Ìròyìn ti o jade ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹwa, oṣú karun, ọdún Ẹgbàá-le-mẹ́rìndínlógún, sọ wi pé Olóri Òṣèlú Ilú Ọba, David Cameron pe orilẹ̀ èdè Nigeria ni ilú ti ó hu iwà ibàjẹ́ jù ni àgbáyé. Kò ṣe àlàyé bi Ì̀jọba ilú rẹ ti ngba owó iwà ibàjẹ́ pamọ́ lati fi tú ilú wọn ṣe.
Ẹni gbé epo lájà, bi kò bá ri ẹni gba a pamọ́, kò ni ya lára lati tún ji omiran. Bi kò ri ẹni gba a, ó lè jẹ epo na a tàbi ki ẹni tó ni epo ri mú ni wéré. Gẹgẹ bi òwe Yorùbá ti sọ pé “Ẹni gbé epo lájà, kò jalè̀ tó ẹni gba a”, bi àwọn ti ó n fi ọna èrú àti iwà ibàjẹ́ ja ilú lólè, kò bá ri àwọn Ilú Ọba gba owó iwà ibàjẹ́ lọ́wọ́ wọn, iwá burúkú á din kù.
Ogun ti Ìjọba tuntun ni Nigeria gbé ti iwà ibàjẹ́ lati igbà ti ará ilú ti dibò yan Ìjọba tuntun -Muhammadu Buhari àti Yẹmi Osinbajo, ni bi ọdún kan sẹhin ni lati jẹ ki àwọn tó hu iwa ibaje jẹ èrè iṣẹ́ ibi, ki wọn si gba owó iwà ibàjẹ́ padà si àpò ilú. Eyi ti ó ṣe pàtàki jù ni ki Ìjọba Ilú Ọba ṣe àlàyé bi wọn yio ti da àwon owó Nigeria padà ni ipàdé gbi gbógun ti iwa ibaje, ki wọn lè fihan pé àwọn kò fi ọwọ́ si iwà ibàjẹ́.
ENGLISH TRANSLATION
The news on Tuesday, the tenth day of May, 2016, quoted the British Prime Minister, David Cameron calling Nigeria one of the most corrupt nation in the world. He did not explain that his country has been aiding and abetting corruption by keeping looted funds and making United Kingdom a safe haven for the looters.
Palm Oil is an agricultural produce of economic value particularly in West Africa, hence it was kept often on the ceiling in time past. If anyone stole palm oil from the ceiling where it is kept, and there is no one to receive it, it is either he/she personally consume it or could have been caught quicker. According to Yoruba proverb that can be interpreted thus, “An accomplice is worse than the offender”. If the corrupt treasury looters have no accomplice in the UK, such wicked act could have been minimized.
The war being waged against corruption since the newly elected government nearly a year ago, by Muhammad Buhari and Yemi Osinbajo led administration, for treasury looters to face the consequences for their corrupt practices and the stolen fund to be refunded to the Nigerian purse, is commendable. The British government should pledge during the Anti-corruption Summit schedule to take place in the UK on Thursday, May 12, 2016, their support at recovering the various looted funds and refunding such funds to Nigeria to show that the UK is not an accomplice.
Originally posted 2016-05-10 23:45:13. Republished by Blog Post Promoter