Tag Archives: Forgiveness

“Bi eyi ò ṣe, omiran yio ṣe – bi Ọlọrun o pani, ẹnikan ò lè pani”: If this has not happened, something else would – If God does not kill, no one can kill”.

Ìtàn yi dá lori Bàbá ti aládũgbò mọ si “Bàbá Beyioṣe”.  Bàbá yi jẹ onígbàgbọ́, ti ki ja tabi ṣe ãpọn.  O bi ọmọ mẹta ti wọn jọ ngbe nitori iyawo rẹ ti kú. Ni ilé ti o ngbe, ó fi ifẹ hàn si àwọn olùbágbé àti aládũgbò.  Bi Bàbá yi bá fẹ́ la ija yio sọ pé “ẹ má jà, a ò mọ ohun ti Ọlọrun fi ohun ti ẹ ńjà lé lori ṣe, nitori na ‘bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe’.

Ni ọjọ́ kan, ọmọ kú fún obinrin olùbágbélé Bàbá Beyioṣe.  Bàbá tún dé ọdọ obinrin yi lati tu ninu, o sọ fún pe “Bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – ẹ pẹ̀lẹ́, a o mọ̀ ohun ti Ọlọrun fi ṣe”.  Ọrọ ìtùnú yi bi ẹniti o ṣe ọ̀fọ̀ ọmọ ti ó kú ninu tó bẹ gẹ ti o fi gbèrò pe ohun yio dán ìgbàgbọ́ Bàbá Beyioṣe wo nipa wiwo ohun ti yio ṣe ti ọmọ ti rẹ nã bá kú.

SAM_1019

Ogi – Corn starch. Courtesy: @theyorubablog

Ogi – Corn pap. Courtesy: @theyorubablog

Ni òwúrọ̀ ọjọ́ kan, Bàbá Beyioṣe, sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé ohun fẹ ji dé ibikan.  Ó ṣe ètò pé ki wọn mu ògì àti àkàrà ni òwúrọ̀ ọjọ́ na.  Àwọn ọmọ ji, wọn lọ si àrò, wọn po ògì lai mọ pe, obinrin ti ọmọ rẹ ku ti bu májèlé si ògì yi.  Àwọn ọmọ gbé ògì wọlé ṣùgbọ́n wọn dúró de ikan ninu wọn ti ó lọ ra àkàrà.  Nigbati ẹni ti ó lọ ra àkàrà de, ẹ̀gbọ́n àgbà pin àkàrà ṣùgbọ́n ija bẹ silẹ nitori ẹni ti o pin akara ko pin daradara.  Nibi ti wọn ti ńja, ògì ti o jẹ ounjẹ àárọ̀ àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe dànù.  Ori igbe ògì ti ó dànù ni àwọn ọmọ wa nigbati Bàbá Beyioṣe wọlé.  Gẹ́gẹ́ bi iṣe rẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ pé “ẹ má jà, bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – a o mọ ohun ti Ọlọrun fi ṣe”.

Obinrin ti o fi májèlé si ògì, ti o reti ki àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe ó kú, ba jade nigbati ó gbọ́ ohun ti o sọ lati tu àwọn ọmọ rẹ ninu.  Ó jẹ́wọ́ pe nitotọ, onígbàgbọ́ ni Bàbá Beyioṣe nitori ohun ti ohun ṣe, ó wá tọrọ idariji.  Bàbá Beyioṣe dariji, ó fún àwọn ọmọ lówó lati ra ounjẹ miran.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-11-29 23:33:23. Republished by Blog Post Promoter