Bi kò bá si ìtẹ́lọ́rùn, kò si ohun ti èniyàn ni ti ó tó. À i ni ìtẹ́lọ́rùn ló nfa iwà burúkú bi, olè̀ jijà, àgbèrè, ojúkòkòrò, irà-kurà, ijẹ-kújẹ, ìpànìyàn, gbi gbé oògùn olóró àti àwọn àlébù yoku. Kò si owó ti ẹni ti kò ni ìtẹ́lọ́rùn lè ni, ki ó tó.
Yorùbá ni “Isà òkú ki i yó”, bẹ́ ẹ̀ ló ri fún a lai ni ìtẹ́lọ́rùn, nitori ojoojúmọ́ ni ohun tuntun njade, pàtàki ni ayé oriṣiriṣi ẹ̀rọ igbàlódé àti ẹ̀rọ ayélujára yi. Fún àpẹrẹ, oriṣiriṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ló wà, ti wọn nṣe jade ni ọdọdún, àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ igbàlódé owó iyebiye. Pẹ̀lú ìṣẹ́ ti ó pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, ọkọ̀ ilẹ́ kò tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú àti Olóri-Ìjọ mọ, ọkọ̀-òfúrufú bi ó ti wọ́n tó, ni wọn nkó jọ. Nitori eyi, kò si owó ti ó lè tó fún ẹni ti ó bá fẹ́ràn ohun ayé.
Ẹ̀kọ nla ni lati kọ́ ọmọ ni ìtẹ́lọ́rùn lati kékeré. Ẹni ti ó bá ni ìtẹ́lọ́rùn, ló ni ohun gbogbo, nitori ko ni wo aago aláago ṣiṣẹ́, á lè lo ohun ti ó bá ni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn.
Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, “Ohun ti kò tó loni mbọ̀ wá ṣẹ́kù ni ọ̀la” bi èniyàn bá lè farabalẹ̀.
ENGLISH TRANSLATION
If there is no contentment, nothing can ever be enough. Lack of contentment is the root cause of many character disorders, such as stealing, adultery, greed, compulsive shopping, gluttony, killings, drug peddling and other vices. No amount of money is ever enough for someone who lacks contentment. Continue reading
Originally posted 2015-05-22 16:00:00. Republished by Blog Post Promoter