Tag Archives: diaspora

Àjùmòbí kò kan tãnu… Same parentage does not compel compassion…

Ajumomobi o ko ti anu

Same parentage does not compel compassion.

Òwe Yorùbá ní “Àjùmòbí kò kan tãnu, ẹni Olúwa  bá rán síni ló nṣeni lõre”.  Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l’Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé.

Yorùbá ní “Òṣìṣẹ́ wa lõrun, abáni náwó wà níbòji”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí wọnyi, ma mba ẹni tí o nṣiṣẹ ka owó lai rò wípé ẹni tí ó nṣiṣẹ yi, nlãgun lati rí owó.  Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l’Ókè-Òkun/Ìlú-Òyìnbó nṣe nínú òtútù.  Fún àpẹrẹ: níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ̃bẹ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l’Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn.

Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba.  Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí.  Ẹbí tóní owó tàbí gbé Òkè-òkun lè fi ojú ãnu ṣe ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ki ṣe iṣẹ́ ẹni bẹ̃ lati gbé ẹrù ẹlẹ́rù.   Ẹjẹ́ ká rántí òwe yi wípé “Àjùmọ̀bí kò kan tãnu, ẹni Olúwa bá rán síni ló nṣeni lõre”, nítorí aladugbo, àjòjì, ọ̀rẹ́, àti bẹ̃bẹ lọ, lè ṣeni lãnu bí Olúwa bá rán wọn.

ENGLISH TRANSLATION

A Yoruba saying goes that “same parentage does not compel compassion, only those sent by God show compassion”.  This proverb can be used to advice those dependent on family member.  Many dependents think it is a right for rich or family members living abroad to carry their responsibilities. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-18 18:00:26. Republished by Blog Post Promoter