Category Archives: Yoruba Proverbs

Discussing as many Yoruba proverbs as possible and relating them to day to day life…

Ẹni gbé epo lájà, kò jalè̀ tó ẹni gba a – Olóri Òṣèlú Ilú Ọba, Na Ìka pe Nigeria lo mo Iwà Ibàjẹ́ hù jù ni Àgbáyé: An accomplice is equally guilty – British Prime Minister called Nigeria ‘fantastically corrupt’

David Cameron said Nigeria and Afghanistan were "possibly the two most corrupt countries in the world" as he chatted with the Queen

David Cameron’s ‘corrupt’ countries remarks to Queen branded ‘unfair’ By PRESS ASSOCIATION David Cameron called Nigeria ‘fantastically corrupt’ before the Queen

Ìròyìn ti o jade ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹwa, oṣú karun, ọdún Ẹgbàá-le-mẹ́rìndínlógún, sọ wi pé Olóri Òṣèlú Ilú Ọba, David Cameron pe orilẹ̀ èdè Nigeria ni ilú ti ó hu iwà ibàjẹ́ jù ni àgbáyé.  Kò ṣe àlàyé bi Ì̀jọba ilú rẹ ti ngba owó iwà ibàjẹ́ pamọ́ lati fi tú ilú wọn ṣe.
Ẹni gbé epo lájà, bi kò bá ri ẹni gba a pamọ́, kò ni ya lára lati tún ji omiran.  Bi kò ri ẹni gba a, ó lè jẹ epo na a tàbi ki ẹni tó ni epo ri mú ni wéré.  Gẹgẹ bi òwe Yorùbá ti sọ pé “Ẹni gbé epo lájà, kò jalè̀ tó ẹni gba a”, bi àwọn ti ó n fi ọna èrú àti iwà ibàjẹ́ ja ilú lólè, kò bá ri àwọn Ilú Ọba gba owó iwà ibàjẹ́  lọ́wọ́ wọn, iwá burúkú á din kù.

Ogun ti Ìjọba tuntun ni Nigeria gbé ti iwà ibàjẹ́ lati igbà ti ará ilú ti dibò yan Ìjọba tuntun -Muhammadu  Buhari àti Yẹmi Osinbajo, ni bi ọdún kan sẹhin ni lati jẹ ki àwọn tó hu iwa ibaje jẹ èrè iṣẹ́ ibi, ki wọn si gba owó iwà ibàjẹ́ padà si àpò ilú.  Eyi ti ó ṣe pàtàki jù ni ki Ìjọba Ilú Ọba ṣe àlàyé bi wọn yio ti da àwon owó Nigeria padà ni ipàdé gbi gbógun ti iwa ibaje, ki wọn lè fihan pé àwọn kò fi ọwọ́ si iwà ibàjẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-05-10 23:45:13. Republished by Blog Post Promoter

“Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” – “If one lives long enough, one will consume as much meat as an elephant”

Erin - Elephant

Erin – Elephant

Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni.  Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin.

Isọ̀  Eran – Meat Stall. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni “Bi  a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si “Ajẹ̀fọ́”?  Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé “Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù”. Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe.  Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-12 18:29:05. Republished by Blog Post Promoter

Ọwọ́ Ọmọdé Kòtó Pẹpẹ, Tagbalagba Ò Wọ Kèrègbè: The Child’s Hand Cannot Reach The Shelf, The Adult’s Hand Cannot Enter The Calabash

calabash

Only a child’s hand can reach into this type of calabash. The image is from Wikipedia.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wípé “ọwọ́ ọmọde ko to pẹpẹ, tagbalagba ko wọ̀ kèrègbè”, èyí tí a lè túmọ̀ sí wípé, ọmọdé kò ga to pẹpẹ láti mú nkan tí wọn gbé si orí pẹpẹ, bẹni ọwọ́ àgbàlagbà ti tóbi jù lati wọ inú akèrègbè lati mu nkan, nitorina àgbà̀ lèlo ìrànlọ́wọ́ ọmọdé.

Ní ayé, oníkálukú ló ní ohun tí wọ́n lè ṣe.  Àwọn nkan wa ti àgbàlagbà lè ṣe bẹ̃ni ọpọlọpọ nkan wa ti ọmọdé lè ṣe. Láyé òde òní, ọmọdé le gbójúlé àgbàlagbà, ṣùgbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàlagbà gbójúlé ọmọdé láti kọ́ lílò ẹ̀rọ ayélujára.

Ò̀we yi fi èrè ifọwọsowọpọ laarin ọmọdé àti àgbà han nítorí kò sẹ́ni tí kò wúlò.

ENGLISH TRANSLATION

A Yoruba adage goes that “although the child’s hand cannot reach the shelf, the elder’s hand cannot enter into the calabash”.  Literally translated, while the child or the young one is too short to pick up something placed on a high shelf, the adult’s hand is too big to pass through the neck of a calabash and needs the help of the child.

In life everyone has a role to play.  There are roles that can be handled by the adult and there are many roles that are better handled by younger or less experienced ones.  Nowadays, in as much as the younger ones are dependent on the adult, most adults are dependent on learning effective use of computers and the internet younger ones.

This proverb shows the advantage of cooperation between the young and the old, experienced and inexperienced, as no one is completely useless.

 

Share Button

Originally posted 2013-04-23 19:15:31. Republished by Blog Post Promoter

Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ kò ní jẹ ki a sùn – If you fail to warn your neighbor of danger, his cries at night might prevent you from sleeping

Ó ti lé ni ọgbọ̀n ọdún ti ìyà iná monomono ti ńfi ìyà jẹ ará ilú orílẹ̀ èdè Nigeria.  Nitori dáku-́dájí iná  mọ̀nàmọ́na ti Ìjọba àpapọ̀ pèsè, ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na kékèké ti a lè fi wé kòkòrò búburú gbòde.

Generators

Power generators: ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na. The image is from http://lowhangingfruits.blogspot.com

Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn” bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu.  Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run.  Ai sọ̀rọ̀ ará ìlú lati igbà ti aiṣe dẽde iná ti bẹrẹ lo fa hẹ̀rẹ̀huru ariwo ti ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ-iná kékèké ma ńfà.  Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun.  Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru.

Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona.  A lè fi õrun,  atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona-. Ìlú ti kò ni õrun tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi õrun pèsè iná mona-mona.

Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí.

English translation: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-22 03:51:57. Republished by Blog Post Promoter

Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ òni, America yan Kamala Harris Obinrin àkọ́kọ́ si ipò Igbakeji-Àrẹ – America celebrates the election of first Female Vice-President

Ọjọ́ keje, oṣù kọkanla ọdún Ẹgbàá, ìròyìn kàn pé Joe Biden àti Igbakeji rẹ Kamala Harris ni wọ́n yàn si ipò Àrẹ kẹrindinlaadọta ti yio gun ori oyè lati Ogún ọjọ́, oṣù kini ọdún Ẹgbàálékan.

Obinrin àkọ́kọ́ Igbakeji Àrẹ Kamala Harris di ẹni ìtàn – 1st American Female Vice President Kamala Harris

Obinrin àkọ́kọ́ Igbakeji Àrẹ Kamala Harris di ẹni ìtàn –  inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilú dún lati gbọ́ iroyin ayọ̀ yi.  Èrò tu jade lati yọ̀. 

Obinrin ti jẹ Àrẹ ni àwọn orilẹ̀-èdè míràn tàbi jẹ ọba ni ilú Òyinbó ṣùgbọ́n àkọ́kọ́ rè é ni orilẹ̀-èdè America ti obinrin di Igbakeji Àrẹ pàtàki ti ó tún jẹ aláwọ̀dúdú.  Ni orile-ede Nigeria, ọkùnrin ló pọ̀ ni ipò Òṣèlú, kò ti si obinrin ti o di Gómìnà ki a má ti sọ ipò Àrẹ.

Yorùbá ni “Gbogbo lọ ọmọ”, èyi fihàn pé Yorùbá ka obinrin àti ọkùnrin si ọmọ, ṣùgbọ́n bi ìyàwó bá wà ti kò bi ọkùnrin, inú wọn ki i dùn pàtàki àwọn ti kò kàwé.   Èyi yẹ kó kọ́ àwọn obinrin ti ó ḿbímọ rẹpẹtẹ nitori wọn fẹ́ bi ọkùnrin pé “Gbogbo lọ ọmọ”, èyi ti ó ṣe pàtàki ni ki Ọlọrun fún ni lọ́mọ rere.

ENGLISH LANGUAGE

The news of election of Joe Biden and Kamala Harris as the 46th President/Vice President of America broke out on November Seven (07), 2020 and would be sworn in on January 20, 2021.

Continue reading
Share Button

Originally posted 2020-11-08 04:19:48. Republished by Blog Post Promoter

“A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” – Ìdàpọ̀ Àríwá àti Gũsu Nigeria: – 1914 Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria

Ó pé ọgọrun ọdún ni ọjọ́ kini, oṣù kini ọdún Ẹgba-̃le-mẹrinla ti Ìjọba Ìlú-Ọba ti fi aṣẹ̀ da Àríwá àti Gũsu orílẹ̀ èdè ti a mọ̀ si Nigeria pọ.  Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni.

Yorùbá ni “À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri”.  Ni tõtọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nigeria ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán.  Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nigbati wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe: “ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú.  A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan.

Yorùbá ni “A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàki, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ.

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé”.  Bi ọkọ àti iyàwó bá wà lai bára sọ̀rọ̀, igbéyàwó á túká, nitori eyi, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ara ilú Nigeria lápapọ̀ ṣe àpérò bi wọn ti lè bára gbé ki ilú má bã túká.

ENGLISH TRANSLATION

“One does not qualify to live with a person without also qualifying to talk to the person” – Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-07 23:11:15. Republished by Blog Post Promoter

“A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù”: Ìmọ̀ràn fún Òṣèlú tuntun àti àwọn ará ilú Nigeria – It takes more than One Day to Nourish a Malnourished child”: Advice for the Newly Elected Politicians and the Nigerian People

Ọmọ ki dédé rù lai ni idi.  Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni: àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ.

Orilẹ̀ èdè Nigeria ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún.  Nigbati àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàki ọmọ Yorùbá.  Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ipinlẹ̀, pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin.  Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.

Ilú bẹ̀rẹ̀ si rù lati igbà ti Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ti fi ipá kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ni  ọdún mọ́kàndinlãdọta sẹhin .  Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ipinlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni “Òbí” ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni “Ọmọ” ti rù.  Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú.

Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun.  Nigbati wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ìbàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù.  Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si.  Nigbati Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nitori àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó.  Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni.  Àyè àti ni owó ojiji nipa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàki ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ.

A lè lo òwe “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù” ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nitori eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀.  Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé “Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́”, nitori eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-01-12 10:09:45. Republished by Blog Post Promoter

Ìkà ò jẹ́ ṣe ọmọ ẹ bẹ́ẹ̀ – Gbi gba wèrè mọ ẹ̀sìn Aláwọ̀-dúdú: The wicked always protect their own – Religious madness in Africa

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Libya migrants: Muslim refugees arrested in Italy for throwing Christians into sea after fight

Ni ọjọ́ kẹrin-din-lógún, oṣ̀u kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún, ọwọ́ Ọlọpa Italy tẹ ọkunrin mẹ̃dogun ti ó ju àwọn Ìgbàgbọ́ mejila si odò nitori ẹ̀sìn lati inú ọkọ̀ ojú agbami ti o nko Aláwọ̀-dúdú ti ó nsa fún ogun àti iṣẹ lo si Òkè-òkun/Ilú-Òyinbò.

Ni gbogbo ọ̀nà ni Aláwọ̀-dúdú fi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Lára gbi gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn ni Àlùfã fi ni ki àwọn ọmọ ijọ bẹ̀rẹ̀ si jẹ koríko ti ọmọ rẹ kò lè jẹ, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ijọ ti ó jẹ koríko ló gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọmọ ijọ ti kò le bọ ara rẹ tàbi bọ ọmọ, ti ó nda ida-mẹwa nigbati Olóri Ijọ nfi owó yi gun ọkọ̀ òfúrufú fi han pé ọ̀pọ̀ ti gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Aládurà ti ó nri iran ti kò ri tara rẹ gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.

A screen capture from a Boko Haram video purporting to show the kidnapped girls

‘The Chibok girls are never being freed,’ says Boko Haram leader

Ẹlẹ́sin Mùsùlùmi ti ó npa ẹlòmíràn ni orúkọ ẹ̀sìn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Eyi ti ó ni èèwọ̀ ni iwé kika fún ẹ̀sìn ohun “Boko Haram” ti wọn fi nba ilé iwé jẹ, ji àwọn obinrin kò kúrò ni ilé iwé, fihàn pé wọn gba wèrè mọ́ ẹ̀sìn.  Ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdógún ló pé ọdún kan ti ẹgbẹ́ burúkú “Boko Haram” ti ko igba-le-mọkandinlógún obinrin kúrò ni ilé-iwè ni Chibok.  Lèmọ́mù rán ọmọ tirẹ̀ lọ si ilé-iwé, irú àwọn ọmọ Lèmọ́mù ti ó ka iwé ni ó nṣe Òṣèlú tàbi jẹ ọ̀gá ni iṣẹ́ Ìjọba.

Kò si Òṣèlú Aláwọ̀-dúdú ti kò sọ pé ohun jẹ Onígbàgbọ́ tàbi Mùsùlùmi ṣùgbọ́n eyi kò ni ki wọn ma ja ilú ni olè.  Ìfẹ́ agbára ki jẹ ki wọn fẹ gbe ipò silẹ̀ nitori eyi wọn á fi ẹ̀sìn da ilú rú.  Eleyi ló fa ogun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-18 00:30:26. Republished by Blog Post Promoter

“A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀: Ìkìlọ̀ fún àwọn tó fẹ́ lọ Ò̀kè-òkun tipátipá” – “Struggling to save the chicks from untimely death and its complaining of being prevented from foraging at the dump – Caution against desperate illegal Oversea migration”

A lè lo òwe yi lati ṣe ikilọ̀ fún ẹni tó fẹ́ lọ si Òkè-òkun (Ìlu Òyìnbó) lọ́nà kọ́nà lai ni àṣẹ tàbi iwé ìrìnà.  Bi ẹbi, ọ̀rẹ́ tàbi ojúlùmọ̀ tó mọ ewu tó wà ninú igbésẹ̀ bẹ ẹ bá ngba irú ẹni bẹ niyànjú, a ma binú pé wọn kò fẹ́ ki ohun ṣoriire.

Watch this video

More than 3,000 migrants died this year trying to cross by boat into Europe

An Italian navy motorboat approaches a boat of migrants in the Mediterranean Sea

Thirty dead bodies found on migrant boat bound for Italy

Bi oúnjẹ ti pọ̀ tó ni ààtàn fún òròmọ adìẹ bẹni ewu pọ̀ tó, nitori ààtàn ni Àṣá ti ó fẹ́ gbé adìẹ pọ si.  Bi ọ̀nà àti ṣoriire ti pọ̀ tó ni Òkè-òkun bẹni ewu àti ìbànújẹ́ pọ̀ tó fún ẹni ti kò ni àṣẹ/iwé ìrìnà.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkú sọ́nà, ọ̀pọ̀ ndé ọhun lai ri iṣẹ́, lai ri ibi gbé tàbi lai ribi pamọ́ si fún Òfin nitori eyi, ọ̀pọ̀ wa ni ẹwọn. Lati padà si ilé á di ìṣòro, iwájú kò ni ṣe é lọ, ẹhin kò ni ṣe padà si, nitori ọ̀pọ̀ ninú wọn ti ju iṣẹ́ gidi silẹ̀, òmiràn ti ta ilé àti gbogbo ohun ìní lati lọ Òkè-òkun. Bi irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ṣe npẹ si ni Òkè-òkun bẹni ìtìjú àti padà sílé ṣe npọ̀ si.

Òwe Yorùbá ti ó sọ pé “A ngba òròmọ adìẹ lọ́wọ́ ikú, ó ni wọn ò jẹ́ ki ohun lọ ààtàn lọ jẹ̀ yi kọ́wa pé ká má kọ etí ikún si ikilọ̀, ká gbé ọ̀rọ̀ iyànjú yẹ̀wò, ki á bà le ṣe nkan lọ́nà tótọ́.

ENGLISH TRANSLATION

This proverb can be applied to someone struggling at all cost to migrate Abroad/Oversea without a Visa or proper documentation.   Even when family, friend or colleague that knows the danger in illegal migration, tries to warn such person of the danger, he/she will be angry of being prevented from prosperity. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-19 09:10:15. Republished by Blog Post Promoter

“Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro” – “Empty barrel makes most noise”

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún ohun ti ó wúlò bi epo-rọ̀bì, epo-pupa, epo-òróró, epo-oyinbo, ọ̀dà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ki pariwo.  Àgbá òfìfo, kò ni nkan ninú tàbi o ni nkan díẹ̀, irú àgbá yi bi o ti wù ki ó lẹ́wà tó, ni ariwo rẹ máa ńpọ̀ ti wọn ba yi lóri afárá tàbi ori titi ọlọ́dà.

Oil-Barrels-2619620

Àgbá òfìfo ti ó lẹ́wà – Colourful empty barrels

Àgbá òfìfo ni àwọn ti ó wà ni òkè-òkun/ilú òyìnbó ti ó jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati wá ṣe àṣehàn ti wọn bá ti àjò bọ, ohun ti wọn kò tó wọn a pariwo pé àwọn jù bẹ́ẹ̀ lọ.  Ni tòótọ́, ìyàtọ̀ òkè-òkun/ilú-òyìnbó si ilẹ̀ Yorùbá ni pé, àti ọlọ́rọ̀ àti aláìní ló ni ohun amáyé-dẹrùn bi omi, iná mọ̀nà-mọ́ná, titi ọlọ́dà, ilé-iwé gidi, igboro ti ó mọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Àwọn Òṣèlú kò kọjá òfin, bẹni irònú wọn ki ṣe ki á di Òṣèlú lati kó owó ilú jẹ.

Ni ayé àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, owó kọ́ ni wọn fi ńmọ ẹni gidi, àpọ́nlé/ọ̀wọ̀ wà fún àgbà, ẹni ti ó bá kàwé, olootọ enia, ẹni tó tẹpá mọ́ṣẹ́,  akin-kanjú àti ẹni ti ó ni òye.  Ni ayé òde òni, àgbá òfìfo ti pọ ninú ará ilú, àwọn Òṣèlú àti àwọn òṣiṣẹ́ ijọba.  Bi wọn bá ti ri owó ni ọ̀nà èrú, wọn a lọ si òkè-òkun/ilú-òyìnbó lati ṣe àṣehàn si àwọn ti wọn bá lọhun lati yangàn pẹ̀lú ogún ilé ti wọn kọ́ lai yáwó, ọkọ̀ mẹwa ti wọn ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ti wọn ni àti ayé ijẹkújẹ ti wọn ńjẹ ni ilé.  Wọn á ni àwọn kò lè gbé òkè-òkun/ilú-òyìnbó, ṣùgbọ́n bi àisàn bá dé, wọn á mọ ọ̀nà òkè-òkun/ilú-òyìnbó fún iwòsàn àti lati jẹ ìgbádùn ohun amáyé-derùn miran ti wọn ti fi èrú bàjẹ́ ni ilú tiwọn.

Bi àgbá ti ó ni ohun ti ó wúlò ninú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni gidi tó ṣe àṣe yọri ki pariwo. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro”, bá ẹni-kẹ́ni ti ó bá ńṣe àṣehàn tàbi gbéraga wi pé ki wọn yé pariwo ẹnu.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-08-08 18:20:28. Republished by Blog Post Promoter