“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”

Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́.  Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara.    Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi.  Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.

Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo  èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò.  Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku.  Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni.  Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.

A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ.  Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION

Gold is one of the precious mineral, particularly for Jewellery.  The beauty of Gold is not shown, until all the impurities are removed through the furnace.  The pictures on this page showed that the more gold dust is included in Jewellery, the more costly it is, not as glittering or as big.  For example, the Jewellery set in the first picture is big and glittering more than the second set, whereas the second Jewellery set is ten times more expensive.   The difference between gold and imitation, real gold continues to appreciate even after usage, it does not fade, when broken it can be repaired but some sensitive skins react to imitation or costume jewellery, when broken, it cannot be repaired, its value does not appreciate.

According to Yoruba proverb that said “Not all that glitters is Gold”, so also, it is not all the people regarded as rich or wealthy are as rich or wealthy.  Many of these perceived rich or wealthy ones use indebtedness to acquire possession in order to show off or have acquired their wealth through dubious means such as stealing, kidnapping and other devilish means.  All they have acquired through fraud are often nothing in comparisim to other humble wealthy people.  For example, the money embezzled by African Politicians and Government workers that are being siphoned abroad or used to enslave their people, is not as much as that of talented young ones abroad.

The Proverb “Not all that glitters is gold” can be used to encourage people not imitate or desperate to acquire wealth.  Imitation is dangerous because things seen may not be as real as it appeared.

 

Share Button

Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.