Ọlọpa ti fi iyà jẹ ará ilú fún igbà pípẹ́, nitori iwà-ibàjẹ́ àti gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ni iṣẹ́ Ọlọpa àti ni orilẹ̀-èdè Nigeria. Ọlọpa ti tori àti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fi iyà jẹ ọlọ́jà, àgbẹ, oníṣẹ́ọwọ́ àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ tàbi pa ọlọ́kọ̀. Wọn kò mọ àgbà yàtọ̀ si ọ̀dọ́ lati kó enia si àtìmọ́lé lainidii, ṣùgbọn wọn kò jẹ ṣe iwà burúkú yi fún Òṣèlú ti wọn ńjalè orilẹ̀-èdè àti olówó ti ó ngbé Ọlọpa kiri. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilú ló ti jẹ ìyà lọ́wọ́ Ọlọpa tàbi mọ enia ti ó jẹ iya lainidii. Bi ẹni pé iwa burúkú Ọlọpa kò tó, Ìjọba dá “Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè” silẹ̀ lati ara Ọlọpa. Orúkọ Ọlọpa kò dára tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Ọlọpa Pàtàki yi bẹ̀rẹ̀ si gbógun ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ti kò ṣẹ̀, wọn kò bikità fún ẹ̀mi. Ìwà-ibàjẹ́ ti àwọn Ọlọpa Pàtàki yi burú ju ti àwọn adigun-jalè lọ.
Òwe Yorùbá wi pé “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun”. Òṣùwọ̀n Ọlọpa Pàtàki kún ni ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàá, àwọn ọ̀dọ́ tú jade lati kọ̀yà Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè. Lẹhin idákẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn ọ̀dọ́ ṣe ipinu lati “Sọ̀rọ Sókè” ni pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, ṣùgbọ́n jàndùkú àwọn Òṣèlú àti Ọlọpa bẹ̀rẹ̀ si dà wọ́n rú. Àwọn ọ̀dọ́ ni “Ó tó gẹ́”, wọn tẹnumọ pé wọn kò fẹ Ọlọpa Pàtàki fún Ìgbógun ti Adigun-jalè mọ́.
Ni alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ogún ọjọ́, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàá, àwọn tó wọ aṣọ Ológun yinbọn lati tú àwọn ọ̀dọ́ ti ó dúró lati kọ̀yà ni òpópó Lẹkki/Ẹ̀pẹ́ ni ipinlẹ̀ Èkó. Ni àárọ̀ Ọjọrú, ọjọ́ kọkànlélógún, ìroyin kàn pé ibọn ti àwọn tó wọ aṣọ Ológun yin si àárin èrò, ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ leṣe àti okùnfà ikú omiran, nitori eyi, ìlú Èkó gbaná. Lára ibi ti àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ni, ọkọ̀ akérò ipinlẹ̀ Èkó, ilé iṣẹ amóhùnmáwòrán, ilé ìyá Gómínà ipinlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú, ilé-iṣẹ́ Bèbè Odò àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Jàndùkú da Àfin Ọba Akinolú ti ilú Èkó rú wọn si gbé ọ̀pá oyé.
Gbogbo Akọ̀wé Èdè Yorùbá lóri ayélujára rọ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ ti ó ńbínú pé ki wọn fọwọ́ wọ́nú, ki wọn dẹkun àti ba ọrọ̀ ipinlẹ̀ Èkó jẹ́. Ki Èdùmàrè tu idilé àwọn ti ó kú ninú.
ENGLISH TRANSLATION
Nigerian Police has always been brutal towards Nigerians in their efforts to extort bribe due to the level of corruption in the Police and Nigeria. Drivers, traders, farmers etc had fallen victim or killed by Police over bribe. Police was no respecter of the young or old in locking people up for no just cause, except the politicians and the rich ones moving around with escort. As if the reputation of the Police was not bad enough, Special Anti-Robbery Squad (SARS) was formed using staffing from existing Nigerian Police. Overtime, SARS began to terrorise mostly the youths on trump up charges without respecting lives. SARS became worse than the armed-robbers.
According to a Yoruba adage, “Every day is for the thief, but one day is for the victim”. On October 8, 2020, SARS’ cup was full as the youths trooped out to protest their brutality. After many years of tolerance, the youths decided to “Speak Out” with a peaceful protest, but political thugs and Police disrupted days of peaceful protest. The youths, however, continued to demand for “End of SARS”.
On Tuesday evening, October 20, 2020, men dressed in army/military uniform disrupted the peaceful protest along Lekki/Epe Highway, Lagos, by shooting to disperse the crowd. As the news of the casualty of this attack emerged on Wednesday, October 21, 2020, Lagos was on fire, some Lagos public buses (BRT), Television Station (TVC), Lagos Governor Babajide Sanwo-Olu’s mother’s house, Nigerian Port Authority building etc were all set on fire. The Palace of Lagos Monarch Akinolu was vandalized and his staff of Office taken away.
The Yoruba Blog Editorial Team (an online publication) use this opportunity to appease to the protesting youths to desist from disrupting Lagos commerce and destruction of properties. May God console the families of those who died during the protest demanding abolition of Special Anti-Robbery Squad – “End SARS”.
Originally posted 2020-10-22 19:34:49. Republished by Blog Post Promoter