Originally posted 2013-06-21 22:30:27. Republished by Blog Post Promoter
“Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi nya igi oko: Ìbò ni ipinlẹ Ọ̀ṣun” – “There is strength in numbers: Osun State Election”
Ninú Ẹ̀yà mẹrin-din-logoji orilẹ̀ èdè Nigeria, ẹ̀yà mẹ́fà ni o wa ni ipinlẹ Yorùbá lápapọ̀. Àwọn ẹ̀yà wọnyi ni: Èkó – ti olú ilú rẹ jẹ Ìkẹjà; Èkiti – ti olú ilú rẹ jẹ Adó-Èkiti; Ò̀gùn – ti olú ilú rẹ jẹ Abẹ́òkúta; Ondo – ti olú ilú rẹ jẹ Àkúrẹ́; Ọ̀ṣun – ti olú ilú rẹ jẹ Òṣogbo àti Ọyọ – ti olú ilú rẹ jẹ Ìbàdàn.
Ni Òkè-Òkun, bi enia ba ni ẹjọ́ ni ilé-ẹjọ́, tàbi ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ri, tàbi hùwà àbùkù miran, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè gbé àpóti ibò ṣùgbọ́n, ti kò bá ni itiju, ti ó gbé àpóti ibò, ọ̀pọ̀ àwọn èrò ilú kò ni dibò fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Eyi kò ri béè ni orilẹ-èdè Nigeria, nitori, ẹlẹ́wòn, eleru, olè, apànìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ti ó di olówó ojiji ló ńgbé àpóti ibò nitori wọn mọ̀ pé àwọn lè fi èrú dé ipò.
Àwọn èrò ẹ̀yà Ọ̀ṣun fi òwe Yorùbá ti o ni “Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi ńya igi oko” hàn ni idibò ti ó kọjá ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ, ọdún Ẹgbẹlemẹrinla, wọn kò bẹ̀rù bi Ìjọba àpapọ̀ Nigeria ti kó Ológun àti ohun ijà ti àwọn ará ilú lati da ẹ̀rù bà wọn. Wọn tú jáde lati fi ọ̀pọ̀ dibò àti bójú tó ibò wọn lati gbé Góminà Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá padà.
ENGLISH TRANSLATION
Out of the thirty-six States in Nigeria, six are in Yoruba land altogether. These States are: Lagos – State capital Ikeja; Ekiti – State capital at Ado-Ekiti; Ogun – State capital at Abeokuta; Ondo – State capital at Akure; Osun – State capital at Osogbo and Oyo with the State capital at Ibadan.
In the developed world/abroad, if a person has a pending law suit in the Court, or has once been in prison, or has behaved in a disgraceful manner, such person cannot vie for a Political position, but even if such a person has no sense of shame, and decided to vie, many of the masses would not vote for such. This is not the case in Nigeria, because a prisoner, fraudster, thief, killers/assassin etc with their ill-gotten wealth/money could vie for political position since they know they could win through fraudulent means.
The people of Osun State reflected the application of the Yoruba proverb that said “It is by means of their numbers that Locusts could tear down a tree” during the Governorship Election held on Saturday, ninth August, 2014, when they defied the Federal might as Soldiers and armoured tanks were drafted to intimidate the people. They trooped out in their numbers to vote and protect their votes to re-elect Governor (Mr) Rauf Aregbesola.
Originally posted 2014-08-15 22:49:34. Republished by Blog Post Promoter
Ààntéré ọmọ Òrìṣà-Omi – “Ọmọ o láyọ̀lé, ẹni ọmọ sin lo bimọ”: Aantere – The River goddess child “Children are not to be rejoiced over, only those whose children bury them really have children”.
Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́. Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi: Ọmọlọlá, Ọmọniyi, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ̃bẹ̃ lọ. A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ. Nigbati ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni “Ìyàwó” ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di “Ìyá orúkọ àkọ́bí”, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di “Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta”. Bàbá ọmọ a di “Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta”. Nitori idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀.
Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó. Nitori àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi. Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji. Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ. Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nitori ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà. Ọkọ àti Ìyàwó ni awọn a gbã bẹ.
Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni “Ààntéré” eyi ti ó tumọ si “Ọmọ Omi”. Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ. Ni ọjọ kan, Ààntéré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ. Nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nitori o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ. Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà.
Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ. Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri.
Originally posted 2013-10-11 20:24:26. Republished by Blog Post Promoter
“Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra” – “The sky is wide enough for the birds to fly without bumping into each other”
Ẹ̀sìn ti wa láyé, ki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi tó dé. Fún àpẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ ninú “Ọlọrun” ti Yorùbá mọ̀ si “Òrìṣà-òkè” tàbi “Eledumare”. Bi Yorùbá ṣe ḿbá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ni ayé àtijọ́ ni ó yàtọ̀ si ti àwọn ẹlẹ́sìn igbàlódé.
Yorùbá ńlo “Ifá” lati ṣe iwadi lọ́dọ̀ “Ọlọrun”, ohun ti ó bá rú wọn lójú. Yorùbá ma ńlo àwọn “Òrìṣà” bi “Ògún”, “Olókun”, “Yemọja”, “Ọya”, “Ṣàngó” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “Onílàjà” larin èniyàn àti Eledumare.
Yorùbá ni “Ẹlẹkọ ò ni ki Alákàrà má tà”. Ẹ̀sìn ti fa ijà ri, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, àti ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Onigbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ló ńṣe ẹ̀sìn wọn lai di ẹnikeji lọwọ. Ni òkè-òkun, ẹni ti ó ni ẹ̀sìn àti ẹni ti kò ṣe ẹ̀sìn kankan ló ńṣe ti wọn lai di ara wọn lọ́wọ́. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán yi: Mùsùlùmi àti Onígbàgbọ́ ńṣe ìwàásu lẹgbẹ ara wọn.
Ó ṣe pàtàki ki ẹ ma jẹ ki àwọn Òṣèlú tàbi alai-mọ̀kan lo ẹ̀sìn lati fa ijà tàbi ogun, nitori “Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra”.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-09-05 13:05:43. Republished by Blog Post Promoter
“ỌMỌ ÌYÁ́ MEJI KI RÉWÈLÈ”: 2 Siblings of the Same Mother Should not Die in the Same Tragedy #Watertown #Boston
“Ọmọ ìyá meji ki réwèlè, Yorùbá ma nlo ọ̀rọ̀ yi nígbàtí ọmọ ìyá meji ba ko àgbákó tó la ikú lọ. Irú ìsẹ̀lẹ̀ tó kó ìpayà ba gbogbo ènìà bayi ki ṣe ijamba lásán ṣù́gbọ́n àwọn ìyá meji: Tsarnev, ni wọn tọ́ka si fún iṣẹ́ ibi tó ṣẹlẹ̀ ni oṣù kẹrin ọjọ kẹdogun nibi ere ọlọnajijin tí wọn sá ni Boston.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yi ṣeni lãnu ṣùgbọ́n lati dáwọ́ ikú dúró, nítorí Ọlọrun, ó yẹ kí àbúrò fi ara han lati ṣe àlàyé ara rẹ̀.
English translation:
Yoruba people have a saying that siblings from the same mother should not land themselves in the same regretful situation. This is a saying I have heard used by elders when for instance siblings end up dead from a similar accident. Terrorism is by no means an accident, but the Tsarnev brothers who have been identified by Boston local news as the Terrorists responsible for the April 15 Boston Marathon bombing, should heed to this saying. The brothers are already stuck in a regretful situation but the younger brother can prevent the situation from getting worse.
This whole spectacle is sad enough as it is. But for the love of God I hope the younger brother chooses not to die and surrenders to explain himself.
Check out the following links to follow this story:
1. Local Boston News Live Stream
2. AP News Update
Originally posted 2013-04-19 11:31:36. Republished by Blog Post Promoter
“Ilé làbọ̀ simi oko, ṣùgbọ́n bi ilé bá sanni àwọ̀ là nwò”: “Home is for rest on return from the farm, but the convenience of the home is a reflection on the skin”
Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pataki àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́ lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko. Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nitori adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ. Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé (Nigeria), ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nitori dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná.
Ó ṣeni lãnu pé “oko” ninu àlàyé yi (òkè-òkun/ìlú-oyinbo) sàn ju “ilé” Èkó. Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, “kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si”. Ni totọ, àwọn Oní-ṣòwò ni orílẹ̀ èdè Nigeria ǹgbìyànjú, nitori kò rọrùn lati ṣòwò ni ìlú ti ohun amáyé-dẹrùn ti ìgbàlódé bi iná mona-mona, òpópónà tó dára, omi mimu, àbò, àti bẹbẹ̃ lọ, kò ti ṣe dẽde. A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pataki ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀. Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko.
A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n “omi pọ̀ ju ọkà lọ”. Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú. “Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe”, nitori eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pataki ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2013-11-15 21:57:48. Republished by Blog Post Promoter
“Ọdún nlọ si òpin”: Ẹ ṣọ́ra fún oníjìbìtì/ẹlẹ́tàn – “End of year is fast approaching”: Beware of (419) Fraudsters
Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì/ẹlẹ́tàn ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nipa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè. Àṣà Yorùbá ni ayé àtijọ́ ni lati gbé àwọn ti ó bá hùwà rere ga, lati yẹ àwọn ti ó bá ṣe iṣẹ́ àṣe yọri si.
Yorùbá ni “Ọmọ ẹ o ṣe àgbàfọ̀, ó kó aṣọ wálé, ẹ ò ri ojú olè bi”, ọ̀pọ̀ òbi ki bèrè bi ọmọ wọn ti ri owó mọ nitori àwọn ẹlẹ̀tàn/oníjìbìtì/ ori ayélujára àti Òṣèlú nkó ohun ti ki ṣe ti wọn wálé. Ẹ̀sìn àti àṣà ayé òde òni ngbe àwọn olè àti oníjìbìtì lárugẹ. Nitori eyi “olówó ojiji” pọ si láwùjọ laarin ẹni ti ó wà ni ipò giga àti ipò kékeré. Iṣẹ́ Ọlọrun àti Òṣèlú ti di ọ̀nà ti èniyàn fi le di “olówó lojiji”. Ọ̀̀pọ̀ ọmọ ilé-iwé giga ti kò ti ilé-ọlọ́rọ̀, tàbi ilé Òṣèlú jade, ti yi si olè jijà lori ayélujára ju pé ki wọn di gun jalè.
Ni ayé àtijọ́, bi ọdún bá dé, olè jija pẹ̀lú ipá ló wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni iwà ẹ̀tàn ti a mọ̀ si oníjìbìtì pàtàki ni ori ayélujára ló wọ́pọ̀. Ó ti pẹ ti ẹ̀tàn/jibiti ori ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n, irú àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nko ọ̀pọ̀ iwe lori ayélujára si ẹgbẹgbẹ̀rún èniyàn ni àgbáyé pẹ̀lú èrò lati jẹ nibi ti wọn kò ṣe si. Ẹni ti kò bá funra á jábọ́ si wọn lọwọ, nitori eyi ẹ ṣọ́ra fún àdàmọdi iwé lati ilé-ifowó-pamọ́ tàbi ọ̀dọ̀ ẹni ti ẹ kò mọ̀.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-11-28 10:45:51. Republished by Blog Post Promoter
Òṣèlú Ẹ Gbé Èdè Yorùbá Lárugẹ: Politicians – Promote Yoruba Language
Nínú ìwé ìròyìn “Vanguard”, ti ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹta, ọjọ́ , ọdún kẹrinlélógún, Ẹgbaalémétàlá, Olùkọ́ àgbà ti Èdè ati Àṣà, Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, kébòsí wípé èdè Yorùbá àti èdè abínibí miran le parun ti a ko bá kíyèsára. Ìkìlọ̀ yí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan Olùkọ̀wé yi lati gbé èdè àti Yorùbá ga lórí ẹ̀rọ Ayélujára.
Àwọn Òṣèlú tó yẹ ki wọn gbé èdè ìlú wọn lárugẹ n dá kún pí pa èdè rẹ. Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ko fi èdè na ṣe nkankan ni Ilé-òsèlú, wọn o sọ́, wọn ò kọ́, wọn ò ká. Àwọn Òṣèlú ayé àtijọ́ bi Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Olóyè Ládòkè Akíntọlá, àti bẹ̃bẹ lọ gbé èdè wọn lárugẹ bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wípé wọn kàwé wọn gboyè rẹpẹtẹ. Yorùbá ní “Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́”. Ó yẹ ki àwọn àgbà kọ́ ọmọ lédè, kí à si gba àwọn ọmọ wa níyànjú wípé sí sọ èdè abínibí kò dá ìwè kíkà dúró ó fi kún ìmọ̀ ni. Ó ṣeni lãnu wípé àkàkù ìwé ló pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, wọn ò gbọ́ èdè Yorùbá wọn ò dẹ̀ tún gbọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì.
Yorùbá ní “Ẹ̀bẹ̀ la mbẹ òṣìkà pé kí ó tú ìlú rẹ ṣe”, A bẹ àwọn Òṣèlú́ Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀̀yọ́, lati ṣe òfin mí mú Kíkọ àti Kíkà èdè Yorùbá múlẹ̀ ní gbogbo ilé ìwé, ní pàtàkì ní ilé-ìwé alakọbẹrẹ ilẹ̀ Yorùbá nitori ki èdè Yorùbá ma ba a parẹ́.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2013-03-26 21:44:54. Republished by Blog Post Promoter
“Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ”: “What the dog will eat, the Devil will provide”
Yorùbá ma nṣe rúbọ Èṣù nigba gbogbo ki ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tó gbalẹ̀. Ounjẹ ni wọn ma fi ṣè rúbo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Irú ounjẹ yi ni Yorùbá npè ni “ẹbọ”. Ìta gbangba ni wọn ma ngbe irú ẹbọ bẹ si, nitori eyi ounjẹ ọ̀fẹ ma npọ fún ajá, ẹiyẹ àti awọn ẹranko miran ni igboro.
Bi ènìyàn kò ti si ninu ìhámọ́ ni ayé òde òní, bẹni ajá pãpa kò ti si ni ìhámọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ “ajá igboro” ma jade lọ wa ounjẹ òjọ́ wọn kakiri ni. Alãdúgbò lè pe ajá lati gbe ounjẹ àjẹkù fún pẹ̀lú, eleyi fi idi ti wọn fi nkígbe pe ajá han. Bayi ni ará Àkúrẹ́ (olú ìlú ẹ̀yà Ondo) ti ma npe ajá fún ounjẹ ni ayé àtijọ́:
Kílí gbà, gbo, gbà, gbo
Ajá òréré́, gbà̀, gbo, gbà…
A lè fi òwe Yorùbá ti o ni “Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ” yi ṣe àlàyé awọn ounjẹ ti Èṣù pèsè ni ayé òde òni wé: ẹjọ, àìsàn/àilera, ọtí/õgun-olóró tàbi ilé tẹ́tẹ́. Ni ida keji, ajá jẹ “Agbẹjọ́rò, Babaláwo/Oníṣègùn, ilé-ọtí àti ilé iṣẹ́/ero tẹ́tẹ́”.
Bi a bá ṣe akiyesi, Yorùbá ni “Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà, owó alágbàṣe á pé”. Bi Agbẹjọ́rò ba bori tàbi kò bori ni ilé-ẹjọ́, owó rẹ á pé, aláìs̀an ni ilera bi ko ni ilera, Babaláwo/Oníṣègùn á gbowó. Bi ọ̀mùtí yó tàbi kò yó, Ọlọti/Olõgun-olóró á gbowó àti bi ẹni tó ta tẹ́tẹ́ bá jẹ bi kò jẹ owó oni-tẹ́tẹ́ á pé.
ENGLISH TRANSLATION
Yoruba often offer sacrifice before the advent of Christianity. Food are often used for the sacrifice. This type of food is called “Sacrifice”. Such sacrifice are usually placed in the open, as a result, there are plenty of free meals for the dogs, birds and other animals on the Streets.
As people’s movement are not restricted like in the modern time, so also are the dogs not in restriction. Many “Street dogs” roam around to source their meal. Neighbours can beckon on the stray dog to offer left over meals, hence the reason for the various style of beckoning on dogs. Check out the above recording the way people in Akure (capital of Ondo State) beckons on the Street dogs in the olden days.
We can use the Yoruba proverb that said “What the dog will eat, the Devil will provide” to compare the kind of food provided by the Devil in the modern days as: Cases, sickness, alcoholism/hard drug or gambling shop. On the other hand, the dog can be parallel with: Lawyers, Doctors/Herbalists, Pub and Gambling House/machine.
If we observe another Yoruba proverb that “Whether the boss sells or not, the labourer will collect his/her wage”. This means, whether the Lawyer/Barrister wins a case in court or not, his/her legal fees must be paid, same as whether the sick person is well or not, the Doctor/Herbalist has to be paid. Whether the Drunkard/Drug addict is intoxicated or not, the Pub-owner’s will be paid.
Originally posted 2013-10-15 20:25:03. Republished by Blog Post Promoter
“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits
Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe. Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni. Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.
Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ. Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa. Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú. Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá. Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn. Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá. Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde. Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ. Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.
Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin. Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa. Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun. Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa
Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi. Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ. Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró. Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run. Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀. Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ. Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu. Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́. Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading
Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter