò ki pọ bi ti ọjọ ìgbéyàwó ibilẹ. Ẹ ranti pé ki ṣe bi ẹbi bá ti náwó tó ni ó lè mú ìgbéyàwó yọri. Ẹ jẹ ki a gbiyànjú lati ṣe ohun gbogbo ni iwọntunwọnsin. Eyi ti o ṣe pataki jù ni lati gba ọkọ àti ìyàwó ni ìmọ̀ràn bi wọn ti lè gbé ìgbésí ayé rere.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-03-24 09:30:01. Republished by Blog Post Promoter