Èsi ibò ti wọn di ni ilú Amẹ́rikà ni oṣù kọkànlá, ọjọ́ kẹjọ jade ni òru ọjọ́ kẹjọ mọ́jú ọjọ́ kẹsan ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún. Àwọn mẹta ti ó gbé àpóti ibò fún ipò olóri òṣèlú ni, Hillary Clinton, obinrin àkọ́kọ́ lati dé irú ipò bẹ́ ẹ̀ fún ẹgbẹ́ (Democrat), Donald J. Trump, Oniṣòwò nlá ti kò ṣe iṣẹ́ Ìjọba kankan ri fún ẹgbẹ́ (Republican) àti Gary Johnson fún ẹgbẹ́ kẹta (Libertarian).
Èsi ibò yi ya gbogbo àgbáyé lẹ́nu nitori àwọn ọ̀rọ̀ ti Donald Trump (Olóri ẹgbẹ́ GOP) ti sọ siwájú nigbati ti ó polongo lati dé ipò. Àwọn ọ̀rọ̀ iko rira wọnyi lòdi si àwọn obinrin, ẹ̀yà miran ti ó yàtọ̀ si ẹ̀yà rẹ, àlejò, ẹlẹ́sin Mùsùlùmi àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Owe Yoruba so wipe “Bi Ẹlẹ́bọ kò bá peni, Àṣefín kò yẹni”. Donald Trump ò ka gbogbo ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú si nkankan tàbi dárúkọ Nigeria. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wi pé nitori Amẹ́rikà ti nṣe Òṣèlú ti wa ntiwa fún igbalélógòji ọdún, ẹni ti wọn yio yan si irú ipò yi á ni iwà àkójọ àti ẹ̀mi àkóso si onírúurú àwọn enia ti ó wà ni gbogbo àgbáyé.
Òwe Yorùbá ni “Bi èniyàn bá ni kò si irú òhun, àwọn ọlọ́gbọ́n a máa wòye”. Lati igbà ti iròyin ibo ti jade pé Donald J. Trump ló wọlé, gẹ́gẹ́ bi wọn ti nṣe é, àwọn Olóri ilú àgbáyé ló kọ iwé tàbi pè lati ki ku ori ire. Ó ṣe ni laanu wi pé, àwọn tó wà ni ilé aṣòfin Nigeria, àti oriṣiriṣi àwọn Òṣèlú kékeré yókù lo nkọ iwé. Gbogbo ìròyìn lati Nigeria kò ri ọ̀rọ̀ àti ìṣò̀ro ti ó dojú kọ ilú ti wọn sọ mọ, ju ọ̀rọ̀ èsi ibò ni Amẹ́rikà. Eyi kò fi ọgbọ́n han nitori ìyà ti ó njẹ ará ilú Nigeria kọjá ki wọn ma sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari lati ṣe àyipadà kúrò ni iwà ibàjẹ́ ti ó ba ilú jẹ, ki ilú lè tòrò, ki ó si lè pèsè oúnjẹ àti ohun amáyédẹrùn fún ará ilú.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading