Tag Archives: Elephant’s Trunk

“Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri” – Ìtàn bi imú Erin ti di gigùn: “Whoever pry unnecessarily, will witness an offensive sight” – The story of how the Elephant’s nose became a trunk.

Ni igbà kan ri, imú Erin dàbi ti àwọn ẹranko tó kù ni, ṣùgbọ́n Erin fi aigbọ tara ẹni, di o ni imú gigùn.  Gbogbo nkan tó nlọ ni ayé àwọn ẹranko yoku ni Erin fẹ tọpinpin rẹ.

Yorùbá ni “Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri”.  Ni ọjọ́ kan, gẹgẹbi iṣe Erin, ó ri ihò dúdú kan, ó ti imú bọ lati tọpinpin lai mọ pe ibẹ̀ ni Òjòlá (Ejò nla ti o ngbe ẹranko tàbi enia mi) fi ṣe ibùgbé.  Bi o ti gbé imú si inú ihò yi ni Òjòlá fa ni imú lati gbe mì.  Erin pariwo lati tú ara rẹ̀ silẹ̀ ṣùgbọ́n Òjòlá kò tu imú rẹ silẹ̀.  Ìyàwó Erin gbọ́ igbe ọkọ rẹ, o fa ni irù lati gbiyànjú ki ó tú ọkọ rẹ silẹ̀.  Bi àwọn mejeeji ti  ṣe ́gbìyànjú tó, ni imú Erin bẹ̀rẹ̀ si gùn si titi o fi já mọ́ Òjòlá lẹ́nu.

Imú Erin di gigùn – Elephant’s nose became a trunk. Courtesy: @theyorubablog.com

Imú gigùn yi dá itiju fún Erin, ó fi ara pamọ́ titi, ṣùgbọ́n nigbati àwọn ẹranko ti ó kù ri imú rẹ gigun wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe ilara irú imú bẹ.  Èébú dọlá, ohun itiju di ohun ilara.

Ọ̀bọ jẹ ẹranko ti ó féràn àti ma ṣe àfarawé gbogbo ẹranko yoku.   Ni ọjọ́ kan, Ọ̀bọ lọ si ibi ihò dúdú ti Erin lọ lati ṣe ohun ti Erin ṣe.  Yorùbá ni “Ohun ojú wa, lojú nri”.  Bi ó ti gbé imú si inú ihò dúdú yi ni Òjòlá gbe mi, ó si kú.  Àwọn ẹranko tó kù fi ti Ọ̀bọ kọ́gbọ́n, nitori eyi ni o fi jẹ imú Erin nikan ló gùn ni gbogbo ẹranko.

Ẹkọ pataki ninu itàn yi ni pe “àfarawé” lè fa àkóbá bi: ikú òjijì, àdánù owó àti ara, ẹ̀wọ̀n àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

ENGLISH TRANSLATION

A long time ago, the Elephant’s nose was just normal like that of other animals, but the Elephant for not minding his business became a long nose/hand animal.  The Elephant is always prying at all other animals’ matters.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-12 09:30:01. Republished by Blog Post Promoter