Yorùbá ní “Ã ò pé kámá jọ Baba ẹni timútimú, ìwà lọmọ àlè”. Òwe yi bá ọpọlọpọ Yorùbá tí o nyi orúkọ ìdílé wọn padà nítorí ẹ̀sìn lai yi ìwà padà̀ lati bá orúkọ titun áti ẹ̀sìn mu. Yorùbá ni “ilé lanwo ki a tó sọmọ lórúkọ” nítorí èyí, ọpọlọpọ orúkọ ìdílé ma nbere pẹ̀lú orúkọ òrìṣà ìdílé bi: Ògún, Ṣàngó, Ọya, Èṣù, Ọ̀sun, Ifá, Oṣó àti bẹ̃bẹ lọ. Fún àpẹrẹ: Ògúnlànà, Fálànà, Ṣólànà ti yi padà sí Olúlànà. Ìgbà míràn ti wọn bá lò lára orúkọ àwọn òrìṣa yi wọn a ṣe àyípadà si, fún àpẹrẹ: “Eṣubiyi” di “Èṣúpòfo”.
Njẹ Èṣù pòfo bí, nígbàtí ẹni ti o yi orúkọ padà sí “Èṣúpòfo” njale, ṣiṣẹ́ gbọ́mọgbọ́mọ, purọ́, kówó ìlú jẹ, àti bẹ̃bẹ lọ? Ótì o, Èṣù o pòfo, ìwà lọmọ àlè. Ọmọ àlè ti pọ si nítorí ìwà Èṣu ti pọ si ni ilẹ̀ Yorùbá. Kò sí nkan tí óburú ninú orúkọ yíyí padà, èyí ti o burú ni kí a yí orúkọ padà lai yi ìwà padà. Ẹ fi ìwà rere dípò ìporúkodà.
ENGLISH TRANSLATION
The Yoruba people have a saying that “It is not enough to have a striking resemblance to one’s father, character distinguishes a bastard”. This proverb refers to Yoruba people that replace their family names without matching change of character to go with the name or religion. Another Yoruba saying goes that: “home is observed before naming a child” as a result of this, and so family names are derived with a prefix of the name of the gods and goddesses worshiped in the family such as Ò̀̀̀̀̀̀gun – god of iron/war, Ṣango – god of thunder, Oya – Sango’s wife, Eṣu – Satan, Osun – river goddess, Ifa – Divination, Oso – Wizard etc. For example names like: Ogunlana, Falana, Solana have mostly been changed to “Olulana”. Sometimes, when part of these gods/goddess names are used it is often changed, for example: “Esubiyi – delivered by Satan” is turned “Esupofo – satan has lost”. Continue reading
Originally posted 2015-01-23 10:15:54. Republished by Blog Post Promoter