Déjì Àkúrẹ́ Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó pari gbogbo ètùtù ibilẹ ti Ọba Àkúrẹ́ ma nṣe lati gori oyè ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, lati di Ọba Kejidinlãdọta ilú Àkúrẹ́ ni ipinlẹ̀ Ondó ti ila-oorun orilẹ̀ èdè Nigeria.
Ọba Àkúrẹ́ gun Òkiti Ọmọlóre – The New King of Akure completed the traditional rites
Kí kí Ọba ni èdè Àkúrẹ́ – Congratulatory message to the new King in Akure Dialect
Kábiyèsi, Ọba Aláyélúà, wo kú ori ire o
Ẹbọ á fín o Àbá
Adé á pẹ́ lóri, bàtà á pẹ́ lọ́sẹ̀ o
Ùgbà rẹ á tu ùlú Àkúrẹ́ lára (Àṣẹ)
ENGLISH TRANSLATION
The Monarch of Akure, Deji Aladelusi Ogunlade-Aladetoyinbo has completed the all the traditional rites required to ascend the throne and was crowned on Wednesday, July eight, Two Thousand and Fifteen to become the forty eight Monarch of the Ancient City of Akure, Ondo State in Western Nigeria.
The Yoruba Blog Team sent Congratulatory Message in Akure dialect.
Originally posted 2015-07-14 20:44:41. Republished by Blog Post Promoter
Ni àtijọ́, àwọn ọmọ ilé-iwé ló ńran àgbàlagbà ti kò lọ ilé-iwé lọ́wọ́ lati kọ iwé, pataki ni èdè abínibí. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn iwé-àkọ-ránṣẹ́ wọnyi ni ojú iwé yi:
Ìwé ti Ìyá kọ sí ọmọ
Èsì iwé ti ọmọ kọ si iyá
Iwé ti ọkọ kọ si iyàwó
Èsi iwé ti aya kọ si ọkọ
Ìwé ti Ìyá kọ sí ọmọ – Yoruba mother to child letter. Courtesy: @theyorubablog
Èsì iwé ti ọmọ kọ si iyá – Response from child to mother. Courtesy: @theyorubablog
Iwé ti ọkọ kọ si iyàwó – Husband’s Yoruba letter to wife. Courtesy: @theyorubablog
Èsi iwé ti aya kọ si ọkọ Wife’s response to husband ‘s letter in Yoruba. Courtesy: @theyorubablog
Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì: Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ̃bẹ lọ. Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè (Àṣẹ).
ENGLISH TRANSLATION
Watch out weekly for postings on: application of Yoruba Proverbs, posts to help you learn Yoruba, folklore, news that we can learn lessons from, stories about the Yoruba community and food in London, New York, Chicago, Orlando etc. Join us to ensure that the Yoruba language is not extinct by writing and reading Yoruba on the Internet.
Thanks so much, The Yoruba language will not be destroyed by the power of God and our collective efforts (Amen).
Originally posted 2013-05-17 02:06:24. Republished by Blog Post Promoter
Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri. Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára. Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’. Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ.
Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe. Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí). Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’. Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin.
Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé. Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin. Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé.
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Àlébù ki ṣe ẹ̀gàn tàbi agọ̀; ṣùgbọ́n, ẹ̀gàn àti agọ̀ ni fún ẹni ti ojú rẹ fọ́ si àlébù ara rẹ”. Irú ẹni bẹ̃, kò lè ri àtúnṣe tàbi sọ àlèbú yi di ohun ini. Ninú ìtàn bi Àjàpá ti sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn ti a mọ̀ si titi di oni, Àjàpá jẹ́ ẹranko ti kò lè yára rin tàbi ni agbára iṣẹ́ àti ṣe lówó, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n lati bo àlébù rẹ.
Yorùbá ni “Alágbára má mèrò; baba ọ̀le; Ọgbọ́n ju agbára”. Àjàpá́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹwẹ, nigbati Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ alágbá̀ra ti kò mèrò. Kò si ohun ti Àjàpá lè ṣe lai ni idi tàbi ọgbọ́n àrékérekè, nitori eyi, ó sọ ara rẹ di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ nitori gbogbo ẹranko yoku ti já ọgbọ́n rẹ. Ẹlẹ́dẹ̀ kò fi ọgbọ́n wá idi irú ọ̀rẹ́ ti Àjàpá jẹ́. Laipẹ, Àjàpá lọ yá owó lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lu àdéhùn pe ohun yio san owó na padà ni ọjọ́ ti ohun dá. Ẹlẹ́dẹ̀ rò pé ọ̀rẹ́ ju owó lọ, ó gbà lati yá Àjàpá lówó nitori àdéhùn rẹ.
Nigbati ọjọ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ reti titi ki ó wá san owó ti ó yá, ṣù̀gbọn Àjàpá kò kúrò ni ilé rẹ nitori ó mọ̀ pé ohun kò ni owó́ lati san. Àjàpá fi ohun pẹ̀lẹ́ ṣe àlàyé pé bi ohun ti fẹ́ ma kó owó lọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ni olè dá ohun lọ́nà, ti wọn gba gbogbo owó lọ. Inú Ẹlẹ́dẹ̀ kò dùn nitori kò gba iṣẹ̀lẹ̀ yi gbọ́, ṣùgbọ́n ó gba nigbati Àjàpá tún dá ọjọ́ miran lati san owó na. Bi Ẹlẹ́dẹ̀ ti kúrò ló bá aya rẹ “Yáníbo” dìmọ̀pọ̀ bi ohun kò ti ni san owó padà. Ó ni bi ọjọ́ bá pé, bi Yáníbo bá ti gbọ́ ìró Ẹlẹ́dẹ̀, kó yi ohun padà, ki ó bẹrẹ si lọ ẹ̀gúsí ni àyà ohun lai dúró bi Ẹlẹ́dẹ̀ bá wọlé bèrè ohun.
Àjàpa ninu ẹrọ̀fọ̀ ti Ẹlẹ́dẹ̀ ju si – The Tortoise thrown by the Pig into the swamp. Courtesy: @theyorubablog
Ni ọjọ́ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ dé lati gba owó rẹ, Yáníbo ṣe bi ọkọ rẹ ti wi. Ẹlẹ́dẹ̀ fi ibinu gbé ọlọ àti ẹ̀gúsí sọnù si ẹrọ̀fọ̀ ti ó wá ni ìtòsí lai mọ̀ pé Àjàpá ni ọlọ yi. Yáníbo fi igbe ta titi ọkọ rẹ fi wọlé. Àjàpá yọ ara rẹ̀ kúrò ninú ẹrọ̀fọ̀, ó nu ara rẹ̀, ó ṣe bi ẹni pé ohun kò ri Ẹlẹ́dẹ̀ nigbati ó délé. Ó bèrè ohun ti ó fa igbe ti Yáníbo ńké. Yáníbo ṣe àlàyé.
Ẹlẹ́dẹ̀i fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ – The Tortoise prout in the swamp. Courtesy: @theyorubablog
Yorùbá ni “Ọ̀bùn ri ikú ọkọ tìrọ̀ mọ́, ó ni ọjọ́ ti ọkọ ohun ti kú ohun ò wẹ̀”. Àjàpá ri ohun ṣe àwá-wi, ó sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ pé ọlọ ti ó gbé sọnù ṣe pataki fún idilé àwọn, nitori na ó ni lati wá ọlọ yi jade ki ohun tó lè san owó ti ohun yá. Ẹlẹ́dẹ̀ wọnú ẹrọ̀fọ̀ lati wá ọlọ idile Àjàpá. Lati igbà yi ni Ẹlẹ́dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ titi di ọjọ́ oni.
Àkàrà gbóná re, Here comes hot fried bean fritters Ẹ bámi ra àkàrà o Buy my fried bean fritters Àkàrà yi dùn, ó lóyin This fried bean fritters is sweet with honey Àkàrà gbóná re. Here comes hot fried bean fritters
Àkàrà jẹ ikan ninu ounjẹ aládùn ilẹ̀ Yorùbá. Ẹ̀wà (funfun tabi pupa) ni wọn fi nṣe àkàrà, wọn a bo ẹ̀wà, wọn a lọ, ki wọn to põ pẹ̀lú èlò ki wọn tó din. A lè fi àkàrà jẹ ẹ̀ko, fi mu gaàrí tabi jẹ fún ìpanu. Ki ṣe gbogbo enia ló mọ àkàrà din, awọn enia ma nfẹran ẹni ti ó ba mọ àkàrà din. Àti ọmọdé àti àgbà ló fẹ́rán àkàrà. Awọn ọmọde ma nkọrin bayi:
Taló pe ìyá alákàrà ṣeré, Who is calling fried bean fritters woman for fun Ìyá alákàrà 2ce Fried bean fritters seller Ó nta sánsán simi nímú Its smell is inviting to my nose Ìyá alákàrà Fried bean fritters seller Ó nta dòdò sími lọ̀fun Its smelling like fried plantain in my throat Ìyá alákàrà. Fried bean fritters seller
Ki ṣe enia nikan ló fẹ́ràn àkàrà, Àjàpá naa fẹ́ràn àkàrà, ṣùgbọ́n kò ri owó raa, nitori èyi “Ojú ni Àjàpá fi nri àkàrà, ètè rẹ ko baa”. Àjàpá wá ronú ọgbọ́n ti ó lè dá lati pèsè àkàrà fún òhun àti idilé rẹ. Ó ronú bi wọn ti lè dá ẹ̀rù ba ọmọ alákàrà ki ó lè sá fi igbá àkàrà, rẹ silẹ̀. Ó gbé agọ̀ wọ̀, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ fi pápá́ bora. Bi alákàrà ba ti kiri kọjá, Àjàpá a bẹ si iwájú ọmọ alákàrà, wọn a ma ko orin bayi:
Àjàpá . Courtesy: @theyorubablog
Àjàpá gbé agọ̀ wọ̀ – The Tortoise wore a mask to frighten – Courtesy: @theyorubablog
Ọlirae ma gbọ̀nà, The Spirit has taken over the Road Tobini tobini to 2ce Tobini, tobini to Olóri yara lọ, Corn meal seller go quickly Tobini tobini to Tobini, tobini to Alákàrà dá dànù Fried bean fritter seller abandon it Tobini tobini to. Tobini, tobini to
Ẹ̀rù ba alákàrà, á da àkàrà dà nù. Àjàpá àti ẹbí rẹ á bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà. Yorùbá ni “Wọ́n mú olè lẹẹkan, ó ni ohun ò wá ri, tani fi ọ̀nà han olè?”. Ọmọ alákàrà sunkún lọ si ilé, inú Ìya-alákàrà kò dùn si ọmọ rẹ nitori o pàdánù àkàrà àti owó ti o yẹ ki ó pa. Kò gba ìtàn ọmọ rẹ̀ gbọ́, nitorina, ó gbé àkàrà fún ni ọjọ́ keji ati ọjọ́ kẹta, ọmọ tún padà pẹ̀lú ẹkún. Ohun fúnra rẹ̀ tẹ̀lé ọmọ rẹ̀, iwin tún yọjú, àwọn mejeeji sá eré padà si ìlú lai ranti gbé igbá àkàrà. Ìyá alákàrà gba ọ̀dọ̀ Ọba àti àgbà ìlú lọ lati sọ ohun ti ojú wọn ri. Ọba pe awọn òrìṣà ìlú lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ba ọrọ̀ ìlú jẹ yi. Ninu gbogbo òrìsà, Ọ̀sanyìn nikan ló gbà lati yanjú ọ̀rọ̀ yi.
Ìyá alákàrà tungbe àkàrà fún ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun àti Ọsanyin tẹ̀lé. Bi alákà̀rà ti bẹ̀rẹ̀ si polówó, Àjàpá tún jade gẹgẹ bi iṣe rẹ̀. Yoruba ni “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun”. Ìyá alákàrà àti ọmọ rẹ̀ tún méré, ṣùgbọ́n Ọ̀sanyin ti o fi ara pamọ́ dúró lati wo ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Àjàpá àti àwon idile rẹ̀ jade nwọn bọ ohun ti nwọn fi bora silẹ̀ lati tún bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà. Orí ti Àjàpá yọ jade lati jẹ àkàrà, Ọ̀sanyin fọ igi ẹlẹgun mọ lórí, awọn ẹbi rẹ̀ sálọ. Ọ̀sanyin gbé òkú Àjàpá lọ si ọ̀dọ̀ Ọba. Inú ará ìlú dùn nitori àṣiri olè tú. Ọba pàṣẹ pe Àjàpá ni ki nwọn bẹrẹ fi rúbọ si Ọ̀sanyin.
Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe ojúkòkòrò kò lérè, bó pẹ́, bóyá àṣírí olè á tú. Ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ – Àjàpá pàdánù ẹ̀mí nitori àkàrà.
Oriṣiriṣi wèrè ló wà, nitori pé ki ṣe wèrè ti ó wọ àkísà ni ìgboro tàbi já sita nikan ni wèrè. Ẹnikẹni ti o nhu ìwà burúkú tàbi ṣe ìpinnu burúkú ni Yorùbá npè ni “wèrè”.
Wèrè – Mad person
Ìpinnu ṣi ṣe, ṣe pàtàki ni ayé àtijọ́ àti òde òní. Òwe Yorùbá sọ wi pé “Bi ará ilé ẹni bá njẹ kòkòrò búburú, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ̀ kò ni jẹ́ ki a sùn ni òru”. Àbáyọrí ìpinnu tàbi èrò burúkú kò pin si ọ̀dọ̀ ẹbi àwọn ti ó wà ni àyíká elérò burúkú, ó lè kan gbogbo àgbáyé. Fún àpẹrẹ, kò si ìyàtọ̀ laarin wèrè tó já sita nitori wèrè ni Yorùbá npe ọkọ tàbi ìyàwó ti ó ni ìwà burúkú, ẹbi burúkú, ọba ti ó nlo ipò rẹ lati rẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àti òṣèlu ti ó nja ilú ni olè lati kó owó ti wọn ji lọ si òkè òkun nibiti ohun amáyédẹrùn ti ilú wọn kò ni wà.
Gẹ́gẹ́ bi òwe Yoruba ti ó sọ wi pé “A ki sọ pé ki Wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́?” Ìtumọ̀ òwe yi ni wi pé ìpinnu pàtàki bi ìyè àti ikú kò ṣe é gbé lé wèrè lọ́wọ́. Ó yẹ ki àwọn ènìyàn gidi ti ori rẹ pé dásí ọkọ tàbi ìyàwó, ọba tàbi àwọn ti ó wà ni ipò agbára, òṣèlu ti o nfi ipò wọn jalè àti àwọn ti ó nhu ìwà burúkú yi lati din àbáyọrí ìwà burúkú lóri ẹbí, alá-dúgbò àti àgbáyé kù.
(Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Olikoye Ransome Kuti – Oníṣègùn-Ọmọdé ti gbogbo àgbáyé mọ̀, Òjíṣẹ́-Òṣèlú Nigeria ni ọdún keji-din-lọ́gbọ̀n si ọdún keji-lé-lógún sẹhin, ṣe irànlọ́wọ́ gidigidi nipa di-din “Ikú ọmọdé kù” nipa ẹ̀kọ́-ìlàjú fún gbogbo ilú àti abúlé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni, ìlàjú lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsi gbàlà lọ́wọ́ ikú igbẹ́-gburu, nipa ìmọ̀ “Omi Oni-yọ lati dipò omi ara”.
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ bi Àbíkú ti din-ku ni orilẹ̀ èdè Nigeria, nitori eyi orúkọ Àbíkú din-kù:
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún mẹrin-lé-lógún sẹhin jẹ́ Igba-lé-mẹ́tàlá
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún keji sẹhin ti din-kù si Mẹrin-lé-lọgọfa.
ENGLISH TRANSLATION
An Internationally acclaimed Paediatrician, Late Professor Olikoye Ransome-Kuti – Nigeria’s Minister of Health 1986 to 1992 contributed greatly to the reduction of Child Mortality in Nigeria through his Television/Radio Enlightenment Programme as well as promotion of Rural Health Education. Many children were saved from death through diarrhoea through his Television and Radio Enlightenment Programme on “Oral Dehydration Therapy – ORT”.
Check out example of how Child Mortality has reduced in Nigeria, hence names associated with Child Mortality has reduced. According to UNICEF statistics:
Under 5 Mortality Rate (U5MR) 1990 – 213
Under 5 Mortality Rate (U5MR) 2012 – 124
Orúkọ Yorùbá fú́n Àbíkú – Yoruba Name associated with child-mortality
Igé Kúrú Orúkọ Àbíkú – Short form of Name associated with child-mortality
Itumọ – Meaning in English
Gbókọ̀yi
Kọyi
The forest rejected this
Kòkúmọ́
Kòkú
Not dying again
Malọmọ
Malọ
Do not go again
Igbẹkọyi
Kọyi
The dungeon rejected this
Akisatan
No more rags (worn out clothes or rags were used as diapers)
Kòsọ́kọ́
No hoe (e.g. hoe is synonymous with any instrument used in digging the grave i.e. Digger, Shovel, etc
Ọkọ́ya
The hoe is broken (i.e. hoe is synonymous with any digging instruments)
Ẹkúndayọ̀
Dayọ̀
Weeping has turned to joy
Rẹ̀milẹ́kún
Rẹmi
Pacify me from weeping
Ògúnrẹ̀milẹ́kún
Rẹ̀milẹ́kún
The god of iron (Ogun) has pacified me from weeping
Olúwarẹ̀milẹ́kún
Rẹ̀mi/Rẹ̀milẹ́kún
God has pacified me from weeping
Bámitálẹ́
Tálẹ́
Remain with me till the evening/end
Fadaisi/Fadayisi
Daisi/Dayisi
“Ifa” has spared this
Ogundaisi/Ogundayisi
Daisi/Dayisi
“Ogun” has spared this
Mátànmijẹ
Mátànmi
Don’t deceive me
Jokotimi
Joko
Seat with me
Dúrójayé
Dúró/Jayé
Stay to enjoy the world
Dúró́sinmi
Dúró/Sinmi
Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent)
Dúróorikẹ
Rikẹ
Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent)
Dúrótimi
Rotimi
Stay with me
Bámidúró
Dúró
Stand with me
Jokotọla
Joko/Tọla
Seat with wealth
Adérọ́pò
Rọ́pò
He/she who came to replace
Olúwafirọ́pò
Rọ́pò/Firọ́pò
God’s replacement
Dúródọlá
Dúró/Dọlá
Wait for wealth
Kilanko
Lanko
What are we naming
Ajá
Dog
Ẹnilọlóbọ̀
Ẹnilọ
He/she who left has returned
Dúrójogún
Dúró/Jogún
Live/Stay to inherit.
Originally posted 2014-09-23 09:01:44. Republished by Blog Post Promoter
This website uses cookies to improve your experience. We'll assume you're ok with this, but you can opt-out if you wish. Cookie settingsACCEPT
Privacy & Cookies Policy
Privacy Overview
This website uses cookies to improve your experience while you navigate through the website. Out of these cookies, the cookies that are categorized as necessary are stored on your browser as they are essential for the working of basic functionalities of the website. We also use third-party cookies that help us analyze and understand how you use this website. These cookies will be stored in your browser only with your consent. You also have the option to opt-out of these cookies. But opting out of some of these cookies may have an effect on your browsing experience.
Necessary cookies are absolutely essential for the website to function properly. This category only includes cookies that ensures basic functionalities and security features of the website. These cookies do not store any personal information.
Any cookies that may not be particularly necessary for the website to function and is used specifically to collect user personal data via analytics, ads, other embedded contents are termed as non-necessary cookies. It is mandatory to procure user consent prior to running these cookies on your website.