Tag Archives: Elephant

“Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” – “If one lives long enough, one will consume as much meat as an elephant”

Erin - Elephant

Erin – Elephant

Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni.  Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin.

Isọ̀  Eran – Meat Stall. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni “Bi  a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si “Ajẹ̀fọ́”?  Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé “Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù”. Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe.  Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-12 18:29:05. Republished by Blog Post Promoter

“Ọgbọ́n ju agbára”: Ìjàpá mú Erin/Àjànàkú wọ ìlú – “Wisdom is greater than strength”: The Tortoise brought an Elephant to Town

Ni ìlú Ayégbẹgẹ́, ìyàn mú gidigidi, eleyi mu Ọba ìlú bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ fún àwọn ará ìlú nitori kò mọ ohun ti ohun lè ṣe.  Òjò kò rọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, oorun gbóná janjan, nitorina, kò si ohun ọ̀gbìn ti ó lè hù.  Ìrònú àti jẹ àti mun bá gbogbo ará ìlú – Ọba, Olóyè, Ọmọdé àti àgbà.

Yorùbá ni “Àgbà kii wà lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ”, nitori èyí, Ọba sáré pe gbogbo àgbà ìlú àti “Àwòrò-Ifá” lati ṣe iwadi ohun ti ìlú lè ṣe ki òjò lè rọ̀.  Àwòrò-Ifá dá Ifá, ó ṣe àlàyé ẹbọ ti Ifá ni ki ìlú rú.  Ifá ni “ki ìlú mu Erin lati fi rúbọ ni gbàgede ọjà”.

Gẹ́gẹ́bi Ọba-orin Sunny Ade ti kọ́ “Ìtàkùn ti ó ni ki erin ma wọ odò, t’ohun t’erin lo nlọ”.  Ògb́ojú Ọdẹ ló npa Erin ṣùgbọ́n Olórí-Ọdẹ ti Ọba yan iṣẹ́ ẹ mi mú Erin wọ ìlú fún, sọ pé ko ṣẽ ṣe nitori “Ọdẹ aperin ni àwọn, ki ṣe Ọdẹ a mu erin”.  Ọba paṣẹ fún Akéde ki ó polongo fún gbogbo ara ilu pe “Ọba yio da ẹnikẹni ti  ó bá lè mú Erin wọ ìlú fun ìrúbọ yi lọ́lá”.  Ọ̀pọ̀ gbìyànjú, pàtàki nitori ìlérí ti Ọba ṣe fún ẹni ti ó bá lè mu Erin wọ̀lú, wọn sọ ẹmi nu nínú igbó, ọ̀pọ̀ fi ara pa lai ri Erin mú.

Laipẹ, Ìjàpá lọ bà Ọba àti Olóyè pé “ohun yio mú Erin wálé fún ẹbo rírú yi”.  Olú-Ọdẹ rẹrin nigbati o ri Ìjàpá, ó wá pa òwe pé “À nsọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú”.  Olú-Ọdẹ fi ojú di Àjàpá, ṣùgbọ́n Ìjàpá kò wo bẹ̀, ó fi ọgbọn ṣe àlàyé fún Ọba.  Ọbá gbà lati fún Ìjàpá láyè lati gbìyànjú.

Ìjàpá lọ si inú igbó lati ṣe akiyesi Erin lati mọ ohun ti ó fẹ́ràn ti ohun fi lè mu.  Ìjàpá ṣe akiyesi pé Erin fẹ́ràn oúnjẹ dídùn àti ẹ̀tàn.  Nigbati Ìjàpá padá, o ṣe “Àkàrà-olóyin” dání, o ju fún Erin ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sọ ohun ti ó báwá pé “àwọn ará ìlú fẹ ki Erin wá jẹ Ọba ìlú wọn nitori Ọba wọn ti wọ Àjà”.  Àjàpá pọ́n Erin lé, inú ẹ̀ dùn, ohun naa rò wi pé, pẹ̀lú ọ̀la ohun nínú igbó o yẹ ki ohun le jẹ ọba.  Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọba àti ará ìlú, wọn ṣe gbogbo ohun ti Ìjàpá ni ki wọ́n ṣe.    Ìjàpá àti ará ìlú mu Erin wọ ìlú pẹ̀lú ọpọlọpọ àkàrà-olóyin, ìlù, ijó àti orin yi:

Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀   ) lẹ meji
Ìwò yí ọ̀la rẹ̃,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀,
Agbada á má ṣe wéré,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Ààrò á máa ṣe wàrà,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀    ) lẹ meji

You can also download a recital by right clicking this link: Erin ká relé kó wá jọba

Inú Erin dùn lati tẹ̀ lé ará ìlú, lai mọ̀ pé jàpá ti gba wọn ni ìmọ̀ràn lati gbẹ́ kòtò nlá ti wọ́n da aṣọ bò bi ìtẹ Ọba.  Erin ti wọ ìlú tán, ó rí àga Ọba níwájú, Ìjàpá àti ará ìlú yi orin padà ni gẹ́rẹ́ ti ó fẹ́ lọ gun àga Ọba:

A o merin jọba
Ẹ̀wẹ̀kún, ẹwẹlẹ ……

You can also download a recital by right clicking this link: A o merin jọba

Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-27 09:10:22. Republished by Blog Post Promoter

Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù: Shamelessness is the king of all Vices

Gopher Tortoise

Ìjàpá ọkọ Yáníbo – Tortoise the husband of Yanibo

Gbogbo Ẹranko  - Group of Animals

Gbogbo Ẹranko – Group of Animals

Gbogbo Ẹranko (Ajá, Àmọ̀tẹ́kùn, Ẹkùn, Kìnìún, Ọ̀bọ, Akátá, Ológbò, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ìjàpá/Àjàpá àti bẹ̃bẹ lọ) kó ara jọ lati gbèrò lórí àlébù tí wọ́n rí lára ìyàwó wọn.  Ajá ní ìyawó òhun nṣe àgbèrè, Ẹkùn ní ìyàwó òhun nṣe àfojúdi,  Ológbò ní ìyàwó òhun njale, Ọ̀bọ ní ìyàwó òhun lèjàjù àti bẹ̃bẹ lọ.  Àwọn Ẹranko yókù ṣe àkíyèsí wípé,

Àjàpá/Ìjàpá kàn mi orí ni lai sọ nkankan ju un!

Kìnìún wa bèrè lọ́wọ́ Ìjàpá wípé ṣe Yáníbo (ìyàwó Ìjàpá) kòní àlébù ni?  Àjàpá/Ìjàpá dìde ó wá fọhùn wípé gbogbo àlébù ti gbogbo wọn sọ nípa ìyàwó wọn kéré lára ti ìyàwó ohun nítorí “Yáníbo kò ní ìtìjú”.   Ẹni ti kó ni ìtìjú a jalè, a purọ́, a ṣe àgbèrè, a ṣe àfojúdi àti bẹ̃bẹ lọ.

Ni Ìlúọba, bi Òṣèlú bá ṣe ohun ìtìjú bi: àgbèrè, jalè, gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bi wọn bá ka mọ tàbí kó rò wípé aṣírí fẹ́ tú, á gbé ìwé sílẹ̀ pé òhun kò ṣe mọ nítorí ki ipò òhun má ba di ìdájọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n apàniyàn, olè, alágbèrè àti bẹ̃bẹ lọ., pọ nínú Òṣèlú Nigeria nítorí wọn kò ni ìtìjú.  Ipò Òṣèlú tiwọn fún wọn láyè lati ni àlébù àti lati tẹ ìdájọ́ mọ́lẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni “Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù” gba èrò lati ri wípé ará ìlú dìbò fún Afínjú Òṣèlú kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe nkan  tí aláìnítìjú Òṣèlú ti bàjẹ́.

ENGLISH TRANSLATION

All the animals (Dog, Panther, Leopard, Lion, Monkey, Jackal, Cat, Donkey/Ass, Tortoise etc.) gathered together to discuss the vices they noticed in their wives.   Dog’s wife was said to be committing adultery, Leopard’s wife was insolent, Cat’s wife was stealing, while Monkey’s wife was quarrelsome etc.

All the animals noticed that there was no comment from the Tortoise other than nodding and sighing.  The Lion then asked what Yanibo (Tortoise’s wife) vice was?  The Tortoise rose up and said to the other animals that all the vices they have mentioned could not be compared with his wife’s only vice because “Yanibo has no shame”.

In the United Kingdom, when a Politician commits any act of shame like adultery, stealing, taking bribe, on or before he/she is caught would resign in order not to perverse the cause of justice but killers, thieves, adulterers etc. are common among the Nigerian Politicians because they have no shame.  They use their position to perverse the cause of justice.

This Yoruba Folklore that depicted that “Shamelessness is the king of all Vices” is worthy of note for the people to be mindful of the kind of Politician by casting their votes to elect “Decent” Politicians to repair what the” Shameless” ones has destroyed.

Share Button

Originally posted 2014-05-13 10:15:03. Republished by Blog Post Promoter