Gẹ́gẹ́bí Ọba nínú Olórin ti ógbé àṣà àti orin Yorùbá lárugẹ lagbaaye (Ọba orin Sunny Ade) ti kọ wípé: “Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó”, òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ni lati gún iṣu lódó kí ó tó di Iyán, ṣùgbọ́n fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó ní ìfẹ́ oúnje abínibí tí ó wà ni Ìlúọba/Òkèòkun, a ò gún iṣu lódó mọ, a ro lórí iná bí ìgbà ti a ro Èlùbọ́ to di Àmàlà ni.
Ìyàtọ̀ tó wà laarin Èlùbọ́ tó di Àmàlà àti iṣu tó di Iyán tí a rò nínú ìkòkò ni wípé, Àmàlà dúdú, Iyán funfun, ṣùgbọ́n Àmàlà fẹ́lẹ́ ju Iyán lọ. A ní lati ṣe àlàyé fún àjòjì wípeí ara iṣu ni Èlùbọ́ tó di Àmàlà ti jáde gẹ́gẹ́bi Iyán ti jáde lára Iṣu.
Ọbẹ̀ oriṣiriṣi bi ẹ̀fọ́ elegusi, ilá àsèpọ, àpọ̀n (Ọgbọnnọ), ewédú àti gbẹ̀gìrì, ẹ̀gúsí funfun àti bẹbẹ lọ la lè fi jẹ Iyán àti Àmàlà. Bi ẹ̀fọ́ ẹlẹgusi ti jẹ ọ̀rẹ́ gidi fún Iyán laarin gbogbo ọbẹ̀, bẹni gbẹgìrì pẹ̀lú Ewédú (Àbùlà) jẹ ọ̀rẹ́ gidi fún Àmàlà.
A ṣe àkíyèsí wípé àwọn Yorùbá ní ilé fẹ́ràn oúnje òkèrè ju oúnje ilẹ̀ wa lọ ju àwọn tí ó wà ni Òkèokun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ẹ̀ bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu oúnje Yorùbá wípé o jẹ ki wọn sanra ṣùgbọ́n, ohun gbogbo ni ìwọ̀túnwọ̀nsìn ló yẹ, oúnjẹ ilẹ̀ wa ṣe ara lõre ju ki a gba àrà oúnjẹ òkèrè lọ.
Ẹ gbe oúnjẹ Yorùbá lárugẹ, Iyán àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ ẹlẹgusi àti Àmàlà pẹ̀lú gbẹ̀gìrì àti Ewédú dún ládùnjù.
ENGLISH TRANSLATION
According to the King of Music, who promoted Yoruba culture and music worldwide (King Sunny Ade), his song lyrics said “Before Yam becomes Pounded Yam, it is pounded in a mortar”, this adage is true as Yam is pounded to turn it to Pounded Yam. However, for the convenience of lovers of traditional meals living in Europe/Oversea, Yam is no longer pounded in a mortar but cooked in a pot just like that of Yam Flour Meal.
The difference between Pounded Yam (Iyan) and Yam Flour Meal (Amala) prepared in the pot is that Yam Flour Meal comes out in dark colour while Pounded Yam comes out white, but Yam Flour Meal is lighter than Pounded Yam. The need to explain that both meals are by-products of Yam to Foreigners is because of the colour of the finished meal.
Many types of soup/sauce such as Vegetable with Melon, Mixed Okra, powdered wild mango fruit sauce, Ewedu/Craincrain/Cochorus mixed with Beans sauce, melon soup etc can all be used to accompany Pounded Yam and Yam Flour Meal.
It is observed that Yorubas living in Nigeria are showing more preference for foreign food than those living abroad. Many are even degrading these meals as a source of putting on weight, but if everything is done in moderation, Yoruba food is more, healthy than many foreign food.
Promote Nigerian food, Pounded Yam eaten with Vegetable soup/sauce, Yam Flour Meal with Ewedu/Cochorus mixed with Beans soup is very tasty.
Originally posted 2015-03-17 09:20:09. Republished by Blog Post Promoter