Ijọba Nigeria sún idibò kúrò ni oṣù keji, ọjọ́ kerinla si oṣù kẹta, ọjọ́ kejidinlogbon ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún nitori àwọn Ológun ni àwọn kò lè daabo bo ará ilú ni àsikò idibò. Wọn ni àwọn fẹ dojú ijà kọ ẹgbẹ́ burúkú ti a mọ̀ si “Boko Haram”.
Àwọn ará ilú fi ibinú han nipa ki kọ isún siwájú ọjọ́ idibò, ṣùgbọ́n nigbati Olóri Ilé-iṣẹ́ Idibò Attahiru Jega ṣe àlàyé wi pe,́ ẹmi àwọn òṣìṣé idibò ṣe pàtàki, ohun kò lè fi ẹ̀mi wọn wewu nitori eyi, ó rọ ará ilú lati gba ọjọ́ tuntun ti wọn sún idibò si.
Àwọn ti ó ndu ipò Òṣèlú fi si sún idibò siwájú polongo lati rọ àwọn ará ilú fún ibò wọn. Eleyi fa inira fún àwọn awakọ̀ pàtàki ni ilú Èkó, ó si tún ba ọrọ̀ ajé jẹ́. Ọjọ́ Idibò naa ló wọlé dé wẹ́rẹ́ yi nitori ó di ọ̀la. Bi ará ilú bá fẹ́ ki àyipadà rere dé si ìyà a kò si iná, kò si omi àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé, a rọ àwọn ọmọ Nigeria rere ki wọn tu jade lati ṣe ojuṣe wọn lati lọ dibò yan ẹni ti wọn ba lero wi pé ó lè ṣe àtúnṣe si ipò Òṣèlú tuntun.
Ẹgbẹ́ gbigbé àṣà àti èdè Yorùba lárugẹ gbadura pé ki ó má si ogun tàbi ijà ni àsikò àti ki ilú tura lẹhin idibò.
ENGLISH TRANSLATION
The Nigerian Government postponed the election date from February fourteen to March twenty-eight, 2015 because the Military declared that they could not guarantee security during the earlier scheduled Electoral Date in order to face the fight with the terrorist group known as “Boko Haram”.
The public reacted to the election postponement in anger, but when the Chairman of Independent National Electoral Commission (INEC) Professor Attahiru Jega explained that the live of electoral workers are very important hence he could not risk their lives. As a result, he pleaded with the public to accept the new electoral dates.
Those vying for political positions seized the opportunity to extend their campaign to canvass for the people’s vote. These caused hardship for commuters especially in Lagos and it affected commerce. The new electoral date is now here and will be held the next day. If the people want “Change” from suffering as a result of no light, water or decaying modern infrastructure, we appeal to responsible Nigerians to go out in large numbers to exercise their voting rights to elect those they believe could serve the people well.
The Yoruba Blog Team pray that there will be no violence and for peace during and after the election.