Tag Archives: corruption

“Ará Ilú Nigeria: “Fi Ẹ̀tẹ̀ silẹ̀ pa Làpálàpá” – Nigerians are: Ignoring Leprosy for the cure of Ringworm”

Ẹ̀tẹ̀ tó mbá ilú jà ni ‘iwà-ibàjẹ́’.  Ìyà ti ará ilú njẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, ki i ṣe èrè iwà-ibàjẹ́ ọdún kan, ṣùgbọ́n  ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.  Kò si ìfẹ́ ilú, nitori eyi, àwọn oniwà ibàjẹ́ ni àwọn ará ilú nyin bi wọn bá ti ẹ fi èrú kó owó jọ pàtàki ni ilé ìjọ́sìn, wọn kò ri ẹni ba wọn wi.

Ojú Olé Rè é – Looters of Nigeria. Courtesy: @theyorubablog

Ojú Olé Rè é – Looters of Nigeria. Courtesy: @theyorubablog

Fún akiyesi, ilé iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, owó ti Ìjọba àpa-pọ̀ ba pin lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná fún gbogbo ará ilú, ọ̀gá ilé-iṣẹ́ á pin pẹ̀lú àwọn Ìjọba Ológun tàbi Òṣèlú Alágbádá.  Ni bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, nigbati àwọn ọmọ iṣẹ́ ri pé àwọn ọ̀gá ti ó nji owó, kò si ẹni ti ó mú wọn, àwọn na a brẹ̀rẹ̀ si lọ yọ nkan lára ẹ̀rọ ti ó gbé iná wọ àdúgbò lati lè gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ará àdúgbò.  Ará àdúgbò á dá owó ki àwọn òṣiṣẹ́ ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná tó wá tú ohun ti ó bàjẹ́ tàbi ohun ti wọn yọ ṣe.

Kàkà ki ará ilú para-pọ̀ lati wo ẹ̀tẹ̀ san, nipa gbi gbé ogun ti iwà-ibàjẹ́ ni ilé-iṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, onikálùkù bẹ̀rẹ̀ si ṣètò fún ará wọn nipa ri ra ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná ti àwọn Òyinbó ngbe dani nigbati wọn bá fẹ lọ pàgọ́.  Àwọn ẹ̀rọ wọnyi kò lágbára tó lati dipò iná mọ̀nàmọ́ná ti ó yẹ ki Ìjọba pèsè.  Àwọn ará ilú kò ro ìnáwó ti ó kó wọn si, ariwo, àti èéfín burúkú ti ẹ̀rọ yi nfẹ sinú afẹ́fẹ́.  Àwọn ti ó nja ilú lólè ni ó nkó ẹ̀rọ wọnyi wọlé, wọn kò gbèrò ki iná mọ̀nàmọ́ná wa nitori wọn kò ni ri ẹni ra ọjà wọn.   Wọn rò wi pé àwọn lè dá ilé-iṣẹ́ ti ó n pèsè iná mọ̀nàmọ́ná silẹ̀ ti ó lè lo atẹ́gùn, omi, epo rọ̀bì, oòrùn lati pèsè iná ti kò léwu bi ẹ̀rọ́ iná mọ̀nàmọ́ná.

Ẹ̀tẹ̀ ṣòro lati wòsàn ju làpálàpá lọ, ibàjẹ́ ló yára lati ṣe ju lati tú nkan ṣe lọ. O ye ki ará ilú para pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́, lati gbé ogun ti iwà ibàjẹ́ àti àwọn aṣèbàjẹ́, ju pé ki wọn fi ara gbi gbóná kọ ìyà ọgbọ̀n ọdún laarin ọdún kan tàbi meji.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-05-17 21:34:04. Republished by Blog Post Promoter

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ – Everyday is for the thief … a warning to fraudsters

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ, ỌJỌ KAN NI TOLÓHUN”: “EVERYDAY IS FOR THE THIEF, ONE DAY FOR THE OWNER”.

Ní ọjọ Ẹti ọjọ keji lelogun oṣu keji ọdún yi, Ẹrọ amóhùn máwòrán Iluọba (BBC 1) tu asiri ọmọkunrin kan ti o ni iwe ijẹri irina ọmọ Naijeria ni oruko ọtọtọ mẹta ti o fi nlu ìjọba ní jìbìtì gba iranlọwọ ti ko tọ si. O ti gba owó rẹpẹtẹ ki wọn to ri mu.

Ni Ìlú Ọba (United Kingdom) Ìjọba pese ilé fún awọn abirùn ati aláìní ti o jẹ ọmọ onilu ati iranlọwọ miran lati mu ayé dẹrùn fún wọn.  Àwọn àjòjì ti o fi èrú ati irọ gba àwọn iranlọwọ yi, wọn a dẹ tún fi ma yangan titi ọjọ ti olóhun yio fi muwọn.  Irú iwa burúkú bi ka fi èrú gba ohun ti ko tọ wọnyi mba orúkọ jẹ.

Ẹ jẹ ki a fi owé Yorùbá to wipe “Ọjọ gbogbo ni tolè, ọjọ kan ni tolóhun” se ikilo fun iru awọn oníjìbìtì bẹ ere jibiti, nitori bi o ti wu ko pẹ to, ọjọ kan ọwọ òfin a ba iru àwọn bẹ.  Nigbati wọn ba ri wọn mu, wọn a ko ìtìjú ba orúkọ idile ati ìlú wọn.

ENGLISH TRANSLATION

On Friday 22nd February 2013, BBC 1 Television Channel exposed a man with 3 Nigerian Passports in different names that he was using to defraud the Government by collecting benefits that he was not entitled to claim.  He had collected large sums of money before he was caught. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-22 20:58:21. Republished by Blog Post Promoter