Ni ayé igbà kan, ọ̀gbẹlẹ̀ wa ni ilú àwọn ẹranko, nitori ọ̀dá òjò fún igbà pi pẹ́. Ọ̀gbẹlẹ̀ yi fa ìyàn, wọn kò ri omi mu tàbi wẹ̀. Eleyi mú ki gbogbo ẹranko (Kìnìún, Ẹkùn, Erin, Ẹfọ̀n, Àgbọ̀nrín, Òkété, Ehoro, Ọ̀kẹ́rẹ́, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Àjàpá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ) pé jọ lati kó ọgbọ́n pọ̀ bi àwọn yi o ṣe ri omi. Wọn yan Kìnìún ni Alaga, Ẹkùn jẹ́ igbá keji, Erin jẹ́ Baálẹ̀.
Yorùbá sọ pé “A sọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú”, Àjàpá binú kúrò ni ìpàdé nitori wọn kò yan ohun si ipò Alaga. Àwọn ẹranko yoku mba ìpàdé lọ, oníkálùkù mú ìmọ̀ràn wá, Àgbọ̀nrín ni ki wọn ṣe ètùtù si Òriṣà-Omi, Òkété ni ki wọn lo ọgbọ́n àti agbára ti Ọlọrun fún wọn, lati gbẹ́ ilẹ̀ jínjìn si ojú odò ti ó ti gbẹ. Lẹhin àpérò, wọn gba ìmọ̀ràn ti Òkété múwá, wọn gbẹ́ ojú odò titi wọn fi ri omi.
Bi iroyin pé wọn ti ri omi ti kàn, Àjàpá ti kò bá wọn ṣiṣẹ́ nitori ibinú, o gbìmọ̀ bi ohun yi o ti ṣe ẹ̀rù ba àwọn ẹranko yoku ni idi odò, ki ohun lè ri àyè dá pọn omi. Ó sọ ara rẹ di Ànjọ̀nú, ó so agbè púpọ̀ pẹ̀lú okùn ti yio fi pọn omi mọ́ gbogbo ara, ó ji lọ idi odò lati dá nikan pọn omi. Ó bẹ̀rẹ̀ si kọrin:
Bi mba bérin lódò ma tẹ ẹ …… Kàndú
Bi mo bẹ́fọ̀n lódò ma tẹ ẹ ……. Kàndú
Kan, kan, kan, kàndú Continue reading
Originally posted 2014-09-12 10:53:56. Republished by Blog Post Promoter