Ni ọjọ́ kẹrin-din-lógún, oṣ̀u kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún, ọwọ́ Ọlọpa Italy tẹ ọkunrin mẹ̃dogun ti ó ju àwọn Ìgbàgbọ́ mejila si odò nitori ẹ̀sìn lati inú ọkọ̀ ojú agbami ti o nko Aláwọ̀-dúdú ti ó nsa fún ogun àti iṣẹ lo si Òkè-òkun/Ilú-Òyinbò.
Ni gbogbo ọ̀nà ni Aláwọ̀-dúdú fi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn. Lára gbi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn ni Àlùfã fi ni ki àwọn ọmọ ijọ bẹ̀rẹ̀ si jẹ koríko ti ọmọ rẹ kò lè jẹ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ijọ ti ó jẹ koríko ló gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn. Ọmọ ijọ ti kò le bọ ara rẹ tàbi bọ ọmọ, ti ó nda ida-mẹwa nigbati Olóri Ijọ nfi owó yi gun ọkọ̀ òfúrufú fi han pé ọ̀pọ̀ ti gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn. Aládurà ti ó nri iran ti kò ri tara rẹ gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.
Ẹlẹ́sin Mùsùlùmi ti ó npa ẹlòmíràn ni orúkọ ẹ̀sìn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn. Eyi ti ó ni èèwọ̀ ni iwé kika fún ẹ̀sìn ohun “Boko Haram” ti wọn fi nba ilé iwé jẹ, ji àwọn obinrin kò kúrò ni ilé iwé, fihàn pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn. Ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún ló pé ọdún kan ti ẹgbẹ́ burúkú “Boko Haram” ti ko igba-le-mọkandinlógún obinrin kúrò ni ilé-iwè ni Chibok. Lèmọ́mù rán ọmọ tirẹ̀ lọ si ilé-iwé, irú àwọn ọmọ Lèmọ́mù ti ó ka iwé ni ó nṣe Òṣèlú tàbi jẹ ọ̀gá ni iṣẹ́ Ìjọba.
Kò si Òṣèlú Aláwọ̀-dúdú ti kò sọ pé ohun jẹ Onígbàgbọ́ tàbi Mùsùlùmi ṣùgbọ́n eyi kò ni ki wọn ma ja ilú ni olè. Ìfẹ́ agbára ki jẹ ki wọn fẹ gbe ipò silẹ̀ nitori eyi wọn á fi ẹ̀sìn da ilú rú. Eleyi ló fa ogun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú. Continue reading
Originally posted 2015-04-18 00:30:26. Republished by Blog Post Promoter