Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù. Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku. Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀. Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ. Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nitori bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn.
Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé (ẹiyẹ ọsin)ni, Adiẹ (Àkùkọ àti Àgbébọ̀ adiẹ), Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó/Odidẹrẹ́ àti Ọ̀kín. Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni: Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Igún/Àkàlàmàgbò àti Lekeleke. Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn. Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi.
Agbe ló laró ————— ki rá ùn aró
Àlùkò ló losùn ———— ki rá ùn osùn
Lekeleke ló lẹfun ——– ki rá ùn ẹfun
Ka má rá ùn owó, ka má rá ùn ọmọ
Ohun tá ó jẹ, tá ó mu, kò mà ni wọn wa ò.
ENGLISH TRANSLATION
Ostrich is the biggest and has the largest eggs among the birds. The long neck and legs made it taller than all the other birds. Ostrich is also the fastest runner on land more than all the birds. This is why Yoruba crowned Ostrich as the King of Birds. Many wild birds such as Ostrich are almost extinct as a result of the expansion of towns and cities displacing the wild birds which can now be seen at the Zoo.
There are various types of birds in Yoruba land, the most common at home or in town (domestic birds) are: Chicken (Cock and Hen), Duck, Pigeon, Guinea Fowl, Parrot, and Peacock. The common wild birds that are known in the town or communities are: Falcon/Kite, Eagle, Owl, Vulture and Cattle-egret. Birds are of various colours, one species of bird can come in various colours, while some are black like the dye, some are red like the camwood, and some are white, but the Yoruba song on this page depicted the common colours that are peculiar with some species of birds. For example, Cattle-Egret are white like chalk, Blue Turaco are coloured like the dye and Red Turaco are reddish like the camwood. Check out the pictures and prononciation of some of the birds that are common in Yoruba land on this page.
Originally posted 2014-10-17 12:27:16. Republished by Blog Post Promoter