“Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ”: “What the dog will eat, the Devil will provide”

Yorùbá ma nṣe rúbọ Èṣù nigba gbogbo ki ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tó gbalẹ̀.  Ounjẹ ni wọn ma fi ṣè rúbo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.  Irú ounjẹ yi ni Yorùbá npè ni “ẹbọ”.  Ìta gbangba ni wọn ma ngbe irú ẹbọ bẹ si, nitori eyi ounjẹ ọ̀fẹ ma npọ fún ajá, ẹiyẹ àti awọn ẹranko miran ni igboro.

Ajá ìgboro - Stray dog eats food on the street. Courtesy: @theyorubablog

Ajá ìgboro – Stray dog eats food on the street. Courtesy: @theyorubablog

Bi ènìyàn kò ti si ninu ìhámọ́ ni ayé òde òní, bẹni ajá pãpa kò ti si ni ìhámọ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ “ajá igboro” ma jade lọ wa ounjẹ òjọ́ wọn kakiri ni.  Alãdúgbò lè pe ajá lati gbe ounjẹ àjẹkù fún pẹ̀lú, eleyi fi idi ti wọn fi nkígbe pe ajá han.  Bayi ni ará Àkúrẹ́ (olú ìlú ẹ̀yà Ondo) ti ma npe ajá fún ounjẹ ni ayé àtijọ́:

Kílí gbà, gbo, gbà, gbo

Ajá òréré́, gbà̀, gbo, gbà…

 

A lè fi òwe Yorùbá ti o ni “Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ” yi ṣe àlàyé awọn ounjẹ ti Èṣù pèsè ni ayé òde òni wé: ẹjọ, àìsàn/àilera, ọtí/õgun-olóró tàbi ilé tẹ́tẹ́.  Ni ida keji, ajá jẹ “Agbẹjọ́rò, Babaláwo/Oníṣègùn, ilé-ọtí àti ilé iṣẹ́/ero tẹ́tẹ́”.

Adájọ́ Obinrin ati Ọkunrin -  Female and Male Judge Courtesy: @theyorubablog

Adájọ́ Obinrin ati Ọkunrin – Female and Male Judge
Courtesy: @theyorubablog

Bi a bá ṣe akiyesi, Yorùbá ni “Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà, owó alágbàṣe á pé”.  Bi Agbẹjọ́rò ba bori tàbi kò bori ni ilé-ẹjọ́, owó rẹ á pé, aláìs̀an ni ilera bi ko ni ilera, Babaláwo/Oníṣègùn á gbowó.  Bi ọ̀mùtí yó tàbi kò yó, Ọlọti/Olõgun-olóró á gbowó àti bi ẹni tó ta tẹ́tẹ́ bá jẹ bi kò jẹ owó oni-tẹ́tẹ́ á pé.

 

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba often offer sacrifice before the advent of Christianity.  Food are often used for the sacrifice.  This type of food is called “Sacrifice”.  Such sacrifice are usually placed in the open, as a result, there are plenty of free meals for the dogs, birds and other animals on the Streets.

As people’s movement are not restricted like in the modern time, so also are the dogs not in restriction.  Many “Street dogs” roam around to source their meal.  Neighbours can beckon on the stray dog to offer left over meals, hence the reason for the various style of beckoning on dogs.  Check out the above recording the way people in Akure (capital of Ondo State) beckons on the Street dogs in the olden days.

We can use the Yoruba proverb that said “What the dog will eat, the Devil will provide” to compare the kind of food provided by the Devil in the modern days as: Cases, sickness, alcoholism/hard drug or gambling shop.  On the other hand, the dog can be parallel with: Lawyers, Doctors/Herbalists, Pub and Gambling House/machine.

If we observe another Yoruba proverb that “Whether the boss sells or not, the labourer will collect his/her wage”.  This means, whether the Lawyer/Barrister wins a case in court or not, his/her legal fees must be paid, same as whether the sick person is well or not, the Doctor/Herbalist has to be paid.  Whether the Drunkard/Drug addict is intoxicated or not, the Pub-owner’s will be paid.

Share Button

Originally posted 2013-10-15 20:25:03. Republished by Blog Post Promoter

“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.  Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.  Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter

Orúkọ ti ó wọ́pọ̀ ni idile “Ọlá”, “Ọba”, “Ìjòyè” àti “Akinkanjú ni àwùjọ – Common Names among “Wealthy Family, Palace, Chieftains, Valiant Families”

A

Yoruba Names Short Form English meaning
Abimbọ́lá Bimbọ Met wealth at birth
Abisọ́lá Bisọ́lá Born into wealth
Abiọ́lá Biọ́lá Born into wealth
Adébisi Adé/Bisi Crown has increased by birth
Adébọ́lá Adé/Bọ́lá Crown met wealth
Adébọ̀wálé Débọ̀ The crown has returned home
Adédára Dára The crown is good
Adédàmọ́lá Dàmọ́la Crown has joined with wealth
Adédàpọ̀ Dàpọ Mixture of Crowns
Adédiran Diran Crown becomes lineage
Adékòge Gòkè Crown has risen up
Adéifẹ́ Ìfẹ́ The crown of love
Adéloyè Déloyè The Crown is the Title
Adémọ́lá Démọ́lá Crown came into wealth
Adénikẹ Nikẹ Crown has petting
Adéniran Niran Crown has pedigree
Adéniyi Niyi Crown has honour
Adéọlá Deọla Crown of wealth
Adéoyè Déloyè The Crown of Chieftain
Adésanmi Sanmi The crown is suitable for me
Adésọ́lá Désọ́lá He/She who came into wealth
Adéṣọlá Ṣọlá The crown became wealth
Adéwálé Wálé The crown came home
Adéwọlé Wọlé The crown entered home
Adéwọnúọlá Wọnú The crown entered into wealth
Adéwùnmi Wùnmi I love the crown
Ajibọ́lá Jibọ́lá Woke to meet wealth
Akinọlá Akin The valour of wealth
Akinlabi Labi We gave birth to the valiant
Àńjọláolúwa Anjọla We are enjoying the wealth of God
Arinọla Arin The middle of wealth
Ayọ̀ọlá Ayọ The joy of wealth
Share Button

Originally posted 2014-07-01 20:07:31. Republished by Blog Post Promoter

Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká – Effect of Environmental Pollution on Rapid Climate Change

Ẹ wo àròkọ “Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká” lóri ayélujára ni ojú ewé yi: Check out the essay on “Effect of environmental pollution on rapid climate change” on our YouTube channel on the internet.

Share Button

Originally posted 2019-01-21 17:55:15. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀kọ́ àti Ọgbọ́n ni Ọ̀rọ̀ Àgbà lati Ẹnu Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ lórí Ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán Òpómúléró – Review of Words of Wisdom by Dr. Victor Omololu Olunloyo on Opomulero TV

Bi a ba fi eti si ọ̀rọ̀ ti àgbà Yorùbá Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ  ni ori ẹ̀rọ “Amóhùnmáwòrán Òpómúléró”, ni ori ayélujára, a o ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọnyi:

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ fi àṣà Yorùbá ti ó ti ńparẹ́ hàn nipa bi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú “Oríkì”

Nínú ìtàn lati ẹnu agba, a o ri pé Bàbá loye lati kékeré.  Nkan bàbàrà ni ki ọmọ jade ni ilé ìwé giga ni ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ki ó si gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.  Ni ọdún Ẹgbàádínméjìdínlógójì,  Gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ẹ̀kọ́ Ìṣirò, Ìjọba Ipinlẹ Ìwọ Oòrùn ayé ìgbà yẹn kò sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ kéré jú lati fún ni ipò Alaṣẹ lóri iṣẹ́ Ìdàgbàsókè Ìtọ́jú Owó.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ fihàn pé, lai si ni ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, kò ni ki á di ọ̀tá bi ti ayé òde òní.  A ri àpẹrẹ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ ṣe súnmọ́ Olóògbé Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tó, bi ó ti jẹ́ wi pé wọn kò si ninú ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, àwọn méjèèji jẹ olootọ ti ó si ni ìgboyà.

Ọgbọ́n ki i tán, bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ti kàwé tó, Bàbá ṣi ńkàwé lati wá ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ọgbọ́n púpọ̀ wà ni ọ̀rọ̀ àgbà yi, ẹ ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yi lóri Amóhùnmáwòrán Òpómúléró.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-03-30 20:39:07. Republished by Blog Post Promoter

Ọdún tuntun káàbọ̀ – Ẹgbà-lé-mẹ́rìnlà – Welcoming the New Year – 2014

Ẹ kú ọdún o – Season Greetings. Courtesy: @theyorubablog

kú dún

Festive Greetings

 kú ìyè dún

Greetings on the return of the year

dún á ya abo

Prosperous New Year  

À èyí ṣe àmọ́dún o.                                                  Better years ahead

View more presentations or Upload your own.
Share Button

Originally posted 2013-12-31 23:11:39. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀dájú ló bi owó, ìtìjú ló bi igbèsè”: “Shrewdness gives birth to money while shyness gives birth to debt”.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Iṣẹ́ ni oogun ìṣẹ́”, jẹ́ òtítọ́, bi òṣìṣẹ́ bá ri owó gbà ni àsìkò, tàbi gba ojú owó fún iṣẹ́ ti wọn ṣe.  Òṣìṣẹ́ ti ó ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí/àkókò lórí owó kékeré, kò lè bọ́ ninu ìṣẹ́,  nitori, ọlọ́rọ̀ kò  ni ìtìjú lati jẹ òógùn Òṣìṣẹ́.  Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́, a fi ìtìjú gé ara wọn kúrú nipa àti bèrè ẹ̀tọ́ wọn.  Òṣìṣẹ́ míràn a ṣe iṣẹ́ ọ̀fẹ́ fún ọlọ́rọ̀ tàbi ki wọn fúnra wọn gé owó ise wọn kúru lati ri ojú rere ọlọ́rọ̀, nipa èyi, wọn á pa owó fún ọlọ́rọ̀ ni ìparí ọdún.

http://www.wptv.com/dpp/news/national/mcdonalds-taco-bell-wendys-employees-to-protest-fast-food-restaurant-wages

Òṣìṣẹ́ da iṣẹ́ silẹ – employees protest

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti o ni “Ọ̀dájú ló bi owó, ìtìjú ló bi igbèsè” ṣe ló lati ba oloro tàbi o ni ilé-iṣẹ́ ti á lo gbobo ọ̀nà lati ma gba “Ẹgbẹ́-òṣìṣẹ́” láyè.  Ọlọ́rọ̀ kò ni ìtìjú lati lo òṣìṣẹ́ fún owó kékeré.  A lè lo ọ̀rọ̀ yi lati gba Òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn má tara wọn ni ọ̀pọ̀, nipa bi bèrè owó ti ó yẹ fún iṣẹ́ ti wọn ṣe àti pé ki òṣìṣẹ́ gbìyànju lati kọ iṣẹ́ mọ́ iṣẹ́ lati wà ni ipò àti bèrè ojú owó.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-03 17:35:06. Republished by Blog Post Promoter

“Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́” – A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le – Cutting off the head is not the antidote for headache – Using the Christmas season to encourage parents of the abducted Chibok School Girls to keep hope alive.

Yorùbá ni “Ibi ti ẹlẹ́kún ti nsun ẹkún ni aláyọ̀ gbe nyọ́”.  Òwe yi fihan ohun tó nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé.  Bi ọ̀pọ̀ àwọn ti ó wà ni Òkè-òkun ti nra ẹ̀bùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni oriṣiriṣi fún ọdún, bẹni àwọn ti kò ni owó lati ra oúnjẹ pọ ni àgbáyé.  Eyi ti ó burú jù ni àwọn ti ó wà ninú ibẹ̀rù pàtàki àwọn Onígbàgbọ́ ti kò lè lọ si ile-ijọsin lati yọ ayọ̀ ọdún iranti ọjọ́ ibi Jesu nitori ibẹ̀rù àwọn oniṣẹ ibi.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́”. Bawo ni pi pa èniyàn nitori kò gba ẹ̀sìn ṣe lè mú ki èrò pọ̀ si ni irú ẹ̀sìn bẹ́ ẹ̀?  Òkè-Ọya ni Àriwá Nàíjírià, Boko Haram npa èniyàn pẹ̀lú ibọn àti ohun ijà ti àwọn ti ó ka iwé ṣe, bẹni wọn korira, obinrin, iwé kikà, ẹlẹ́sìn- ìgbàgbọ́ ni Òkè-Ọya àti ẹni ti ó bá takò wọn pé ohun ti wọn nṣe kò dára.  Pi pa èniyàn kọ ni yio mu ki àwọn ará ilú gba ẹ̀sìn.

Free the Chibok Girls

Nigerian women protest against Government’s failure to rescue the abducted Chibok School Girls

A ki àwọn iyá àti bàbá àwọn ọmọ obirin ilú Chibok ti wọn ji kó lọ́ ni ilé-iwé, àwọn ẹbi ti ó pàdánù ọmọ, iyàwó, ọkọ, ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi – Boko Haram, pé ki Ọlọrun ki ó tù wọn ninú.  A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le, pé ki wọn ma ṣe sọ ìrètí nù, nitori “bi ẹ̀mi bá wà ìrètí nbẹ”.

 

ENGLISH TRANSLATION

According to Yoruba saying “As some are mourning, some are rejoicing”.  This adage is apt to describe the happenings around the world.  As many Oversea or in the developed World are spending huge sum for gifts and so much food for the yuletide, so also are many people in the world facing starvation as they have no money to buy food.  The worst, are those living in fear particularly the Christians that cannot go to places of worship to celebrate Christmas because of fear of the terrorists. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-23 21:35:53. Republished by Blog Post Promoter

Síse Àpọ̀n – Preparing Wild Mango Seed Soup

Ẹ fọ ẹja, edé àti irú, ẹ dàápọ̀ pẹ̀lú ẹran bibọ, ẹja gbígbẹ, iyọ̀, irú, iyọ̀ igbàlódé àti omi sinú ikòkò kan. Ẹ gbe ka iná fún sisè.  Bi ẹ ti nse lọ, ẹ da epo-pupa sinú ikòkò keji.  Ẹ yọ epo díẹ̀, ki ẹ da àpọ̀n si lati yọ àpnọ̀ yi, bi ó ba ti gbónọ́ díẹ̀, ẹ da gbogbo èlò ọbẹ̀ inú ikòkò kini ni gbí-gbónọ́ sinú ikòkò keji ti epo àti àpọ̀n wa.  Ẹ ro pọ, ẹ yi iná rẹ silẹ̀ díẹ, ki ẹ ro titi yio fi jiná.  Ti ọbẹ̀ na bá ki jù, ẹ bu omi gbi-gbónọ́ díẹ si titi yio ri bi ẹ ṣe fẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-20 10:15:26. Republished by Blog Post Promoter

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter