Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ – If the Hunter thinks of the suffering in the wild, he would not share his kill with anyone.

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ - Hunter

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ – Hunter

Láyé àtijọ́, iṣẹ́ Ọdẹ jẹ ikan ninú iṣẹ gidi ni ile Yorùbá.  Ògbójú Ọdẹ ló npa ẹranko bi Erin, Ẹkùn, Kìnìún àti Ẹfòn, Ìmàdò, Ikõkò, nígbàtí àwọn to nṣe Ọdẹ etílé npa ẹranko ìtòsí ilé bi Ọ̀kẹ́rẹ́, Òkété, Ọ̀bọ àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹran ìgbẹ bi Ìgalà, Àgbọ̀nrín àti , ẹran ọ̀sìn bi Àgùntàn, Ewurẹ, Òbúkọ, Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ ẹran tí o wọ́pọ̀ fún jíjẹ ni ayé àtijọ dípò ẹran Mãlu tí ó wá wọpọ láyé òde òní.

Àwọn ẹranko bi Ẹfọ̀n, Erin, Kìnìún, Ẹkùn ti dínkù nígbàtí ẹranko bi Àgbánreré ti parẹ́ ni ilẹ̀ Yorùbá.

A lè fi ò̀we Yorùbá “Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ” wé ìyá ti àwọn ti ó wà ni Ìlúọba/Ò̀kèòkun njẹ nínú òtútù lati pa owó.  Nínú owó yi, wọn a ronú àti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti wọn gbìyànjú lati ràn lọ́wọ́, ki i wo ìya ti ojú wọn rí.

Ẹ rántí wípé ẹni ti o bá laanu ló lè ronú lati ran ẹlòmíràn lọ́wọ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-23 10:15:07. Republished by Blog Post Promoter

ẸNITÍ ỌLỌRU KÒ DÙN NÍNÚ TÓ NLA ṢÚGÀ, JẸ̀DÍJẸ̀DÍ LÓ MA PÁ: WHOEVER GOD HAS NOT MADE GLAD THAT IS LICKING SUGAR WILL DIE OF PILE”

Yorùbá ní “Ẹnití Ọlọrun kò dùn nínú, tó nla ṣúgà (iyọ̀ ìrèké), jẹ̀díjẹdí ló ma pá”.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ṣ̀e àtìlẹhìn fún iwadi tó fihàn wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ìrẹ̀wẹ̀sì mbaja ma mu ọtí àti jẹ oúnje ọlọra, ti iyọja tàbí tí iyọ̀ ìrèké pọ̀ nínú rẹ.  Ó ṣeni lãnu wípé, kàka ki ẹni bẹ͂ jade nínú ìrẹ̀wẹ̀sì, oúnje tó kún fún ọ̀rá, iyọ̀ àti iyọ̀ ìrèké (ṣúgà) mã dákún àìsàn míràn bi: jẹ̀díjẹdí, ẹ̀jẹ̀ ríru àti oniruuru àìsàn míràn.

Oúnje dídùn àti ọtí mímu kò lè mú ìrẹ̀wẹ̀sì kúrò tàbí fa ìdùnnú, ṣùgbọ́n àyípadà ọkàn sí ìwà rere àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun ló lè mú inú dùn.

Ẹkú ọdún Ajinde o, ẹ ma jẹ́un ju, Jesu ku fun ẹlẹ́sẹ̀ àti aláìní, nítorí nã ti ẹ ba ri jẹ, ẹ rántí áwọn ti ko ri.  Yorùbá ni “ajọjẹ kò dùn bẹni kan o ri”.

ENGLISH TRANSLATION

The Yoruba adage that “Whoever has not been made glad by God that is licking sugar will die of pile” is in support of the research that showed that most people drink and eat more fatty, salty and sugary food when they are depressed.  Unfortunately, instead of coming out of depression, bad diet containing too much fat, salt and sugar will only add more health complications such as pile, hypertension and a host of other diseases.

Tasty food or alcoholic drink would not lift anyone out of depression or gladness of spirit, but only positive attitude and trust in God.

Happy Easter, do not over feed, Jesus died for the sinners and the poor, as a result if you have, remember those who have none.  Youruba said “Eating together is not sweet, if one person is left out”.

Share Button

Originally posted 2013-03-30 00:03:05. Republished by Blog Post Promoter

“A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú” – “We know not what God will do, stops one from committing suicide”

Àṣà Yorùbá ma ńri ọpẹ́ ninú ohun gbogbo, nitori eyi ni àjọyọ̀ àti ayẹyẹ ṣe pọ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Bi kò bá ṣe ayẹyẹ igbéyàwó; á jẹ́ idúpẹ́ fun ikómọ/isọmọlórúkọ; ìsìnku arúgbó; ikóyọ ninú ewu ijàmbá ọkọ̀; iṣile; oyè gbigbà ni ilé-iwé giga tàbi oyé ilú; idúpẹ́ ìparí ọdún tàbi ọdún tuntun àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Kò si igbà ti àlejò kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ kan tàbi èkeji ni gbogbo ilẹ́ Yorùbá.  Eyi jẹ́ ki àlejò rò wipé igbà gbogbo ni Yorùbá fi ńṣọdún.

Kò si ẹni ti o ńdúpẹ́ ti inú rẹ ńbàjẹ́, tijó tayọ̀ ni enia fi nṣe idúpẹ́.  Ninú idúpẹ́ àti àjọyọ̀ yi ni ẹni ti inu rẹ bàjẹ́ miran ti lè ni ireti pé ire ti ohun naa yio dé.  Ni ilú Èkó, lati Ọjọ́bọ̀ titi dé ọjọ́ Àikú ni enia yio ri ibi ti wọn ti ńṣe ayẹyẹ.  Ọjọ́bọ̀ jẹ ọjọ́ ti wọn ńṣe àisùn-òkú; ọjọ́ Ẹti ni isinkú, ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ti ayẹyẹ igbéyàwó nigbati ọjọ́ Àikú wà fún idúpẹ́ pàtàki ni ilé ijọsin onigbàgbọ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ yi ló mú ipèsè jijẹ, mimu, ilù àti ijó lati ṣe àlejò fún ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ ti ó wá báni ṣe ayẹyẹ.

A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ò mọ èyi ti Ọlọrun yio ṣe, kò jẹ́ ki á binú kú”, tu ẹni ti ó bá ni ìrẹ̀wẹ̀sì ninú, pé ọjọ́ ọ̀la yio dára.   Yorùbá gbàgbọ́  pé ẹni ti kò ri jẹ loni, bi kò bá kú, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, lè di ọlọ́rọ̀ ni ọ̀la. Nitori eyi, kò yẹ ki enia “Kú silẹ̀ de ikú” nitorina, “Bi ẹ̀mi bá wà, ireti ḿbẹ”.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-15 10:03:30. Republished by Blog Post Promoter

Ìkíni ni Èdè Yorùbá – Greetings in Yoruba Language

Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀  Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si abala ojú     ìwé yi,  àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò  fún yin.

ENGLISH TRANSLATION

As a sign of respect, the Yoruba have greetings for any time of the day, special events and ceremonies. We hope you will enjoy some of the greetings below in the slides and voice recordings.

Share Button

Originally posted 2013-07-04 23:41:35. Republished by Blog Post Promoter

“Bàbá Ìtàn Ìkọ̀lé-Èkìtì, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí relé” – “The Father of History of Ikole-Ekiti, Late Professor Emeritus Ade Ajayi has gone home”

Babá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Bàbá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Ilé ò, ilé, Ilé ò, ilé,
Babá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà

Ni Àṣà Yorùbá, ọmọdé ló nkú, àgbà ki kú, àgbà ma nrelé ni.  Ọ̀fọ̀ ni ikú ọmọdé jẹ́, ijó àti ilú ni wọn fi nṣe ìsìnku àgbà lati sín dé ilé ikẹhin.  Ìròyìn ikú Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí kàn lẹhin ikú rẹ ni ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ,ọdún Ẹgbã-le-mẹrinla.  A bi ni ilú Ìkọ̀lé-Èkìtì ni ọdún marun-le-lọgọrin sẹhin.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọdé àti àgbà ilú lati onírúurú iṣẹ́àti àwọn èniyàn pàtàki ni ilé-lóko péjọ ni ọjọ kọkàn-din-logun, oṣù kẹsan,ọdún Ẹgbã-le-mẹrinla lati ṣe ìsìnku rẹ.

http://www.ngrguardiannews.com/news/national-news/179784-eulogies-as-eminent-scholar-ade-ajayi-is-buried

Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí - Late Professor Emeritus Ade Ajayi

Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí – Late Professor Emeritus Ade Ajayi

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé “Ẹni ti kò bá mọ ìtàn ara rẹ, yio dahun si orúkọ tí kò jẹ́”.  Ki awọn bi Olóògbé tó bẹ̀rẹ̀ si kọ Ìtàn Yorùbá àti ilẹ́ Aláwọ̀-dúdú silẹ̀, àwọn Aláwọ̀-funfun kò rò pé Aláwọ̀-dúdú ni Ìtàn nitori wọn kò kọ silẹ̀, wọn nsọ Ìtàn lati ẹnu-dé-ẹnu ni.  Nitori eyi, ohun ti ó wu Aláwọ̀-funfun ni wọn nkọ.  Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, kọ́ ẹ̀kọ́, ó si gboyè rẹpẹtẹ lori Ìtàn, pàtàki lati jẹ́ ki Yorùbá mọ ìtàn ara wọn.  Ó lo imọ̀ yi lati kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwé itan, ikan lára iwé wọnyi ni “Ìtàn àti Ogun jijà Yorùbá”.  Ó tún kọ nipa Ìgbési-ayé “Olóògbé Olóri àwọn Alufaa Àjàyí Crowther” àti “Onidajọ Káyọ̀dé Ẹ̀ṣọ́”.

Yorùbá pa òwe pé “Àgbà ki wà lọ́jà, ki ori ọmọ titun wọ”, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí ni Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, Èkó kẹta.  Nitori ìfẹ́ ti ó ni si ìdàgbà sókè Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, ìtàn àti ìpamọ́ ohun-ìtàn, ó kọ iwé si Olóri Òṣèlú Nigeria (Goodluck Ebele Jonathan), nigbà Ìporúkọdà lójiji lati Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó si orúkọ Olóògbé MKO Abiọ́lá – ti gbogbo ilú dibò fún lati ṣe Olóri Òṣèlú, ṣùgbọ́n àwọn Ìjọba Ológun kò jẹ́ kó dé ipó yi.  Olóri Òṣèlú Nigeria yi ọkàn padà lati ma yi orúkọ Ilé-ẹ̀kọ Giga yi padà lojiji nitori ọ̀wọ̀ ti ó ni fún Olóògbé. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-26 17:56:15. Republished by Blog Post Promoter

“Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ – Ọdún wọlé dé”: “One who acts moderately will not be disgraced – The Festive Period is here”

Ọdún Kérésì jẹ́ ọdún Onigbàgbọ́ lati ṣe iránti ọjọ́ ibi Jésù Olùgbàlà.  Ọjọ́ kẹjọ lẹhin ọdún Kérésìmesì ni ọdún  tuntun.  Fún ayẹyẹ ọdún, kò si iyàtọ̀ laarin Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ni ilẹ̀ Yorùbá nitori Yorùbá gbà wi pé “Ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ kó dúpẹ́”.  Ọpẹ́ ló yẹ ki èniyàn dá ju igbèsè ji jẹ lati ṣe àṣe hàn ni àsikò ọdún.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn Àgbẹ̀ á dari wálé pẹ̀lú irè oko pàtàki iṣu.  Àwọn Oniṣòwò á ri ọjà tà nitori àsikò yi ni Bàbá àti Ìyá ma nrán aṣọ ọdún fún àwọn ọmọdé àti oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ipalẹ̀mọ́ ọdún.  Inú ọmọdé ma ndùn nitori asiko yi ni wọn nse irẹsi àti pa adiẹ fún ọdún.  Àwọn ọmọdé á lọ lati ilé ẹbi kan si ekeji, ẹbi ti wọn lọ ki, á fún wọn ni oúnjẹ àti owó ọdún.  Àwọn àgbàlagbà naa ma ndá aṣọ ẹgbẹ́ fún idúpẹ́ ọdún, ṣùgbọ́n ki owó epo rọ̀bi tó gba igboro, ki ṣe aṣọ olówó nla bi ti ayé òde òni.

Àsikò ti olè npọ̀ si niyi pàtàki ni ilú Èkó, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ na owó ti wọn kò ni lati ṣe ọdún.  Ìpolówó ọjà pọ̀ ni àsikò yi ni Òkè-Òkun, nitori eyi, ọ̀pọ̀ nlo ike-igbèsè tàbi ki wọn ya owó-èlè lati ra ọjà ti wọn kò ni owó rẹ.  Lẹhin ọdún, wọn a fi ọdún tuntun bẹ̀rẹ̀ si san igbèsè, nitori eyi Ìyá àti Bàbá a ma a ti ibi iṣẹ́ kan lọ si ekeji lai ni ìsimi tàbi ri àyè àti bójú tó àwọn ọmọ.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wi pé “Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ ”, nitori eyi gbogbo ọmọ Yorùbá ni ilé, ni oko, ẹ ṣe bi ẹ ti mọ, ẹ ma tori odun na ọwọ́ si nkan ti ọwọ́ yin kò tó, ki ẹ ma ba a tẹ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Onigbàgbọ́  ayé òde oni ki i fẹ fi èdè Yorùbá kọrin ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ bi ọmọ Òyinbó ti kọ orin àwọn “Obinrin Rere” ni ojú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-18 23:18:09. Republished by Blog Post Promoter

Wi wé Gèlè Ìgbàlódé – How to tie Modern Head Scarfs

Share Button

Originally posted 2015-07-07 19:41:40. Republished by Blog Post Promoter

“Ọbẹ̀ tó dùn, Owó ló pá: Àwòrán àti pi pè Èlò Ọbẹ̀” – “Tasty Soup, Cost Money – Pictures and pronunciation of Ingredients”

Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se.  Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù.

Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn.  Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi.

View more presentations or Upload your own.

 

View more presentations or Upload your own.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-08 16:30:36. Republished by Blog Post Promoter

Orukọ́ Ẹranko àti Àwòrán – Yoruba Names of Animals and pictures

Share Button

Originally posted 2013-06-21 22:30:27. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi nya igi oko: Ìbò ni ipinlẹ Ọ̀ṣun” – “There is strength in numbers: Osun State Election”

Ninú Ẹ̀yà mẹrin-din-logoji orilẹ̀ èdè Nigeria, ẹ̀yà mẹ́fà ni o wa ni ipinlẹ Yorùbá lápapọ̀.  Àwọn ẹ̀yà wọnyi ni: Èkó – ti olú ilú rẹ jẹ Ìkẹjà; Èkiti – ti olú ilú rẹ jẹ Adó-Èkiti; Ò̀gùn – ti olú ilú rẹ jẹ Abẹ́òkúta; Ondo – ti olú ilú rẹ jẹ Àkúrẹ́; Ọ̀ṣun – ti olú ilú rẹ jẹ Òṣogbo àti Ọyọ – ti olú ilú rẹ jẹ Ìbàdàn.

ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn - Osun voters voted and protected their votes

ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn – Osun voters voted and protected their votes

Ni Òkè-Òkun, bi enia ba ni ẹjọ́ ni ilé-ẹjọ́, tàbi ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ri, tàbi hùwà àbùkù miran, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè gbé àpóti ibò ṣùgbọ́n, ti kò bá ni itiju, ti ó gbé àpóti ibò, ọ̀pọ̀ àwọn èrò ilú kò ni dibò fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.  Eyi kò ri béè ni orilẹ-èdè Nigeria, nitori, ẹlẹ́wòn, eleru, olè, apànìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ti ó di olówó ojiji ló ńgbé àpóti ibò nitori wọn mọ̀ pé àwọn lè fi èrú dé ipò.

Àwọn èrò ẹ̀yà Ọ̀ṣun fi òwe Yorùbá ti o ni “Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi ńya igi oko” hàn ni idibò ti ó kọjá ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ, ọdún Ẹgbẹlemẹrinla, wọn kò bẹ̀rù bi Ìjọba àpapọ̀ Nigeria ti kó Ológun àti ohun ijà ti àwọn ará ilú lati da ẹ̀rù bà wọn.  Wọn tú jáde lati fi ọ̀pọ̀ dibò àti bójú tó ibò wọn lati gbé Góminà Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá padà.

ENGLISH TRANSLATION

Out of the thirty-six States in Nigeria, six are in Yoruba land altogether.  These States are: Lagos – State capital Ikeja; Ekiti – State capital at Ado-Ekiti; Ogun – State capital at Abeokuta; Ondo – State capital at Akure; Osun – State capital at Osogbo and Oyo with the State capital at Ibadan.

In the developed world/abroad, if a person has a pending law suit in the Court, or has once been in prison, or has behaved in a disgraceful manner, such person cannot vie for a Political position, but even if such a person has no sense of shame, and decided to vie, many of the masses would not vote for such.  This is not the case in Nigeria, because a prisoner, fraudster, thief, killers/assassin etc with their ill-gotten wealth/money could vie for political position since they know they could win through fraudulent means.

The people of Osun State reflected the application of the Yoruba proverb that said “It is by means of their numbers that Locusts could tear down a tree” during the Governorship Election held on Saturday, ninth August, 2014, when they defied the Federal might as Soldiers and armoured tanks were drafted to intimidate the people.  They trooped out in their numbers to vote and protect their votes to re-elect Governor (Mr) Rauf Aregbesola.

Share Button

Originally posted 2014-08-15 22:49:34. Republished by Blog Post Promoter