Ìgbà tàbi àsikò mèji ló wà ni ọ̀pọ̀ ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú, ìgbà òjò àti ẹ̀rùn. Ni ayé àtijọ́, òjò ni ará ilú gbójúlé lati pọn omi silẹ̀ fún ọ̀gbẹlẹ̀. Àsikò òjò ṣe pàtàki fún iṣẹ́-àgbẹ̀, omi pi pọn pamọ́ fún li lò, àti fún ìtura lọ́wọ́ ooru.
A lè fi ìgbà òjò wé ìgbà ti orilẹ̀ èdè Nigeria pa owó rẹpẹtẹ lori epo rọ̀bì lai fi owó pamọ́. Lati ìgbà ti epo rọ̀bì ti gbòde, ilú ko kọ ara si iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ miran ti ó lè pa owó wọlé. Àwọn Ìjọba Ológun àti Alágbádá, bẹ̀rẹ̀ si ná owó bi ẹni pé ìgbà ẹ̀rùn kò ni dé. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti ji jà ilú ni olè, kò jẹ ki òjò owó epo rọ̀bì rọ̀ kári. Pẹ̀lú gbogbo owó epo rọ̀bì rẹpẹtẹ, iwà ibàjẹ́ pọ̀ si, kò si ọ̀nà ti ó dára, ilé-iwé bàjẹ́ si, ilé-iwòsàn kò ni ẹ̀rọ igbàlódé, ilú wà ni òkùnkùn nitori dákú-dáji iná-mọ̀nàmọ́ná àti ìnira yoku.
Òwe Yorùbá sọ wipé “Òjò nrọ̀, Orò nké, atọ́kùn àlùgbè ti ò láṣọ méji a sùn ihòho” Ìtumọ̀ òwe yi ni pé “Ẹni ti kò bá pọn omi de òùngbẹ nigbà òjò , a jẹ ìyà rẹ ni ìgbà ẹ̀rùn”. A lè fi òwe yi ṣe ikilọ fún àwọn Òṣèlú Alágbádá ti ó nkéde fún ibò ni lọ́wọ́lọ́wọ́ pé àtúnṣe ṣi wà lati rán aṣọ kọjá méji fún ará ilú. Ni àsikò ẹ̀rùn ti owó epo rọ̀bì fọ́ yi, ó yẹ ki àwọn Òṣèlú lè ronú ohun ti wọn lè ṣe lati yi ìwà padà kúrò ni inákuná àti lati ronú ohun ti wọn lè ṣe lati pa owó wọlé kún owó epo rọ̀bì, ki ilú lè rọgbọ lọ́jọ́ iwájú.
ENGLISH TRANSLATION
There are two main seasons in most African Countries, rain and dry season. In the olden days, people depended mostly on the rain in order to fetch and store water for the dry season. Raining season is very crucial for farming, storage of water for subsequent use and cooling off the heat.
Raining season can be compared with when Nigeria made a lot of revenue from Crude Oil without saving. Since the discovery of Crude Oil in commercial quantity, farming and other skilful jobs that could have contributed to the national revenue has been neglected. Both the military and democratic government began to squander the revenue as if there will never be dry season such as the crude oil price crash. Corruption and public fund looting did not allow the rainfall of crude oil revenue reach the populace. Despite the huge crude oil revenue, indiscipline increased, no good road, schools became dilapidated, hospitals lacked modern equipment and the country remained in darkness as a result of the constant power outage and other problems.
Yoruba proverb said “The rain is falling and the call of the secret cult is sounding loudly outside, the shuttle that lacks a change of clothing will sleep naked”. This means, “If one does not make provision during the raining season, one is bound to suffer hardship during the dry season”. This proverb can be used to caution the politicians that are currently canvassing for the peoples’ votes that there is still room for improvement to increase the number of the people’s clothing. As it is now the dry season, caused by the crude oil price crash, it is apt for the politicians to think of the strategies of changing the attitude of squandering public funds and come up with ideas of increasing revenue from other sources in addition to the crude oil revenue so as to secure the future.
Originally posted 2015-02-06 09:30:04. Republished by Blog Post Promoter