Bi a ba fi eti si ọ̀rọ̀ ti àgbà Yorùbá Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ni ori ẹ̀rọ “Amóhùnmáwòrán Òpómúléró”, ni ori ayélujára, a o ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọnyi:
Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ fi àṣà Yorùbá ti ó ti ńparẹ́ hàn nipa bi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú “Oríkì”
Nínú ìtàn lati ẹnu agba, a o ri pé Bàbá loye lati kékeré. Nkan bàbàrà ni ki ọmọ jade ni ilé ìwé giga ni ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ki ó si gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n. Ni ọdún Ẹgbàádínméjìdínlógójì, Gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ẹ̀kọ́ Ìṣirò, Ìjọba Ipinlẹ Ìwọ Oòrùn ayé ìgbà yẹn kò sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ kéré jú lati fún ni ipò Alaṣẹ lóri iṣẹ́ Ìdàgbàsókè Ìtọ́jú Owó.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ fihàn pé, lai si ni ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, kò ni ki á di ọ̀tá bi ti ayé òde òní. A ri àpẹrẹ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ ṣe súnmọ́ Olóògbé Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tó, bi ó ti jẹ́ wi pé wọn kò si ninú ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, àwọn méjèèji jẹ olootọ ti ó si ni ìgboyà.
Ọgbọ́n ki i tán, bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ti kàwé tó, Bàbá ṣi ńkàwé lati wá ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ọgbọ́n púpọ̀ wà ni ọ̀rọ̀ àgbà yi, ẹ ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yi lóri Amóhùnmáwòrán Òpómúléró.
ENGLISH TRANSLATION
Listening to the words of one of the distinguished Yoruba elders, Dr. Omololu Olunloyo on an online Opomulero TV, the following were observed:
Dr. Olunloyo began by reciting his family lineage odes (Oriki) one of the Yoruba culture that is almost extinct.
Deducing from the words of the elder, one would notice a man who had always been brilliant from his young age. It was a big deal/mean fit to graduate from the University/College at age twenty-three (23) and obtain a Doctoral Degree (PhD) at age twenty-six (26) in those days and even now. In 1962, Dr. Victor Omololu Olunloyo became Commissioner at age twenty seven (27). As a distinguished Mathematician, the Western Region Politicians did not regard him as too young before giving him the portfolio as a Commissioner for Economic Development.
Dr. Omololu Olunloyo showed that not being in the same political party does not have to lead to enmity as it is common nowadays. For example, he was not in the same political party with Late Chief Obafemi Awolowo, yet he was very close to him because they had a lot in common as they were both forthright and fearless.
Dr. Omololu Olunloyo declared that knowledge is unlimited as he still continued to seek more knowledge through reading. There is a lot of lessons from this elder video, watch this on Opomulero TV.
Originally posted 2018-03-30 20:39:07. Republished by Blog Post Promoter