http://odili.net/news/source/2013/jun/16/517.html
Kikọ ọmọ lati ṣe “Ọmọlúàbí” jẹ́ ohun ti àwọn òbí ayé àtijọ́ ndù ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí ayé òde òní tó ndu owó lati kó ọrọ̀ jọ ju wípé ká kọ́ ọmọ lọ. Kíka ọrọ ìfojúkojú nínú ìwé ìròyìn (Sun) fihàn wípé ẹ̀kọ́ ti ìyá àti bàbá bá kọ́ ọmọ ni kékeré wúlò fún ẹbí àti ará lọ́jọ́ iwájú. Ẹkọ ti Gómìnà Fáṣọlá gbà lọ́wọ́ òbí wúlò fún ẹbí, ará àti ìlú Èkó.“Bí orí bá pẹ́ nílẹ̀ á dire”, bi o tiẹ jẹ wípé Gómìnà Fáṣọlá kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ Òṣèlú, orí darí rẹ síbẹ̀. Òwe Yorùbá ni “Orí olókìkí kò jẹ́ asán, wọ́n nkigbe ẹ nílé, wọ́n nkigbe ẹ́ logùn”, nitõtọ Gómìnà Fáṣọlá gbìyànjú fún ìlú Èkó, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ.
Góm̀nà, ẹ kú orire adọọta ọjọ́ ìbí, orire naa dalẹ́, ẹ̀mí ọlá á gùn lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ìbí láyé o (Àṣẹ).
Èkó ò ní bàjẹ́ o!!!
ENGLISH TRANSLATION
Teaching the children to be a “Gentleman” is what the parents of old aspired to instil on the children, unlike the parents of nowadays that are striving to acquire so much wealth in place of moral character. Reading the interview granted to the Sun Newspapers showed that the virtue inculcated in the children while they are young becomes very useful to the family and other people in future. The moral character passed on to Gov. Fashola by his parents while he was young has become useful for his family and Lagos State.
Yoruba adage that “If the head remains long on earth, it becomes fortunate” showed that even though Gov. Fashola did not set out as a Politician/Public Servant, fate directed him towards that path. According to the “Yoruba Proverbs” by Oyekan Owomoyela’s translation “The lot of a valorous person is not simple, he is called upon at home and he is called upon in battle (A great person is subject to demands from all sides)”, it could also mean “Uneasy lies the head that wears the crown”. Gov. Fashola is striving hard in Lagos State but there is an awful lot to do.
Congratulations Governor, may joy of the celebration of your 50th birthday continue to the end, and may you live long to celebrate many more birthdays on earth (Amen).
Long live Lagos State!!!