Category Archives: Yoruba Folklore

“Ìtàn Ìjà laarin Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Asin – Ìgbẹ̀hìn Ìjà fún Asin àti òfófó fún Ìjàpá kò bímọ ire” – “The fight between the Squirrel and the Rat (with a long mouth) and the Consequence of Gossiping for the Tortoise”.

Ni ayé igbà kan ri, àwọn ẹranko ni ọjà ti wọn.  Ni ọjọ́ ọjà, Kìnìún, Ajá, Ìgalà, Ikõkò, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Erin, Ẹkùn,  Ìjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku gbé irè oko àti ẹrù fún títà wá si ọjà.  Erin ni Olóri ọjà, Kìnìún ni igbá keji.  Gbogbo ẹranko mọ àlébù ara wọn.  Wọn mọ̀ pé Asin fẹ́ràn ijà, bẹni òfófó àti àtojúbọ̀ ni àlébù Ìjàpá.

Àjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku - Tortoise and other animals.

Àjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku – Tortoise and other animals.

Ni ọjọ́ kan, ijà bẹ́ silẹ̀ laarin Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Asin.  Ki ṣe pé àwọn ẹranko yoku kò lè làjà yi, ṣùgbọ́n wọn rò pé Asin ti tún gbé iṣe rẹ̀ dé nitori ó fẹ́ràn ijà, nitori eyi, wọn kò dá si ijà.  Ìjàpá fi ìsọ̀ rẹ̀ silẹ̀, ó sá lọ wòran ijà.  Nigbati ó dé ibi ijà, ó rò pé Asin lágbára ju Ọ̀kẹ́rẹ́ lọ, ó kó si wọn laarin.  Eku-Asin kò fẹ́ràn Ìjàpá nitori ki gbọ tara ẹ, nitori eyi, inú bi i, ó fi Ọ̀kẹ́rẹ́ silẹ̀, ó kọjú ijà si Ìjàpá.  Ó fi ibinú gé imú Ìjàpá jẹ.  Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ si ké igbe pẹ̀lú orin yi nitoÌri ki àwọn ẹranko yoku lè gba ohun lọwọ Asin:

Asín tòhun Ọ̀kẹ́rẹ́ —————– jo mi jo
Àwọn ló jọ njà ———————- jo mi jo
Ìjà ré mo wá là ———————-jo mi jo
Asín wá fi mí ni mú jẹ ———— jo mi jo
Ẹ gbà mí lọwọ́ rẹ̀ —————— jo mi jo
Àwò mí mbẹ lọ́jà ——————-jo mi jo

Àwọn ẹranko yoku kọ̀ lati gba Ìjàpá lọwọ Asin, dipò ki wọn làjà gẹ́gẹ́ bi orin arò Ìjàpá, yẹ̀yẹ́ ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe, pé Ìjàpá ri ẹ̀san òfófó.  Nigbati Ìjàpá ri pé àwọn ẹranko yoku kò ṣetán lati gba ohun, ó lo ọgbọ́n inú rẹ̀ lati tu ara rẹ̀ silẹ̀.  Ó fa imú rẹ àti ẹnu Asin wọ inú ikarawun rẹ, ó pa ikarawun dé mọ ẹnu Ọ̀kẹ́rẹ́.  Asin bẹ̀rẹ̀ si jà pàtàpàtà lati tú ẹnu rẹ̀ silẹ̀. Bi ó ti dura bẹni ẹnu rẹ̀ gùn si titi ó fi já.  Ìjà yi ló sọ Asin di ẹlẹ́nu gígùn, ti ó sọ  Ìjàpá di onímú kékeré titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé kò si èrè rere ninú ijà tàbi iwà òfófó nitori igbẹhin àlébù wọnyi ki i dára.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-01 06:30:37. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn iyàwó ti ó fi ẹ̀mi òkùnkùn pa iyá-ọkọ: Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni” – The story of how a daughter-in-law killed her mother-in-law in mysterious circumstance – We can only be sure of who we love, but not sure of who loves us”

Ìtàn ti ó wọ́pọ̀ ni, bi iyá-ọkọ ti burú lai ri ìtàn iyá-ọkọ ti ó dára sọ.  Eyi dákún àṣà burúkú ti ó gbòde láyé òde òni, nipa àwọn ọmọge ti ó ti tó wọ ilé-ọkọ tàbi obinrin àfẹ́sọ́nà ma a sọ pé àwọn ò fẹ́ ri iyá-ọkọ tàbi ki iyá-ọkọ ti kú ki àwọn tó délé.

Ni ayé àtijọ́, agbègbè kan na a ni ẹbi má ngbé – bàbá-àgbà, iyá-àgbà, bàbá, iyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, iyàwó àgbà, iyàwó kékeré, ìyàwó-ọmọ, àwọn ọmọ àti ọmọ-mọ.  Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀ kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ, ẹbi ti fúnká si ilú nlá àti òkè-òkun nitori iṣẹ́ ajé àti iṣẹ́-ijọba.

Ni ọ̀pọ̀ ọdún sẹhin, iyá kan wà ti a o pe orúkọ rẹ ni Tanimọ̀la ninú ìtàn yi.  Ó bi ọmọ ọkùnrin meje lai bi obinrin. Kékeré ni àwọn ọmọ rẹ wà nigbati ọkọ rẹ kú.  Tanimọ̀la fi ìṣẹ́ àti ìyà tọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbogbo àwọn ọkùnrin na a si yàn wọn yanjú.  Nigbati wọn bẹ̀rẹ̀ si fẹ́ ìyàwó, inú rẹ dùn púpọ̀ pé Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ si dá obinrin ti ohun kò bi padà fún ohun.   Ó fẹ́ràn àwọn ìyàwó ọmọ rẹ gidigidi ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ rẹ  kó lọ si ilú miran pẹ̀lú ìyàwó wọn nitori iṣẹ́.  Àbi-gbẹhin rẹ nikan ni kò kúrò ni ilé nitori ohun ló bójú tó oko àti ilé ti bàbá wọn fi silẹ.  Nigbati ó fẹ ìyàwó wálé, inú iyá dùn pé ohun yio ri ẹni bá gbé.  Ìyàwó yi lẹ́wà, o si ni ọ̀yàyà, eyi tún jẹ́ ki iyá-ọkọ rẹ fẹ́ràn si gidigidi.

Yorùbá ni “Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni”.  Tanimọ̀la kò mọ̀ pé àjẹ́ ni ìyàwó-ọmọ ti ohun fẹ́ràn, ti wọn jọ ngbé yi.  Bi Tanimọ̀la bá se oúnjẹ, ohun pẹ̀lú ọmọ àti ìyàwó-ọmọ rẹ ni wọn jọ njẹ ẹ.  Bi ìyàwó bá se oúnjẹ, á bu ti iyá-ọkọ rẹ.  Kò si ìjá tàbi asọ̀ laarin wọn ti ó lè jẹ ki iyá funra.

Yam pottage

àsáró-iṣu – Yam Pottage. Courtesy: @theyorubablog

Yorùbá gbà pé ohun burúkú ni ki enia jẹun lójú orun.  Ni ọjọ́ kan, iyá ké lati ojú orun ni bi agogo mẹrin ìdájí òwúrọ̀, pe ìyàwó-ọmọ ohun ti fún ohun ni oúnjẹ jẹ ni ojú orun.  Ìyàwó-ọmọ rẹ kò sẹ́, bẹni kò sọ nkan kan.  Ọkọ rẹ kò gba iyá rẹ gbọ.  Lati igbà ti iyá ti ké pé ohun jẹ àsáró-iṣu ti ìyàwó-ọmọ ohun gbé fún òhun jẹ lójú orun ni inú rirun ti bẹ̀rẹ̀ fún iyá.  Inú rirun yi pọ̀ tó bẹ gẹ ẹ ti wọn fi gbé Tanimọ̀la kúrò ni ilé fún ìtọ́jú.  Wọn gbiyànjú titi, kò rọrùn, nitori eyi, Tanimọ̀la ni ki wọn gbé ohun padà lọ si ilé ki ohun lọ kú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-07 17:41:39. Republished by Blog Post Promoter

ÌJÀPÁ JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: The Tortoise is Punished for not Heeding to a Warning

ÌJÀPÁ/Àjàpá JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: THE RESULT OF DISOBEDIENCE AND GREED

The African tortoise

The tragic Tortoise — having eaten food made for his wife by the Herbalist — there really should have been a warning as to consequence. Image is courtesy of @theyorubablog

Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá/Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí.  Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn.  Yáníbo ko dúró lásán, ó tọ Babaláwo lọ láti ṣe ãjo bí òhun ti le ri ọmọ bí.

Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo.  Babaláwo kìlọ̀ fún Ìjàpá gidigidi wípé õgùn yí, obìnrin nìkan ló wà fún, pé kí o maṣe tọwò.  Ìjàpá ọkọ Yáníbo ṣe àìgbọràn, ó gbọ õrùn àsèjẹ, ó tanwò, ó ri wípé ó dùn, nítorí ìwà wobiliki ọkánjúwà, o ba jẹ àsèj̀ẹ tí Babaláwo ṣe ìkìlọ̀ kí ó majẹ. Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú.  Yorùbá ni “ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ”.  Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ:

Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀,  Alugbirinrin 2ce
Õgùn to ṣe fún mi lẹ́rẹkan, Alugbinrin
Tóní nma ma fọwọ́ kẹnu, Alugbinrin
Tóní nma ma fẹsẹ kẹnu,  Alugbinrin
Mo fọwọ kan ọbẹ̀, mo mú kẹnu, Alugbinrin
Mofẹsẹ kan lẹ mo mu kẹnu, Alugbinrin
Mobojú wo kùn o ri gbẹndu, Alugbinrin
Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, Alugbinrin 2ce

Play the Tortoise’ tragic song here:

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: Babalawo mo wa bebe(mp3)

Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀.  Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú.

Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú.  Ìtàn Yorùbá yi wúlò lati ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ti o nwa owó òjijì nípa gbígbé õgùn olóró mì lati kọjá lọ si òkè okun/Ìlúòyìnbó lai bìkítà pé, bí egbògi olóró yí ba bẹ́ si inú lai tètè jẹ́wọ́, ikú ló ma nfa.  Ìtàn nã bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-21 10:45:28. Republished by Blog Post Promoter

Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù – Ìtàn Bàbá tó kó gbogbo ogún fun Ẹrú – “One who owns the Slave owns the Slave’s property too” – The Story of a Father who bequeathed all to his Slave

Àwọn Alágbàṣe ni Oko -Labourers in the farm

Àwọn Alágbàṣe ni Oko -Labourers in the farm

Ni ayé igbà kan ri ki ṣe oye ọkọ, ilé gogoro, aṣọ àti owó ni ilé-ìfowó-pamọ́ ni a fi nmọ Ọlọ́rọ̀ bi kò ṣe pé oye Ẹrú, Ìyàwó, Ọmọ, Ẹran ọsin àti oko kòkó rẹpẹtẹ ni a fi n mọ Ọlọ́rọ̀.   Ni àsikò yi, Bàbá kan wa ti ó ni Iyawo púpọ̀, Oko rẹpẹtẹ, ogún-lọ́gọ̀ ohun ọsin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ẹrú tàbi Alágbàṣe, Ọmọ púpọ̀, ṣùgbọ́n ninú gbogbo ọmọ wọnyi, ikan ṣoṣo ni ọkùnrin.  Bàbá fi ikan ninú gbogbo Ẹrú ti ó ti pẹ́ pẹ̀lú rẹ, ṣe Olóri fún àwọn Ẹrú yoku.  Ẹrú yi fẹ́ràn Bàbá, ó si fi tọkàn-tọkàn ṣe iṣẹ́ fún.

Nigbati Bàbá ti dàgbà, ó pe àwọn àgbà ẹbí lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ bi wọn ṣe ma a pín ogún ohun lẹhin ti ohun bá kú nitori kò si iwé-ìhágún bi ti ayé òde oni.  Ó ṣe àlàyé pé, ohun fẹ́ràn Olóri Ẹrú gidigidi nitori o fi tọkàn-tọkàn sin ohun, nitori na a, ki wọn kó gbogbo ohun ini ohun fún Ẹrú yi.  Ó ni ohun kan ṣoṣo ni ọmọ ọkùnrin ohun ni ẹ̀tọ́ si lati mu.

Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Bàbá re ibi àgbà nrè, ó ku.  Lẹhin ìsìnkú, àwọn ẹbí àti àwọn ọmọ Olóògbé pé jọ lati pín ogún.  Ni àsikò yi, ọmọ ọkùnrin ni ó n jogún Bàbá, pàtàki àkọ́bí ọkùnrin nitori ohun ni Àrólé.  Gẹgẹ bi àsọtẹ́lẹ̀, wọn pe Olóri Ẹrú jade, wọn si ko gbogbo ohun ini Bàbá ti o di Oloogbe fún.  Wọn tún pe ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ti Bàbá bi jade pé ó ni ẹ̀tọ́ lati mu ohun kan ti ó bá wu u ninú gbogbo ohun ini Bàbá rẹ, nitori eyi wọn fún ni ọjọ́ meje lati ronú ohun ti ó bá wù ú jù.  Àwọn ẹbí sun ìpàdé si ọjọ́ keje.  Inú Ẹrú dùn púpọ̀ nigbati inú ọmọ Bàbá bàjẹ́. Eyi ya gbogbo àwọn ti ó pé jọ lẹ́nu pàtàki ọmọ Bàbá nitori ó rò pé Bàbá kò fẹ́ràn ohun. Lẹhin ìbànújẹ́ yi, ó gbáradi, ó tọ àwọn àgbà lọ fún ìmọ̀ràn.

Ẹbí pé jọ lati pín Ogún – Family gathered to share inheritance

Ẹbí pé jọ lati pín Ogún – Family gathered to share inheritance

Ni ọjọ́ keje, ẹbí àti ará tún péjọ lati pari ọ̀rọ̀ ogún pin-pin, wọn pe ọmọ Bàbá jade pé ki ó wá mú ohun kan ṣoṣo ti ó fẹ́ ninú ẹrù Baba rẹ.  Ó dide, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ti ó joko, ó yan Olóri Ẹrú  gẹgẹ bi àwọn àgbà ti gba a ni ìyànjú.  Inú Ẹrú bàjẹ́, ṣùgbọ́n o ni ki Ẹrú má bẹ̀rù, Ẹrú na a ṣe ìlérí lati fi tọkàn-tọkàn tọ́jú ohun ti Bàbá fi silẹ̀.  Idi niyi ti Yorùbá ṣe ma npa a lowe pe “Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù.”

Lára ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, ó dára lati lo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n nitori “Ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ki i jẹ ki á pe àgbà ni wèrè”. Ẹ̀kọ́ keji ni pé, ogún ti ó ṣe pàtàki jù ni ki á kọ ọmọ ni ẹ̀kọ́ lati ilé àti lati bójú tó ẹ̀kọ́ ilé-iwé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-30 08:30:22. Republished by Blog Post Promoter

“Ọgbọ́n ju agbára”: Ìjàpá mú Erin/Àjànàkú wọ ìlú – “Wisdom is greater than strength”: The Tortoise brought an Elephant to Town

Ni ìlú Ayégbẹgẹ́, ìyàn mú gidigidi, eleyi mu Ọba ìlú bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ fún àwọn ará ìlú nitori kò mọ ohun ti ohun lè ṣe.  Òjò kò rọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, oorun gbóná janjan, nitorina, kò si ohun ọ̀gbìn ti ó lè hù.  Ìrònú àti jẹ àti mun bá gbogbo ará ìlú – Ọba, Olóyè, Ọmọdé àti àgbà.

Yorùbá ni “Àgbà kii wà lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ”, nitori èyí, Ọba sáré pe gbogbo àgbà ìlú àti “Àwòrò-Ifá” lati ṣe iwadi ohun ti ìlú lè ṣe ki òjò lè rọ̀.  Àwòrò-Ifá dá Ifá, ó ṣe àlàyé ẹbọ ti Ifá ni ki ìlú rú.  Ifá ni “ki ìlú mu Erin lati fi rúbọ ni gbàgede ọjà”.

Gẹ́gẹ́bi Ọba-orin Sunny Ade ti kọ́ “Ìtàkùn ti ó ni ki erin ma wọ odò, t’ohun t’erin lo nlọ”.  Ògb́ojú Ọdẹ ló npa Erin ṣùgbọ́n Olórí-Ọdẹ ti Ọba yan iṣẹ́ ẹ mi mú Erin wọ ìlú fún, sọ pé ko ṣẽ ṣe nitori “Ọdẹ aperin ni àwọn, ki ṣe Ọdẹ a mu erin”.  Ọba paṣẹ fún Akéde ki ó polongo fún gbogbo ara ilu pe “Ọba yio da ẹnikẹni ti  ó bá lè mú Erin wọ ìlú fun ìrúbọ yi lọ́lá”.  Ọ̀pọ̀ gbìyànjú, pàtàki nitori ìlérí ti Ọba ṣe fún ẹni ti ó bá lè mu Erin wọ̀lú, wọn sọ ẹmi nu nínú igbó, ọ̀pọ̀ fi ara pa lai ri Erin mú.

Laipẹ, Ìjàpá lọ bà Ọba àti Olóyè pé “ohun yio mú Erin wálé fún ẹbo rírú yi”.  Olú-Ọdẹ rẹrin nigbati o ri Ìjàpá, ó wá pa òwe pé “À nsọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú”.  Olú-Ọdẹ fi ojú di Àjàpá, ṣùgbọ́n Ìjàpá kò wo bẹ̀, ó fi ọgbọn ṣe àlàyé fún Ọba.  Ọbá gbà lati fún Ìjàpá láyè lati gbìyànjú.

Ìjàpá lọ si inú igbó lati ṣe akiyesi Erin lati mọ ohun ti ó fẹ́ràn ti ohun fi lè mu.  Ìjàpá ṣe akiyesi pé Erin fẹ́ràn oúnjẹ dídùn àti ẹ̀tàn.  Nigbati Ìjàpá padá, o ṣe “Àkàrà-olóyin” dání, o ju fún Erin ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sọ ohun ti ó báwá pé “àwọn ará ìlú fẹ ki Erin wá jẹ Ọba ìlú wọn nitori Ọba wọn ti wọ Àjà”.  Àjàpá pọ́n Erin lé, inú ẹ̀ dùn, ohun naa rò wi pé, pẹ̀lú ọ̀la ohun nínú igbó o yẹ ki ohun le jẹ ọba.  Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọba àti ará ìlú, wọn ṣe gbogbo ohun ti Ìjàpá ni ki wọ́n ṣe.    Ìjàpá àti ará ìlú mu Erin wọ ìlú pẹ̀lú ọpọlọpọ àkàrà-olóyin, ìlù, ijó àti orin yi:

Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀   ) lẹ meji
Ìwò yí ọ̀la rẹ̃,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀,
Agbada á má ṣe wéré,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Ààrò á máa ṣe wàrà,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀    ) lẹ meji

You can also download a recital by right clicking this link: Erin ká relé kó wá jọba

Inú Erin dùn lati tẹ̀ lé ará ìlú, lai mọ̀ pé jàpá ti gba wọn ni ìmọ̀ràn lati gbẹ́ kòtò nlá ti wọ́n da aṣọ bò bi ìtẹ Ọba.  Erin ti wọ ìlú tán, ó rí àga Ọba níwájú, Ìjàpá àti ará ìlú yi orin padà ni gẹ́rẹ́ ti ó fẹ́ lọ gun àga Ọba:

A o merin jọba
Ẹ̀wẹ̀kún, ẹwẹlẹ ……

You can also download a recital by right clicking this link: A o merin jọba

Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-27 09:10:22. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá àti Ìyá Alákàrà – “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun” – The Tortoise and the fried bean fritter seller – “Every day is for the thief, one day for the owner”.

Ìpolówó Àkàrà              Hawker’s advert

Àkàrà gbóná re,              Here comes hot fried bean fritters
Ẹ bámi ra àkàrà o           Buy my fried bean fritters
Àkàrà yi dùn, ó lóyin       This fried bean fritters is sweet with honey
Àkàrà gbóná re.              Here comes hot fried bean fritters

Àkàrà jẹ ikan ninu ounjẹ aládùn ilẹ̀ Yorùbá.  Ẹ̀wà (funfun tabi pupa) ni wọn fi nṣe àkàrà, wọn a bo ẹ̀wà, wọn a lọ, ki wọn to põ pẹ̀lú èlò ki wọn tó din.  A lè fi àkàrà jẹ ẹ̀ko, fi mu gaàrí tabi jẹ fún ìpanu.  Ki ṣe gbogbo enia ló mọ àkàrà din, awọn enia ma nfẹran ẹni ti ó ba mọ àkàrà din.  Àti ọmọdé àti àgbà ló fẹ́rán àkàrà.   Awọn ọmọde ma nkọrin bayi:

 

Taló pe ìyá alákàrà ṣeré,         Who is calling fried bean fritters woman for fun
Ìyá alákàrà 2ce                        Fried bean fritters seller
Ó nta sánsán simi nímú          Its smell is inviting to my nose
Ìyá alákàrà                              Fried bean fritters seller
Ó nta dòdò sími lọ̀fun             Its smelling like fried plantain in my throat
Ìyá alákàrà.                             Fried bean fritters seller

Ki ṣe enia nikan ló fẹ́ràn àkàrà, Àjàpá naa fẹ́ràn àkàrà, ṣùgbọ́n kò ri owó raa, nitori èyi “Ojú ni Àjàpá fi nri àkàrà, ètè rẹ ko baa”.  Àjàpá wá ronú ọgbọ́n ti ó lè dá lati pèsè àkàrà fún òhun àti idilé rẹ.  Ó ronú bi wọn ti lè dá ẹ̀rù ba ọmọ alákàrà ki ó lè sá fi igbá àkàrà, rẹ silẹ̀.  Ó gbé agọ̀ wọ̀, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ fi pápá́ bora.  Bi alákàrà ba ti kiri kọjá, Àjàpá a bẹ si iwájú ọmọ alákàrà, wọn a ma ko orin bayi:

 

 

Ọlirae ma gbọ̀nà,      The Spirit has taken over the Road
Tobini tobini to 2ce   Tobini, tobini to
Olóri yara lọ,              Corn meal seller go quickly
Tobini tobini to          Tobini, tobini to
Alákàrà dá dànù        Fried bean fritter seller abandon it
Tobini tobini to.         Tobini, tobini to

Ẹ̀rù ba alákàrà, á da àkàrà dà nù.  Àjàpá àti ẹbí rẹ á bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà. Yorùbá ni “Wọ́n mú olè lẹẹkan, ó ni ohun ò wá ri, tani fi ọ̀nà han olè?”.  Ọmọ alákàrà sunkún lọ si ilé, inú Ìya-alákàrà kò dùn si ọmọ rẹ nitori o pàdánù àkàrà àti owó ti o yẹ ki ó pa.  Kò gba ìtàn ọmọ rẹ̀ gbọ́, nitorina, ó gbé àkàrà fún ni ọjọ́ keji ati ọjọ́ kẹta, ọmọ tún padà pẹ̀lú ẹkún.  Ohun fúnra rẹ̀ tẹ̀lé ọmọ rẹ̀, iwin tún yọjú, àwọn mejeeji sá eré padà si ìlú lai ranti gbé igbá àkàrà.  Ìyá alákàrà gba ọ̀dọ̀ Ọba àti àgbà ìlú lọ lati sọ ohun ti ojú wọn ri.  Ọba pe awọn òrìṣà ìlú lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ba ọrọ̀ ìlú jẹ yi.  Ninu gbogbo òrìsà, Ọ̀sanyìn nikan ló gbà lati yanjú ọ̀rọ̀ yi.

Ìyá alákàrà tungbe àkàrà fún ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun àti Ọsanyin tẹ̀lé.  Bi alákà̀rà ti bẹ̀rẹ̀ si polówó, Àjàpá tún jade gẹgẹ bi iṣe rẹ̀.  Yoruba ni “Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun”.  Ìyá alákàrà àti ọmọ rẹ̀ tún méré, ṣùgbọ́n Ọ̀sanyin ti o fi ara pamọ́ dúró lati wo ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀.  Àjàpá àti àwon idile rẹ̀ jade nwọn bọ ohun ti nwọn fi bora silẹ̀ lati tún bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà.  Orí ti Àjàpá yọ jade lati jẹ àkàrà, Ọ̀sanyin fọ igi ẹlẹgun mọ lórí, awọn ẹbi rẹ̀ sálọ.  Ọ̀sanyin gbé òkú Àjàpá lọ si ọ̀dọ̀ Ọba.  Inú ará ìlú dùn nitori àṣiri olè tú.  Ọba pàṣẹ pe Àjàpá ni ki nwọn bẹrẹ fi rúbọ si Ọ̀sanyin.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe ojúkòkòrò kò lérè, bó pẹ́, bóyá àṣírí olè á tú.  Ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ – Àjàpá pàdánù ẹ̀mí nitori àkàrà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-04-11 21:40:58. Republished by Blog Post Promoter

“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.  Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.  Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn àròsọ bi obinrin ti sọ Àmọ̀tékùn di alábàwọ́n: The Folklore on how a woman turned the Leopard to a spotted animal.

Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ õjọ́ rẹ lọ.  Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje.  O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ.

Yorùbá ni “Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò”.  Nigbati obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù.  Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni.  (Ẹ ka itàn àròsọ yi ninu iwé ti M.I. Ogumefu kọ ni èdè Gẹ̀ẹ́si).

Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́.  Yorùbá ni “Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́”, nitori eyi ẹ̀kọ́ pàtàki ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-31 18:08:54. Republished by Blog Post Promoter

“Olúróhunbí jẹ́ ẹ̀jẹ́ ohun ti kò lè san”: “Olurohunbi made a vow/covenant she could not keep”

Yorùbá ka ọmọ bibi si ohun pàtàki fún ìdílé, nitori èyi, tijó tayọ̀ ni Yorùbá ma fi nki ọmọ titun káàbọ̀ si ayé.  Gẹ́gẹ́bí Ọ̀gá ninu Olórin ilẹ̀-aláwọ̀ dúdú, Olóyè Ebenezer Obey ti kọ́ “Ẹ̀bùn pàtàki ni ọmọ bibi…”.  Ìlú ti igbe ọmọ titun kò bá dún, ìlú naa ́a kan gógó.  Eleyi lo ṣẹlẹ̀ ni ìlú Olúróhunbí.

Fún ìgbà pípẹ́, àwọn obinrin ìlú kò ri ọmọ bi, nitorina, gbogbo wọn lọ si ọ̀dọ̀ Òrìṣà Ìrókò lati lọ tọrọ ọmọ.  Oníkálukú wọn jẹjẹ oriṣiriṣi ohun ti wọn ma fún Ìrókò ti wọ́n bá lè ri ọmọ bi.  Ẹlòmiràn jẹ ẹ̀jẹ́ Ewúrẹ́, òmíràn Àgùntàn tàbi ohun ọ̀gbìn.  Yorùbá ni “Ẹyin lohùn, bi ó bá balẹ̀ ko ṣẽ ko”, kàkà ki Olurohunbi, ìyàwó Gbẹ́nàgbẹ́nà, jẹ ẹ̀jẹ́ ohun ọ̀sìn tàbi ohun àtọwọ́dá, o jẹ ẹ̀jẹ́ lọ́dọ̀ Ìrókò pé ti ohun bá lè bi ọmọ, ohun yio fún Ìrókò lọ́mọ naa.

Lai pẹ́, àwọn obinrin ìlú bẹ̀rẹ̀ si bimọ.  Oníkálukú pada si ọ̀dọ̀ Ìrókò lati lọ san ẹ̀jẹ́ wọn, ṣùgbọ́n Olúróhunbí kò jẹ́ mú ọmọ rẹ̀ silẹ lati san ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́. 

Òwe Yorùbá ni  “Bi ojú bá sé  ojú, ki ohun má yẹ̀ ohun”, ṣùgbọ́n

Ọmọ titun – a baby
Ọmọ titun – a baby Courtesy: @theyorubablog

 Olúróhunbí ti gbàgbé ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́. 

Ni ọjọ́ kan, Olúróhunbí dágbére fún ọkọ rẹ̀ pé ohun fẹ́ lọ si oko ẹgàn/igbó, ó bá gba abẹ́ igi Ìrókò kọjá.  Bi ó ti dé abẹ́ igi Ìrókò, Ìrókò gbamú, ó bá sọ di ẹyẹ.  Ẹyẹ Olúróhunbí bẹ̀rẹ̀ si kọ orin lóri igi Ìrókò bayi:

 

Oníkálukú jẹ̀jẹ́ Ewúrẹ́, Ewúrẹ́
Ònìkàlùkú jẹjẹ Àgùntàn, Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀
Olúróhunbí jẹ̀jẹ́ ọmọ rẹ̀, ọmọ rẹ̀ a pọ́n bí epo,
Olúróhunbí o, jain jain, Ìrókó jaini (2ce)

Nigbati, ọkọ Olúróhunbí reti iyàwó rẹ titi, ó bá pe ẹbi àti ará lati wa.  Wọn wa Olúróhunbí titi, wọn kò ri, ṣùgbọ́n nigbati ọkọ rẹ̀ kọjá lábẹ́ igi Ìrókò to gbọ́ orin ti ẹyẹ yi kọ, ó mọ̀ pe ìyàwó ohun ló ti di ẹyẹ.

Gẹgẹbi iṣẹ́ rẹ (Gbénàgbénà), ó gbẹ́ èrè bi ọmọ, ó múrá fún, ó gbe lọ si abẹ́ igi Ìrókò.  Òrìṣà inú igi Ìrókò, ri ère ọmọ yi, o gbã, ó sọ Olúróhunbí padà si ènìà.

Ìtàn yi kọ́ wa pé: igbèsè ni ẹ̀jẹ́, ti a bá dá ẹ̀jẹ́, ki á gbìyànjú lati san; ki a má da ẹ̀jẹ́ ti a kò lè san àti ki á jẹ́ ki ọ̀rọ̀ wa jẹ ọ̀rọ̀ wa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-27 09:20:46. Republished by Blog Post Promoter

“A ki i jẹ Igún, a ki i fi Ìyẹ́ Igún rinti: Ẹnu Ayé Lẹbọ” – “It is forbidden to eat the Vulture or use its feather as cotton bud: One should be careful of what others say”

Ohun ti o jẹ èèwọ̀ tàbi òfin ni ilú kan le ma jẹ èèwọ̀/òfin ni ilú miran ṣùgbọ́n bi èniyàn bá dé ilú, ó yẹ ki ó bọ̀wọ̀ fún àṣà àti òfin ilú.  Bi èniyàn bá ṣe nkan èèwọ̀, ó lè ṣé gbé ti kò bá si ẹlẹri lati ṣe àkóbá tàbi ki ó fi ẹnu ṣe àkóbá fún ara rẹ̀.

Ni ilú kan ti a mọ̀ si “Ayégbẹgẹ́”, àwọn àlejò ọkùnrin meji kan wa ti orúkọ wọn njẹ́ – Miòṣé àti Moṣétán.  Ọba ilú Ayégbẹgẹ́ kede pé èèwọ̀ ni lati jẹ ẹiyẹ Igún ni ilú wọn.  Akéde ṣe ikilọ̀ pé ẹni ti ó bá jẹ Igún, ikùn rẹ yio wu titi yio fi kú ni.  Àwọn àlejò meji yi ṣe ìlérí pé kò si nkan ti yio ṣẹlẹ̀ ti àwon bá jẹ Igún, nitori eyi wọn fi ojú di èèwọ̀ ilú Ayégbẹgẹ́.

Igún - Vulture

Igún – Vulture

Miòṣé, lọ si oko, ó pa Igun, ó din láta, ó si jẹ́, ṣùgbọ́n ó pa adiẹ, ó da iyẹ́ adiẹ si ààtàn bi ẹni pé adiẹ ló jẹ.  Ọ̀pọ̀ ará ilú ti wọn mọ̀ pé èèwọ̀ ni lati jẹ Igún paapa, jẹ ninú rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mọ pé Igún ni àwọn jẹ, wọn rò wi pé adiẹ ni.  Miòṣé fi ọ̀rọ̀ àṣiri yi sinú lai si nkan ti ó ṣe gbogbo àwọn ti ó jẹ Igún pẹ̀lú rẹ.

Moṣétán lọ si oko ohun na a pa Igun, ó gbe wá si ilé, ṣùgbọ́n kò jẹ́.  Ó pa adiẹ dipò Igún, o din adiẹ ó jẹ ẹ, ṣùgbọ́n, ó da iyẹ́ Igún si ààtàn bi ẹni pé Igún lohun jẹ.  Ni ọjọ́ keji àwọn ará ilú ri iyẹ́ Igún wọn pariwo pé Moṣétán jẹ èèwọ̀, ó ni bẹni, ohun jẹ Igún.  Ni ọjọ́ kẹta inú Moṣétán bẹ̀rẹ̀ si i wú titi ara fi ni.  Nigbati ìnira pọ̀ fún Moṣétán, ó jẹ́wọ́ wi pé adiẹ lohun jẹ, ṣùgbọ́n wọn ko gba a gbọ pé kò jẹ Igun, titi ti ó fi ṣubú ti ó si kú. Yorùbá ni “Ẹnu Ayé Lẹbo”, Moṣétán fi ẹnu kó bá ara rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pé, àfojúdi kò dára, ó yẹ ki enia pa òfin mọ nitori “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibò miran”.  Ẹni ti kò bá pa òfin mọ, á wọ ijọ̀ngbọ̀n ti ó lè fa ikú tàbi ẹ̀wọ̀n.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-29 23:20:09. Republished by Blog Post Promoter