Ìtàn ti ó wọ́pọ̀ ni, bi iyá-ọkọ ti burú lai ri ìtàn iyá-ọkọ ti ó dára sọ. Eyi dákún àṣà burúkú ti ó gbòde láyé òde òni, nipa àwọn ọmọge ti ó ti tó wọ ilé-ọkọ tàbi obinrin àfẹ́sọ́nà ma a sọ pé àwọn ò fẹ́ ri iyá-ọkọ tàbi ki iyá-ọkọ ti kú ki àwọn tó délé.
Ni ayé àtijọ́, agbègbè kan na a ni ẹbi má ngbé – bàbá-àgbà, iyá-àgbà, bàbá, iyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, iyàwó àgbà, iyàwó kékeré, ìyàwó-ọmọ, àwọn ọmọ àti ọmọ-mọ. Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀ kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ, ẹbi ti fúnká si ilú nlá àti òkè-òkun nitori iṣẹ́ ajé àti iṣẹ́-ijọba.
Ni ọ̀pọ̀ ọdún sẹhin, iyá kan wà ti a o pe orúkọ rẹ ni Tanimọ̀la ninú ìtàn yi. Ó bi ọmọ ọkùnrin meje lai bi obinrin. Kékeré ni àwọn ọmọ rẹ wà nigbati ọkọ rẹ kú. Tanimọ̀la fi ìṣẹ́ àti ìyà tọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbogbo àwọn ọkùnrin na a si yàn wọn yanjú. Nigbati wọn bẹ̀rẹ̀ si fẹ́ ìyàwó, inú rẹ dùn púpọ̀ pé Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ si dá obinrin ti ohun kò bi padà fún ohun. Ó fẹ́ràn àwọn ìyàwó ọmọ rẹ gidigidi ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ rẹ kó lọ si ilú miran pẹ̀lú ìyàwó wọn nitori iṣẹ́. Àbi-gbẹhin rẹ nikan ni kò kúrò ni ilé nitori ohun ló bójú tó oko àti ilé ti bàbá wọn fi silẹ. Nigbati ó fẹ ìyàwó wálé, inú iyá dùn pé ohun yio ri ẹni bá gbé. Ìyàwó yi lẹ́wà, o si ni ọ̀yàyà, eyi tún jẹ́ ki iyá-ọkọ rẹ fẹ́ràn si gidigidi.
Yorùbá ni “Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni”. Tanimọ̀la kò mọ̀ pé àjẹ́ ni ìyàwó-ọmọ ti ohun fẹ́ràn, ti wọn jọ ngbé yi. Bi Tanimọ̀la bá se oúnjẹ, ohun pẹ̀lú ọmọ àti ìyàwó-ọmọ rẹ ni wọn jọ njẹ ẹ. Bi ìyàwó bá se oúnjẹ, á bu ti iyá-ọkọ rẹ. Kò si ìjá tàbi asọ̀ laarin wọn ti ó lè jẹ ki iyá funra.
Yorùbá gbà pé ohun burúkú ni ki enia jẹun lójú orun. Ni ọjọ́ kan, iyá ké lati ojú orun ni bi agogo mẹrin ìdájí òwúrọ̀, pe ìyàwó-ọmọ ohun ti fún ohun ni oúnjẹ jẹ ni ojú orun. Ìyàwó-ọmọ rẹ kò sẹ́, bẹni kò sọ nkan kan. Ọkọ rẹ kò gba iyá rẹ gbọ. Lati igbà ti iyá ti ké pé ohun jẹ àsáró-iṣu ti ìyàwó-ọmọ ohun gbé fún òhun jẹ lójú orun ni inú rirun ti bẹ̀rẹ̀ fún iyá. Inú rirun yi pọ̀ tó bẹ gẹ ẹ ti wọn fi gbé Tanimọ̀la kúrò ni ilé fún ìtọ́jú. Wọn gbiyànjú titi, kò rọrùn, nitori eyi, Tanimọ̀la ni ki wọn gbé ohun padà lọ si ilé ki ohun lọ kú. Continue reading
Originally posted 2014-11-07 17:41:39. Republished by Blog Post Promoter