Tag Archives: Ambassador

“Obinrin ti kò ni orogún, kò ti mọ àrùn ara rẹ̀”: A woman who has no co-wife cannot yet identify her disease

Òwe yi fi ara han ni itan iyàwó Aṣojú-ọba, ti a ò pè ni Tinumi pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ọkùnrin ti a mọ̀ si Mofẹ́.  Mofẹ́ dàgbà lati fẹ obinrin.  Ó̀ yan obinrin ti à ńpè ni Àyànfẹ́ ni iyàwó àfẹ́sọ́nà.  Nigbati ó mú Àyànfẹ́ lọ han àwọn òbi rẹ, Bàbá Mofẹ́ gba Àyànfẹ́ tọwọ́-tẹsẹ̀, ṣùgbọ́n iyá Mofẹ́ fi àáké kọ́ri pé ọmọ ohun kò ni fẹ́ Àyànfẹ́.  Wọn bẹ̀rẹ̀ idi ti kò ṣe fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ ẹni ti ó múwá, Tinumi kò ri àlàyé ṣe ju pé ohun kò fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ́ “Àtọ̀hún rin wa – ọmọ ti kò ni iran”.  Ọmọ rẹ naa fi àáké kòri pé ẹni ti ohun ma fẹ ni Àyànfẹ́.

Tinumi sọ àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ di orogún, gbogbo ibi ti ó bá ti pàdé Àyànfẹ ni ibi àjoṣe ẹbi ni ó ti ḿbajà pé ki ó dẹ̀hin lẹhin ọmọ ohun.  Àyànfẹ́ lé ọmọ rẹ titi ṣùgbọ́n ó kọ̀ lati dẹhin.

Lẹhin ọdún marun ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ti ńṣe ọ̀rẹ́, iwé jade pé wọn gbé Bàbá Mofẹ́.  Gẹgẹ bi Aṣojú-Ọba lọ si Òkè-òkun.  Bàbá ṣètò bi ọmọ àti iyàwó ti ma tẹ̀lé ohun.  Ọmọ kọ̀ pé ohun kò lọ pẹ̀lú òbi ohun ti àfẹ́sọ́nà ohun kò bá ni tẹ̀lé àwọn lọ.  Bàbá gbà pé ọmọ ohun ti tó fẹ́ iyàwó, wọn ṣe ètò igbéyàwó fún Mofẹ́ àti àfẹ́sọ́nà̀ rẹ.  Lẹhin ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ṣe iyàwó tán, wọn tẹ̀lé Bàbá àti Ìyá wọn lọ si Òkè-okun lati má jọ gbé.

Àrùn ara Tinumi, aya Aṣojú-ọba bẹ̀rẹ̀ si han nitori ó sọ iyàwó ọmọ rẹ di orogún.  Nigbati ọkọ rẹ ri àlébù yi, ó pinu lati wa orogún fun Tinumi nitori ai ni orogún ni ó ṣe sọ aya ọmọ rẹ di orogún.  Gẹgẹ bi a ti mọ, igbéyàwó ibilẹ̀ kò ni ki ọkùnrin ma fẹ iyàwó keji.  Nigbati Bàbá Mofẹ́ fẹ́ iyàwó kékeré, ọmọ àti iyàwó kó kúrò lọ si ilé tiwọn, inú rẹ bàjẹ́ nigbati o kũ pẹ̀lú orogún rẹ.  Ó jẹ èrè iwà burúkú àti ìgbéraga.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-06-20 13:30:24. Republished by Blog Post Promoter