Tag Archives: Child Mortality

“Àbíkú sọ Olóògùn di èké” – “Child mortality mis-portray the genuineness of the Herbalist”

Ìgbàgbọ́ Yorùbá yàtọ̀ si ohun ti àwọn Ẹlẹko-Ijinlẹ fi hàn ni ayé òde òni.  Ni igbà àtijọ́, bi obinrin/iyàwó bá bi ọmọ, ti ó kú ni ikókó tàbi ki ó tó gba àbúrò, ọmọ ti wọn bá bi lẹhin rẹ ni wọn ma fún ni orúkọ “Àbíkú” pàtàki ti ó bá tó bi meji, mẹta ki ọmọ tó dúró.  Yorùbá gbàgbọ́ ninú àpadà-wáyé, ni igbà miran, wọn á fi ibinú fi àmin, bi ki wọn kọ ilà si ara ọmọ ti ó kú tàbi gé lára ẹ̀yà ara ọmọ yi lati mọ bóyá yio padà wá.  Bi ìyá ti ó bi Àbíkú bá bímọ lẹhin ikú ọmọ ti wọn fi àpá si lára, àpá yi ni wọn ma kọ́kọ́ wò lára ọmọ titun.  Bi wọn bá ri àpá yi, wọn o sọ ọmọ naa ni orúkọ Àbíkú.  Orúkọ àbùkù ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àbíkú – ó lè jẹ́ orúkọ ẹranko, orúkọ ti ó fi ìbẹ̀rù hàn, tàbi orúkọ fún ìmọràn.

Àbíkú jẹ́ ikú ọmọdé àti ìkókó titi dé ọmọ ọdún marun.  Ẹkọ-Ijinlẹ fi hàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ọmọdé ti Yorùbá mọ̀ si Àbíkú yi ti ìpasẹ̀ wọnyi wá: àrùn tó ṣe-dádúró, oúnjẹ-àìtó, omi-ẹlẹgbin,  ilé-iwòsàn ti kò pé tàbi ai si ilé-iwòsàn, àrùn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ọmọ ti ó ni iwọn-kékeré nigbà ìkókó. Owe Yoruba ti o ni “Àbíkú sọ Olóògùn di èké” fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn pé, kò si oògùn ti ó lè dá Àbíkú dúró.  Ìmọ̀ Ijinlẹ fi hàn pe ki ṣe gbogbo ọmọ ti ó kú, ni ó yẹ ki ó kú, nitori lati igbà ti àtúnṣe àwọn ohun ti ó nfa ikú ọmọdé yi ti wà, Àbíkú din-kù – nipa ìpèsè omi ti ó mọ́, ilé-ìwòsàn ọmọdé, ilà-lóye àwọn obinrin nipa ìtọ́jú aboyún àti ọmọdé

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-19 21:51:28. Republished by Blog Post Promoter