Tag Archives: Akure Monarch

“Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó gun Ori Oyè ilu Àkúrẹ́” – “New Deji of Akure ascends the Throne”

Déjì Àkúrẹ́ Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó pari gbogbo ètùtù ibilẹ ti Ọba Àkúrẹ́ ma nṣe lati gori oyè ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, lati di Ọba Kejidinlãdọta ilú Àkúrẹ́ ni ipinlẹ̀ Ondó ti ila-oorun orilẹ̀ èdè Nigeria.

img_20150708_221218-resized-800

Ọba Àkúrẹ́ gun Òkiti Ọmọlóre – The New King of Akure completed the traditional rites

 

 

 

 

 

 

 

 

Kí kí Ọba ni èdè Àkúrẹ́ – Congratulatory message to the new King in Akure Dialect

Kábiyèsi, Ọba Aláyélúà, wo kú ori ire o
Ẹbọ á fín o Àbá
Adé á pẹ́ lóri, bàtà á pẹ́ lọ́sẹ̀ o
Ùgbà rẹ á tu ùlú Àkúrẹ́ lára (Àṣẹ)

ENGLISH TRANSLATION

The Monarch of Akure, Deji Aladelusi Ogunlade-Aladetoyinbo has completed the all the traditional rites required to ascend the throne and was crowned on Wednesday, July eight, Two Thousand and Fifteen to become the forty eight Monarch of the Ancient City of Akure, Ondo State in Western Nigeria.

The Yoruba Blog Team sent Congratulatory Message in Akure dialect.

 

Share Button

Originally posted 2015-07-14 20:44:41. Republished by Blog Post Promoter

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ – Prince Kole Aladetoyinbo receives the Staff of Office as the King of Akure

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ - Deji of Akure received Staff of Office

Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ Ọba Àkúrẹ́ – Deji of Akure received Staff of Office

Ni ọjọ́ kẹsan oṣù kẹfa, ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún, Olóri-Òṣèlú Gómìnà Olúṣẹ́gun Mimiko ti Ipinlẹ Ondo,   gbé Ọ̀pá Àṣẹ Ọba fún Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó lati di Déjì ilù Àkúrẹ́ kẹrindinlãdọta.

Lẹhin oṣù mejidinlógún ti Ọba Adebiyi Adeṣida pa ipò dà, Àkúrẹ́ kò ni Ọba, a fi Adelé Ọmọba Adétutù Adeṣida Ojei ti ó delé di igbà ti Ọba Kọ́lé Aládétóyìnbó gba Ọ̀pá Àṣẹ.  Bi ó ti ẹ je wi pé Ọba Adebiyi Adeṣida kò pẹ́ lóri oyè ju ọdún mẹta, igbà rẹ tu ilú Àkúrẹ́ lára.

Gẹ́gẹ́ bi ọmọ Àkúrẹ́ pàtàki, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wumi Akintide ti kọ lóri iwé ìròyìn ori ayélujára, nipa “Àwọn idi lati yọ ayọ̀ Ọba tuntun, Déjì Àkúrẹ́ – Ọ̀dúndún Keji”, tọka si pé, ki ṣe àkọ́kọ́ ti wọn pe Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó wálé lati Òkè-òkun lati wa du ipò Ọba.  Eyi ṣẹlẹ̀ ni ọdún mẹwa sẹhin ni igbà ti Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó jẹ́ ikan ninú àwọn Ọmọba mẹ́tàlá lati idilé Òṣùpá ti oyè kan, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ninú àwọn Afọbajẹ ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nitori eyi, wọn kò ṣe bi ó ṣe yẹ.  Wọn kọ́kọ́ yàn “Iléri” ẹni ti ó gbé owó rẹpẹtẹ silẹ̀ lai ṣe iwadi dájú pé Ọmọba ni, nigbati ilú kọ ẹni ti wọn yàn,  wọn pe Ọmọba Adépọ̀jù Adeṣina (ti won ro loye) lati Ilú-Ọba lati fi jẹ Ọba dipò Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó ti ipò Ọba tọ́ si.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Ayé kò lè pa kádàrá dà, ṣùgbọ́n wọn lè fa ọwọ́ aago sẹhin”, lẹhin ọ́dun mẹwa, àwọn Afọbajẹ yan Ọmọba Kọ́lé Aládétóyìnbó laarin Ọmọba méjìlá lati idile Òṣùpá, ó si gba Ọ̀pá Àṣẹ ni wẹ́rẹ́.

Èdùmàrè á jẹ ki Adé ó pẹ́ lóri, ki bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀, ki igbà Ọba Kọ́lé Aládétóyìnbó tú ilú Àkúrẹ́ lára”, Àṣẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button