A lè lo òwe yi lati ṣe ikilọ̀ fún ẹni tó fẹ́ lọ si Òkè-òkun (Ìlu Òyìnbó) lọ́nà kọ́nà lai ni àṣẹ tàbi iwé ìrìnà. Bi ẹbi, ọ̀rẹ́ tàbi ojúlùmọ̀ tó mọ ewu tó wà ninú igbésẹ̀ bẹ ẹ bá ngba irú ẹni bẹ niyànjú, a ma binú pé wọn kò fẹ́ ki ohun ṣoriire.
Bi oúnjẹ ti pọ̀ tó ni ààtàn fún òròmọ adìẹ bẹni ewu pọ̀ tó, nitori ààtàn ni Àṣá ti ó fẹ́ gbé adìẹ pọ si. Bi ọ̀nà àti ṣoriire ti pọ̀ tó ni Òkè-òkun bẹni ewu àti ìbànújẹ́ pọ̀ tó fún ẹni ti kò ni àṣẹ/iwé ìrìnà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkú sọ́nà, ọ̀pọ̀ ndé ọhun lai ri iṣẹ́, lai ri ibi gbé tàbi lai ribi pamọ́ si fún Òfin nitori eyi, ọ̀pọ̀ wa ni ẹwọn. Lati padà si ilé á di ìṣòro, iwájú kò ni ṣe é lọ, ẹhin kò ni ṣe padà si, nitori ọ̀pọ̀ ninú wọn ti ju iṣẹ́ gidi silẹ̀, òmiràn ti ta ilé àti gbogbo ohun ìní lati lọ Òkè-òkun. Bi irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ṣe npẹ si ni Òkè-òkun bẹni ìtìjú àti padà sílé ṣe npọ̀ si.
Òwe Yorùbá ti ó sọ pé “A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀” yi kọ́wa pé ká má kọ etí ikún si ikilọ̀, ká gbé ọ̀rọ̀ iyànjú yẹ̀wò, ki á bà le ṣe nkan lọ́nà tótọ́.
ENGLISH TRANSLATION
This proverb can be applied to someone struggling at all cost to migrate Abroad/Oversea without a Visa or proper documentation. Even when family, friend or colleague that knows the danger in illegal migration, tries to warn such person of the danger, he/she will be angry of being prevented from prosperity. Continue reading
Originally posted 2014-12-19 09:10:15. Republished by Blog Post Promoter