Ajá dúró dèmί lọna, fẹrẹ kun fẹ 2ce
Bί ὸ bá dúró dèmί lọna fẹrẹ kun fẹ
Makékéké Olóko á gbọ fẹrẹ kun fẹ
Á gbọ á gbéwa dè, fẹrẹ kun fẹ
Á gbéwa dè, á gbàwá nίṣu fẹrẹ kun fẹ
Ajá dúró dèmί lọna, fẹrẹ kun fẹ 2ce
You can also download a recital by right clicking this link: Ajá dúró dèmί lọna
“Àjàpá fẹ́ kó bá Ajá – Kàkà ki eku májẹ sèsé, á fi ṣe àwàdànu” – “Tortoise tried to implicate the Dog – The rat, even if it can’t eat the grain, would rather waste it”
Ni ayé atijọ, ìyàn mú ni ìlú àwọn ẹranko gidigidi, ti àwọn ẹranko fi ńwá oúnjẹ kiri. Iṣu je oúnjẹ gidi ni ilẹ Yorὺbá. Àjàpá àti Ajá gbimọ̀ pọ, lati lọ si oko olóko lati lọ ji iṣu.
Àjàpá jẹ ara ẹranko afàyà fà, ti ko le sáré bi ti Ajá ṣùgbọ́n o lọgbọn gidigidi. Nίgbàtί Àjàpá́ àti Ajá ti jίṣu ko tán, ajá nsáré tete lọ, ki olóko má ba kawọn mọ.
Yorὺbá ni “Kàkà ki eku májẹ sèsé, á fi ṣe àwàdànu”. Àjàpá́ ri wipe ὸhun o le bá Ajá sáré, ó bá ti orin ikilọ bẹnu kί Ajá ba le dúró de ὸhun ni tipátipá. Bί Ajá ko ba dúró, nitotọ olóko á gbọ igbe Àjàpá́, yio si fa àkóbá fún Ajá. Àjàpá́ ko fẹ dá nìkan pàdánú nίtorί olóko á gba iṣu ti ohun jί kó, á sì fi ìyà jẹ ohun.
Titi di ọjọ́ òni, àwọn èniyàn ti o nhu iwà bi Àjàpá pọ̀, ni pàtàki àwọn Òsèlú. . Ikan ninú ẹ̀kọ́ itàn àdáyébá yi ni, lati ṣe ikilọ fún àwọn ti o nṣe ọ̀tẹ̀, ti o nhu iwà ibàjẹ́ tàbi rú òfin pé ki wọn jáwọ́ ninú iwà burúkú. Ìtàn yί tún dára lati gba èniyàn ni iyànjú wίpé ki a má ṣe nkan àṣίrί si ọwọ́ ẹnikẹni pàtàkì ohun ti ko tọ́ tàbί ti ó lὸdì si ὸfin. Yorὺbà ni “Mo ṣé tàn lówà, kὸ sί mo ṣégbé” bó pẹ bó yá, àṣίrί á tú.
Ẹ̀yin ọmọ Yorὺbá nίlé lóko, ẹ jẹ ká hὺwà otitọ kί á sì pa ὸfin mọ, kί a má ba rί àkóbá pàtàkì ọmọ Yorὺbá nί Òkèokun/Ìlúὸyìnbó.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-11-14 10:15:01. Republished by Blog Post Promoter