Ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si tijú lati jẹ orúkọ ti òbí fi èdè Yorùbá sọ wọn. Èyi tó bá tún gba lati jẹ orúkọ Yorùbá á tún bã jẹ ni kikọ tàbi ni pipè. Èwo ni ká kọ “Bayọ ni Bayor, Fẹmi ni Phemmy, Tọlani ni Thorlani – kilo njẹ bẹ̃? Nigbati ẹni to ni orúkọ bá nbajẹ bawo ni àjòji ṣe lè pe orúkọ na dada? Lẹhin ọdún pipẹ́ itumọ̀ orúkọ ti wọn ba jẹ yi a sọnù.
“Ẹni ti kò bámọ̀ itàn ara rẹ̀, wọn á pe lorúkọ ti ki ṣe tirẹ, á si dáhùn”. Á gbọ́ ti igbà òwò burúkú “Òwò Ẹrú”, ti ilú tó lágbára ra àwọn enia bi ẹni ra ohun ini. Ni àsikò yi, bi wọn bà kó enia lẹ́rú, olówó rẹ á fun lórúkọ nitori ko ma ba ranti ibi ti ó ti ḿbọ̀. Eleyi jẹ ki ó ṣòro fún ẹrú lati mọ ibi ti wọn ti wa lẹhin ti òwò ẹrú pari. Ohun ribiribi ti ẹrú ṣe, kò hàn si àwọn ti ó kù ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú pé dúdú ti wọn kó lẹ́rú ló ṣẽ, nitori orúkọ ti ó yi padà.
Òwe Yorùbá ni “Ilé làńwò kátó sọmọ lórúkọ”. Ó ṣeni lãnu pé ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá kò mọ iyi orúkọ wọn, nitori eyi fúnra wọn ni wọn pa orúkọ wọn da si orúkọ ti wọn kò mọ itumọ̀ rẹ.
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ maṣe jẹ́ki ẹ̀yà àti èdè Yorùbá parẹ́. “Orúkọ ẹni ni ifihàn ẹni”, ao ni parẹ máyé o (Àṣẹ)
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-01-21 21:13:32. Republished by Blog Post Promoter