Lati bi ogójì ọdún sẹhin, Epo-rọ̀bi nikan ni okùn ọrọ̀ ajé orilẹ̀ èdè Nigeria, ó si ti pa owó ribiribi wọlé fún ilú. Nigbati Epo-rọ̀bi bẹ̀rẹ̀ si pa owó wọlé, ará ilú kọ iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn ohun ti ilú nṣe silẹ̀ fún ifẹ́ ọjà òkèrè. Àsikò Epo-rọ̀bi ni ilú fi irẹsi òkèrè dipò oriṣiriṣi oúnjẹ ilẹ̀ wa. Ki ṣe eyi nikan, Ìjọba Ológun àti Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ iwà ibàjẹ́ nipa ki kó owó ti ó yẹ ki wọn fi tún ilú ṣe jẹ. Wọn ò kó owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yi dúró ni ilú, wọn nko lọ si Òkè-Òkun, eyi ló ba iná mọ̀nàmọ́ná, ilé-ìwòsàn, ilé-iwé, ọ̀nà, omi mi-mun àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ́.
Lẹhin ti àwọn Ìjọba Ológun àti Òṣèlú fi ipò wọn ba ilú jẹ́ tán, bi ori bá fọ́ wọn, wọn á gba ọ̀nà Òkè-Òkun lọ fún ìtọ́jú, dipò ki wọn tú ile-iwé ṣe, wọn a fi owó ti wọn ji pamọ́ rán ọmọ lọ si Òkè-Òkun fún ẹ̀kọ́ ti ó yè kooro. Wọn a fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ́ ra ilé nla si Òkè-Òkun, oúnjẹ àti èso ilú kò dùn lẹnu olówó, aṣọ àti ohun ti ará ilú nṣe kò dára tó, ọjà Òkè-Òkun nikan ni wọn lè fi yangàn.
Lai pẹ yi, àwọn Òṣèlú bẹ̀rẹ̀ si polongo pé “ki ará́ ilu ra ọja ilú, ki Naira (owo Nigeria) lè gòkè”. Ki i ṣe ìyànjú burúkú ni eyi ṣùgbọ́n, “ọ̀rọ̀ kò dùn lẹ́nu olè”, kì í ṣe lati ẹnu àwọn Òṣèlú ti ẹnu wọn ti fẹ si ọjà òkèrè nitori wọn ti kó owó ilú pamọ́ si àwọn ilú Òkè-Òkun. Bi a bá ṣe akiyesi, ki àṣiri tó tú ni àsikò Ìjọba tuntun (Buhari/Òṣinbàjò), àwọn ti ilé-iṣẹ́ Agbógun ti ìwà ìbàjẹ́ tọka tàbi mú pé ó kó owó ilú jẹ jù̀, kò wọ aṣọ Òkè-Òkun. Ó san ki wọn wọ aṣọ Òkè-Òkun, ju ki wọn kó owó rẹpẹtẹ ti wọn ji kó lọ si Òkè-Òkun.
Díẹ̀ ninú àwọn Òṣèlú ti Ilé Iṣẹ́ Agbógun ti Ìwà Ìbàjẹ́ fi ẹ̀sùn kàn: Some of the Politicians facing corrupt charges by Economic and Financial Crimes Commission (EFCC)
Ẹ̀bẹ̀ la bẹ̀ “Òṣèlú Nigeria” ki wọn ma pe Ajá l’Ọbọ fún ará ilú, ki wọn kó owó ilú ti wọn ji pamọ́ si Òkè-Òkun padà, ki wọn si fi àpẹrẹ rere silẹ̀ fún ará ilú nipa àyipadà kúrò ni iwà ojúkòkòrò àti olè ti wọn nfi ipò jà dúró. Àyipadà Òṣèlú kúrò ninú iwà burúkú ni ó lè mú ki owó ilú (Naira) kògè.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading