Tag Archives: BBC

“Ẹrú kan ló mú ni bú igba ẹrú”: “One slave causes the abuse of two hundred others”.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ló nṣe dáradára ní ilé àti àjò tí a kò gbọ́ ìròyìn wọn.  Óṣeni lãnu wípé àwọn diẹ tó nṣe iṣẹ́ ibi bi: gbígbé oògùn olóró, ẹgbẹ́ òkùnkùn, olè jíjà àti bẹ̃bẹ lọ mba àwọn yoku jẹ.

Yorùbá ni “Ẹni jalè ló bọmọ jẹ”, ìròyìn iṣẹ́ rere ki tàn bi irú ìròyìn iṣẹ ibi ti Michael Adébọ́lájọ àti Michael Adé́bọ̀wálé tó kárí ayé.

Ó yẹ ki Ìjọba àti gbogbo Yorùbá pa ẹnu pọ lati bá oníṣẹ ibi wi nítorí gẹ́gẹ́bí òwe Yorùbá “Ẹrú kan ló́ mú ni bu igba ẹrú”.

ENGLISH TRANSLATION

Many Yoruba indigenes that are doing well both at home and abroad never made any news.  It is unfortunate that the few that engaged in evil acts like: drug peddling, cultism, stealing etc. are destroying the good work of the others.

Yoruba adage said “He/She who steals destroys the innocence of a child”, news about good deed never spread like the news of the recent evil act committed by the duo: Michael Adebolajo and Michael Adebowale that spread all over the world.

It is apt for the Government and all Yoruba indigenes to join hands to condemn evil because according to the Yoruba proverb, “One slave causes the abuse of two hundred”.

Share Button

NÍNÍ OWÓ BABA ÀFOJÚDI, ÀÌNÍ OWÓ BABA ÌJAYÀ: Abundance of Money is the Father of Insolence and Lack of Money the Father of Panic

Welfare System Reforms -- BBC

BBC article on benefit cuts, aini owo baba ijaya.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi. Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà.  Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn.

Gẹ́gẹ́bí ilé iṣẹ́ amóhùn máwòran Ìlúọba ti ròyìn, lati Oṣù kẹrin, ọjọ́ kini, ọdún ẹgbẹ̀rúnmẽjilemẹtala, Ìjọba Ìlúọba bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe lati dín gbèsè ti ìlú jẹ ku; gbígba àwọn òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn tẹra mọ́ṣẹ àti ki àwọn ti ko ṣiṣẹ́ le padà si ẹnu iṣẹ́.  Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni: ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé; yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo; àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ̃bẹ lọ.

Yorùbá ni “Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù  tí o lè  fi tẹ ayé lórùn”,  bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ̃ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní.

ENGLISH TRANSLATION >>> Continue reading

Share Button