Tag Archives: Christmas

“Àjẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́” – Ìkìlọ̀: ẹ jẹun díẹ̀ – Ẹ kú ọdún o, à ṣèyí ṣè àmọ́dún o – “Eating without looking back, is the cause of disgrace for the Pig” – Caution: eat moderately during the Yuletide.

Iyán àti ẹ̀fọ́ rírò – Pounded Yam and mixed stewed vegetable soup. Courtesy: @theyorubablog

Ni asiko ọdún, pataki, asiko ọdún iranti ọjọ ibi Jesu, bi oúnjẹ ti pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti o wa ni Òkè-okun àti àwọn díẹ̀ ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, bẹ̃ ni o ṣọ̀wọ́n tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé.

Ò̀we Yorùbá ni, “Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojú rẹ à lami”.  Bi enia ò bá ni ọ̀kánjúwà, á mọ irú òkèlè ti ó lè gba ọ̀nà ọ̀fun rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀kánjúwa á bu  lai ronu pe òkèlè ti ó ju ọ̀nà ọ̀fun lọ á fa ẹkún.  Òwe yi bá àwọn ti ó ṣe jura wọn lọ tàbi ki ó jẹ igbèsè lati ra ẹ̀bùn, oúnjẹ ti wọn ò ni jẹ tán, aṣọ, bàtà àti oriṣiriṣi ti wọn ri ni ìpolówó lai mọ̀ pé ọdún á ré kọjá.  Lẹhin ọdún, ọ̀pọ̀ a fi igbèsè bẹ̀rẹ̀ ọdún titun,  eyi a fa ìrora àti ọ̀rọ̀ ti ó ṣòro si ayé irú ẹni bẹ̃.

Àjẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ – Eating without looking back, is the cause of disgrace for the Pig. Courtesy: @theyorubablog

Yorùbá ni “Ájẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ”, nitori eyi ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin ti ẹ ni ìfẹ́ àti gbé èdè àti àṣà̀̀ Yorùbá lárugẹ, pe ki ẹ ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Ẹ kú ọdún o, ọdún titun ti o ḿbọ̀ lọ́nà á ya abo fún gbogbo wa.

ENGLISH TRANSLATION

During this yuletide, particularly during the remembrance of Jesus’ birth – Christmas celebration, as there is abundance of food for many people in the developed world and some in Africa so also is scarcity for many others all over the world.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-12-24 23:01:10. Republished by Blog Post Promoter

“Ohun ti ó ntán lọdún eégún” – Kérésìmesì ọdún Ẹgbã-lé-mẹ́rìnlà ti lọ̀ – “Masquerade Festival sure has an end” – Christmas 2014 has gone

Christmas Gifts

Bàbá-Kérésì – Father Christmas

Ìwà alajẹtan ti bori iránti ohun ti Kérésìmesì wà fún.  Ọ̀pọ̀ kò ti ẹ̀ ránti pé iránti ọjọ́ ibi Jesu ni Ìjọba ṣe fún ará ilú ni ọjọ́ ìsimi ni ọjọ́ karun-din-lọgbọn oṣù kejila ni ọdọ-ọdún.  Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni Òkè-Òkun ti ẹ rò pé “Bàbá-Kérésì dára ju Jesu” nitori Bàbá-Kérésì fún àwọn ni ẹ̀bùn ṣùgbọ́n ó kù si ọwọ́ òbi àti àwọn  Onigbàgbọ́ lati tẹra mọ́ àlàyé ohun ti ọdún Kérésìmesì wà fún.

Kò yẹ ki Kérésìmesì sún èniyàn si igbèsè tàbi fa irònú.  Àwọn ti ó wà ni Òkè-Òkun, ìwà-alẹjẹtan ti sún ọ̀pọ̀ si igbèsè, tàbi irònú nitori wọn kò ni owó lati ra ẹ̀bùn àti ohun tuntun ti wọn polówó tantan lóri ẹrọ-isọ̀rọ̀ igbàlódé bi ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán, ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ori ayélujára.

Òwe Yorùbá ni “Ohun ti ó ntán lọdún eégún”, eyi túmọ̀ si pé, “Ohun ti ó ni ibẹ̀rẹ̀, ni òpin”.  Kérésìmesì ọdún yi ti wá, ó ti lọ, fún àwọn ti ó jẹ igbèsè nitori ọdún, ó ku igbèsè lati san wọ ọdún tuntun.  Ni àsikò ìpalẹ̀mọ́ ọdún tuntun yi, ó yẹ ki èniyàn ṣe ipinu lati ṣe bi o ti mọ.

Ọdún tuntun á bá wa láyọ̀ o.

ENGLISH TRANSLATION

Consumerism has nearly overtaken the purpose of Christmas.  Most people no longer remember that the annual public holiday for every twenty-fifth of December is dedicated to the Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-26 16:44:40. Republished by Blog Post Promoter