Tag Archives: Contentment

“Ìwà bi Ọlọrun pẹ̀lú Ìtẹ́lọ́rùn, Èrè nla ni” – “Godliness with Contentment, is great Gain”

 Ìtẹ́lọ́rùn - Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Ìtẹ́lọ́rùn – Contentment. Courtesy: @theyorubablog

Bi kò bá si ìtẹ́lọ́rùn, kò si ohun ti èniyàn ni ti ó tó.  À i ni ìtẹ́lọ́rùn ló nfa iwà burúkú bi, olè̀ jijà, àgbèrè, ojúkòkòrò, irà-kurà, ijẹ-kújẹ, ìpànìyàn, gbi gbé oògùn olóró àti àwọn àlébù yoku.  Kò si owó ti ẹni ti kò ni ìtẹ́lọ́rùn lè ni, ki ó tó.

Yorùbá ni “Isà òkú ki i yó”, bẹ́ ẹ̀ ló ri fún a lai ni ìtẹ́lọ́rùn, nitori ojoojúmọ́ ni ohun tuntun njade, pàtàki ni ayé oriṣiriṣi ẹ̀rọ igbàlódé àti ẹ̀rọ ayélujára yi.  Fún àpẹrẹ, oriṣiriṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló wà, ti wọn nṣe jade ni ọdọdún, àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ igbàlódé owó iyebiye.  Pẹ̀lú ìṣẹ́ ti ó pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, ọkọ̀ ilẹ́ kò tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú àti Olóri-Ìjọ mọ, ọkọ̀-òfúrufú bi ó ti wọ́n tó, ni wọn nkó jọ.  Nitori eyi, kò si owó ti ó lè tó fún ẹni ti ó bá fẹ́ràn ohun ayé.

Ẹ̀kọ nla ni lati kọ́ ọmọ ni ìtẹ́lọ́rùn lati kékeré.  Ẹni ti ó bá ni ìtẹ́lọ́rùn, ló ni ohun gbogbo, nitori ko ni wo aago aláago ṣiṣẹ́, á lè lo ohun ti ó bá ni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn.

Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, “Ohun ti kò tó loni mbọ̀ wá ṣẹ́kù ni ọ̀la” bi èniyàn bá lè farabalẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION

If there is no contentment, nothing can ever be enough.  Lack of contentment is the root cause of many character disorders, such as stealing, adultery, greed, compulsive shopping, gluttony, killings, drug peddling and other vices.  No amount of money is ever enough for someone who lacks contentment. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-22 16:00:00. Republished by Blog Post Promoter

Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà – Contentment is the Father of Character

Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló bí gbogbo ìwà burúkú bi:  irọ́ pípa, olè jíjà, àgbèrè, ojúkòkòrò àti bẹ̃bẹ lọ.

Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló wà ni ìdí àwọn Oṣèlú àti Olórí Ìjọ ti o nlo owó ìlú tàbi owó ìjọ fún ara wọn dipò ki wọn lõ fún ìlú àti ìjọ.   Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú̀ ilẹ̀ Nigeria á fi ọ̀nà ẹ̀rú wá ipò nítorí àti kó owó ìlú jẹ, wọn ki wúlò fún ìlú ṣùgbọ́n fún ara wọn.  Èyí tó ṣeni lãnu jù ni wípé kò sí owó ti wọn ji tí ó tó, nítorí wípé wọn a ji owó àti ohun ti wọn kò ní lò títí di ọjọ́ ikú àti kó èyí tí wọ́n rò wípé ọmọ wọn kò ní ná tán.

Ibi tí àìní ìtẹ́lọ́rùn burú dé ni orílẹ̀ èdè wa, o ràn àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olórí Ìjọ tí ó yẹ ki o wãsu èrè ìtẹ́lọ́rùn fún àwọn Òṣèlú, ará ìlú àti ọmọ Ìjọ.  Ó ṣeni lãnu wípé ojúkòkòrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olórí Ìjọ ju ti Òṣèlú, ọmọ Ìjọ àti àwọn ẹlẹ́tàn lọ nítorí wọ́n du ipò àti ohun ayé.

Il̀ú á dára si ti àwọn ènia bá lè mú òwe Yorùbá tí ó wípé “Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà” yí lò.

ENGLISH TRANSLATION

Lack of contentment is the root cause of bad character like: lying, prostitution, covetousness etc.

Lack of contentment is behind the source of Politicians and Church Leaders embezzling public fund and congregation’s tithes and offering for their own personal use.  Many Nigerian Politicians would use every crooked means to be elected to any position in politics in order to be in a position to have access to public fund and afterward, they are often useless to their electorate but for themselves.  The most pitiable thing is that they steal the money and things they will never need to their dying day as well as storing up what they think their children would never be able to finish.

The worst side of lack of contentment in our country, there is no difference between the Church Leaders who are supposed to be preaching about the reward of contentment to the Politicians, the people and fraudsters.  It is unfortunate that many Church Leaders are more covetous than Politicians, Church Congregants and Fraudsters, as a result of competing for position and mundane things.

The Country will be better off if the Yoruba adage that said “Contentment is the Father of Character” can be applied.

Share Button

Originally posted 2013-06-25 19:40:35. Republished by Blog Post Promoter