Òwe Yorùbá sọ wi pé “bi iná bá kú, á fi eérú bojú, bi ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú, á fi ọmọ ẹ rọ́pò”. Òwe yi fi hàn ipò ti Yorùbá fi ọmọ si. Kò si ẹni ti kò ni kú, ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ nlá ni ikú ọmọ jẹ́ fún òbí àti àwọn ti olóògbé bá fi silẹ̀ pàtàki àbíkú àgbà. Ìròyìn ikú Jidé Tinubu àrólé Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu kàn pé ó jade láyé ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kini oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdínlógún.
Ọlọrun ki ó dáwọ́ àbíkú àgbà dúró, ki ó si tu bàbá olóògbé, Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed, ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo ẹbí ninú. Ki Èdùmàrè dá ikú ọ̀dọ́ dúró, kó tu gbogbo àwọn ti irú ọ̀fọ̀ bẹ́ ẹ̀ bá ṣẹ̀ ninú.
ENGLISH TRANSLATION
According to one of the Yoruba proverbs translated thus “fire is succeeded by ashes, plantain/banana is replaced by its fruits”. This proverb reflects the hope Yoruba placed on their children. Death is unavoidable by everyone, however, the death of one’s child is often a terrible bereavement for the parents of the deceased particularly the death of an adult child. On Wednesday, November 1, 2017, the news of the death of Jide Tinubu the first son of the former Governor of Lagos State, Bola Ahmed Tinubu was announced. Continue reading