Category Archives: Yoruba Proverbs

Discussing as many Yoruba proverbs as possible and relating them to day to day life…

IMULO ÒWE YORUBA: APPLYING YORUBA PROVERBS

“A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ” 

A le lo òwe yi lati kilọ fun ẹni to fẹ lọ si Òkèokun (Ìlu Òyìnbó)  lọna kọna lai ni ase tabi iwe ìrìnà.  Bi ẹbi, ọrẹ tabi ojulumọ to mọ ewu to wa ninu igbesẹ bẹ ba ngba irú ẹni bẹ niyanju, a ma binu wipe wọn o fẹ ki ohun ṣoriire.   Bi ounjẹ ti pọ to l’atan fun oromọdiyẹ bẹni ewu pọ to.  Bi ọna ati ṣoriire ti pọ to ni Òkèokun bẹni ewu ati ibanujẹ pọ to fun ẹniti koni aṣẹ/iwe ìrìnà.  Ọpọlọpọ nku sọna, ọpọ si nde ọhun lai ri iṣẹ, lai ri ibi gbe tabi lai ribi pamọ si fun Òfin. Lati pada si ile a di isoro nitori ọpọ ninu wọn ti ta ile ati gbogbo ohun ìní lati lọ oke okun. Bi iru ẹni bẹ ṣe npe si l’Òkèokun bẹni ìtìjú ati pada sile se npọ si.

Òwe yi kọwa wipe ka ma kọ eti ikun si ikilọ, ka gbe ọrọ iyanju yẹwo ki a ba le se nkan lọna totọ.

ENGLISH TRANSLATION

“WE ARE TRYING TO SAVE THE CHICK FROM DEATH, ITS COMPLAINING OF NOT BEING ALLOWED TO GO TO THE DUMPSITE” — “A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ”

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 22:08:02. Republished by Blog Post Promoter

“Bi ikú ilé ò pani, tòde ò lè pani” – “If the death at home does not kill, the death outside will not”

“Bi ikú ilé ò pani, tòde ò lè pani” – “If the death at home does not kill, the death outside will not”

Òwe Yorùbá ti o ni “Bi ikú ilé ò pani, tòde ò lè pani” bá ọ̀pọ̀ iṣẹ̀lẹ̀ ti o ńṣẹlẹ̀ nitori ìfẹ́ owó ti ó gbòde láyé òde òní mu.

http://www.naijahomenewz.com/2012/05/senior-manager-at-gtbank-arrested-for.html

Senior Manager At GTBank Arrested For Armed Robbery: Wọn mú òṣiṣẹ́ ilé-owó (GTBank) fún iṣẹ́ Adigun-jalè

Ọmọ, ẹbi tabi alábagbe ńdarapọ̀ mọ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, oníjìbìtì lati fi ipá gba owó lọ́wọ́ ẹbi ti wọn bá mọ̀ tabi rò pé ó ni owó púpọ̀.  Fún àpẹrẹ, ẹni ti o mba enia gbé ló mọ ohun ti enia ni.  Bi  ọmọ, ẹbi tabi alábagbe wọnyi bá ni ojúkòkòrò wọn á darapọ̀ mọ olè lati gbé ẹrù tàbi owó pẹ̀lú ipá.  Ọpọlọpọ obinrin ti o ni ohun ẹ̀ṣọ́ bi wúrà àti fàdákà ni alábagbe ma ńdarapọ mọ olè lati wá gbé ohun ẹṣọ yi fún tita lati di olówó ojiji.  Àpẹrẹ pataki miran ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé-owó, ilé iṣẹ́ Ijọba àti bẹ̃bẹ lọ ti wọn darapọ̀ lati ja ilé iṣẹ́ wọn

Ọ̀pọ̀ igbà ni àṣiri ọmọ, ẹbi tàbi alábagbe tó darapọ̀ mọ́ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, òṣìṣẹ́ àti awọn oni iṣẹ́ ibi tókù ma ńtú, ninu ìjẹ́wọ́ awọn oníṣẹ́ ibi wọnyi nigbati ọwọ́ Ọlọpa bá tẹ̀ wọ́n.  Nitori eyi, ó yẹ ki a ma ṣọ́ra. 

ENGLISH TRANSLATION

The Yoruba proverb that said, “If the death at home does not kill, the death outside will not” can be applied to the love of money common nowadays.

Children, family members and roommates often connive with thieves/robbers, kidnappers, fraudsters against a rich or a perceived rich family member to defraud or steal from such person.  For example, most often it is those that are close enough that knows ones worth.  If such children, family and neighbours/roommates are greedy they would end conniving with the intention of defrauding or steal.  It is usually those that are close to most of the women who store gold and silver at home, that connive with robbers to steal such precious metals for quick money. Another important example are employees such as Bankers, Government workers etc stealing conspiring with armed men to steal from their employers.

On many occasions when the thieves, kidnappers and other fraudulent people are caught, they often exposed such family members or neighbours/roommates, employees and other evil doers.  As a result, one should take extra care.

Share Button

Originally posted 2014-02-08 00:53:26. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi: ìyànjú fún àwọn omidan” – “There are two hundred and one suitors to a spinster, only one would make a good husband: Caution for ladies”

Ni ayé àtijọ́, òbi si òbi àti ẹbi si ẹbi ló nṣe ètò iyàwó fi fẹ́ fún ọmọ ọkùnrin ti ó bá ti bàláágà, ti wọn rò pé ó lè tọ́jú iyàwó.  Obinrin ki tètè bàláágà, nitori ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ṣe nkan oṣù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin ma ndàgbà tó bi ọdún mẹrin-din-lógún tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ.  Gẹgẹ bi wọn ti ma nsọ ni igbà igbéyàwó ibilẹ “òdòdó kán wà lágbàlá ti a fẹ́ já”, bi òbi tàbi ẹbi bá ṣe akiyesi ọmọ obinrin ti ó wù wọn lati fẹ́ fún ọmọ ọkunrin wọn, yálà idilé si idilé tàbi ni agbègbè ni ibi “ọdún omidan”, wọn yio lọ bá òbi/ẹbi obinrin na a lati bẹ̀rẹ̀ ètò bi wọn yio ti fẹ fún ọmọ wọn. Ni ayé igbàlódé, obinrin yára lati bàláágà, nitori omiran a bẹ̀rẹ̀ nkan oṣú ni bi ọmọ ọdún mọ́kànlá.  Obinrin ki yára fẹ́ ọkọ mọ nitori ilé-iwé àti pé ki ṣe òbi àti ẹbi ló nfẹ́ obinrin fún ọmọ ọkùnrin mọ.

Yorùbá ma nlò ọ̀rọ̀ ti ó sọ pé “Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi” lati la obinrin lóye pé ki ṣe gbogbo ọkunrin ti ó bá wá bá obinrin lati sọ̀rọ̀ ifẹ́ ló ṣe tán lati fẹ́ iyàwó, gbogbo wọn kọ́ si ni “ọkọ gidi”.  Kò yẹ ki obinrin kanra tàbi lé ọkùnrin ti ó bá kọ ẹnu ifẹ́ si wọn pẹ̀lú èébú, nitori Yorùbá sọ wipé, “A kì í kí aya-ọba kó di oyún” ṣùgbọ́n ki wọn farabalẹ̀ lati mọ irú ẹni ti ọkùnrin na a jẹ.  Li lé ọkùnrin nigbati ọ̀pọ̀ ọkùnrin bá fẹ́ yan obinrin lọrẹ, pàtàki ni igba ti obinrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bàláágà, lè fa ki obinrin ṣe àṣimú ni igba ti wọn bá ṣe tán lati fẹ́ ọkọ, nitori ó ti lè bọ́ si àsikò ikánjú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-03 21:50:24. Republished by Blog Post Promoter

“Ni ilú Afọ́jú, Olójú kan Lọba”: Ìjọba Òṣèlú tuntun gba Ìjọba ni Orilẹ̀-èdè Nigeria – “In the Country of the Blind, One-eyed person is the King”: Transfer of Democratic Power from the incumbent to the Elected in Nigeria

Ọjọ́ itàn ni ọjọ́ kọkàndinlógún, oṣù karun, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún jẹ fun orilẹ̀ èdè Nigeria àti gbogbo ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.  Kò wọ́pọ̀ ki Ìjọba Ológun tàbi Ẹgbẹ́ Òṣèlú gbà lati gbé Ìjọba silẹ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú  nitori eyi àwọn Olóri Òṣèlú lati orilẹ̀ èdè bi mẹrinléladọta pé jọ si Abuja, olú-ilú Nigeria lati ṣe ẹlẹri gbi gbé Ìjọba lati ọ̀dọ̀ Olóri kan si ekeji.

Goodluck Ebele Jonathan gbé Ìjọba fún  Muhammadu Buhari - Handing over

Goodluck Ebele Jonathan gbé Ìjọba fún Muhammadu Buhari – Handing over

Yorùbá sọ wi pé “Melo la ó kà leyin Adépèlé”, a ó ṣe àyẹ̀wò di ẹ̀ ninú àpẹrẹ àwọn Olóri Òṣèlú Aláwọ̀dúdú tó jẹ Oyè “Akintọ́lá ta kú”: Ọ̀gágun Olóògbé Muammar Gaddafi ti Libya ṣe titi wọn fi pa si ori oyè lẹhin ọdún méjilélogóji; Hosni Mubarak ti Egypt wà lóri oyè titi ará ilú fi le kúrò lẹhin ọgbọ̀n ọdún; ará ilú gbiyànjú ṣùgbọ́n wọn ó ri Bàbá Robert Mugabe (arúgbó ọdún mọ́kànlélãdọrun) ti Zimbabwe lé kúrò lati ọ̀rùndinlógóji ọdún; Paul Biya ti Cameroon ti ṣe Olóri Òṣèlú lati ogóji ọdún; Omar al-Bashir ti Sudan ti wà lóri oyè fún ọdún méjilélógún.  Àwọn ọ̀dọ́ ti a lérò wi pé yio tun yi iwà padà kò yàtọ̀ bi wọn bá ti dé ipò.  Pierre Nkurunziza ti Burundi gbà ki àwọn ará ilú kú, ju ki ó ma gbe àpóti ibò ni igbà kẹta lẹhin ọdún mẹwa;  Joseph Kabila – Olóri Òṣèlú Congo lati ọdún mẹrinla; Olóri Òṣèlú Togo Faure Gnassingbé ti wà lóri oyè fún ọdún mẹwa lehin iku Bàbá rẹ, kò dẹ̀ fẹ́ kúrò àti ọ̀pọ̀ tó ti kú si ori oyè.

Yorùbá sọ wi pé “Ni ilú Afọ́jú, Olójú kan Lọba”, ọ̀rọ̀ yi gbà ọpẹ́ fún orilẹ̀-èdè Nigeria, nitori Olóri Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan, gbà lati gbé Ìjọba fún Olóri Ogun Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ́ míràn lai si ìjà.  Irú eyi ṣọ̀wọ́n, pàtàki ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.  Ẹgbẹ́ Òṣèlú Alágboòrùn ti ṣe Ìjọba fún ọdún mẹ́rindinlógún ki ilú tó fi ibò gbé wọn kúrò ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olóri àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ọdún mẹ́rindinlógún kéré.   Ká ni Olóri Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan bá kọ̀ lati ki ẹni ti ilú yàn Olóri-ogun Muhammadu Buhari ku ori ire ni idije idibo, ijà ki ba ti bẹ́.  Eleyi fi hàn pé Ọlọrun ni ifẹ Nigeria, ó ku ka ni ìfẹ́ ara. A lérò wi pé àwọn Olóri àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú yoku yio fi eyi kọ́gbọ́n

A ki Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan ti ó gbé Ìjọba fún Olóri-ogun Muhammadu Buhari ti ilú fi ibò yàn, àwọn ọmọ Nigeria ti ó dibò fún àyipadà àti gbogbo ọmọ Nigeria ni ilé lóko kú ori ire ọjọ́ pàtàki yi ni itàn orilẹ̀ èdè Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-29 15:28:02. Republished by Blog Post Promoter

“Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” – “Poverty is lonesome while success has many siblings”

Ni ayé igbà kan, bi èniyàn bá jẹ́ alágbára, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, ti ó si tún ni iwà ọmọlúwàbí, iyi wà fun bi kò ti ẹ ni owó, ju olówó rẹpẹtẹ ti kò si ẹni ti ó mọ idi owó rẹ ni áwùjọ tàbi ti kò hùwà ọmọlúwàbí.  Ni ayé òde òni, ọ̀wọ̀ wà fún olówó lai mọ idi ọrọ̀, eyi ló njẹ ki irú àwọn bẹ́ ẹ̀ dé ipò Òsèlú, Olóri Ìjọ tàbi gba oyè ti kò tọ́ si wọn.

Ìbẹ̀rù òṣì lè jẹ́ ki èniyàn tẹpá-mọ́ṣẹ́, bẹ ló tún lè jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fi ipá wá owó.  Ìfẹ́ owó tó gba òde kan láyé òde òni njẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ jalè tàbi wá ipò agbára ti ó lè mú ki wọn ni owó ni ọ̀nà ti kò tọ́.  Òṣèlú ki fẹ́ gbé ipò silẹ̀ nitori ìbẹ̀rù pé bi agbára bá ti bọ́, ìṣẹ́ dé.  Àpẹrẹ tani mọ̀ ẹ́ ri pọ̀ lára àwọn Òsèlú ti agbára bọ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba ti ipò rẹ bọ́, Olóri Ìjọ ti ó kó ọrọ̀ jọ ni orúkọ Ọlọrun ló nri idá mẹwa gbà ju Olóri Ìjọ ti kò ni owó.

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” fi hàn pé owó dára lati ni, ṣùgbọ́n kò dára lati fi ipá wá ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.  Kò yẹ ki èniyàn fi ojú pa ẹni ti kò ni rẹ́ tàbi sá fún ẹbi ti kò ni, nitori igbà layé, igb̀a kan nlọ, igbà kan mbọ̀, ẹni ti ó ni owó loni lè di òtòṣì ni ọ̀la, ẹni ti kò ni loni lè ni a ni ṣẹ́ kù bi ó di ọ̀la.  Nitori eyi, iwà ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ki i ṣe owó tàbi ipò.

ENGLISH TRANSLATION

In time past, if a person is strong, hard working with good moral character, such person is honoured even though he/she may not be rich rather than a very rich person whose source of Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-19 15:23:07. Republished by Blog Post Promoter

“Igbà kan nlọ, igbà kan nbọ̀, igbà kan kò dúró titi” – “Time passes by and does not wait forever”

Oriṣi mẹta ni Yorùbá ka igbà ẹ̀dá si.  Gẹ́gẹ́ bi àgbà ninú Olórin ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú Olóyè Ebenezer Obey (Fabiyi) ti kọ́ pé “Igbà mẹta ni igbà ẹ̀dá láyé, igbà òwúrọ̀, igbà ọ̀sán, igbà alẹ́, ki alẹ́ san wá ju òwúrọ̀ lọ”.  Igbà meji ló wà fún ojú ọjọ́ – igbà òjò àti ẹ̀rùn.

https://youtu.be/f4rTDpDvHgE?t=11

Òjò ti fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ kúrò ni ilẹ̀ ni oṣù kẹsan ọdún nitori àsikò ìkórè sún mọ́lé lẹhin òjò.  Gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Igba …” ó yẹ ki enia kọ lati lo àsikò dáradára, nitori igbà kò dúró de ẹni kan.  Kò yẹ ki enia fi àkókò ṣòfò, nitori ẹni kò gbin nkan, kò ni ẹ̀tọ́ àti kórè ni igbà ikórè.  Ọ̀rọ̀ yi ṣe rán ẹni ti ó bá nfi àárọ̀ ṣeré leti pé bi igbà bá ti lọ, kò ṣe rà padà.

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-01 20:07:32. Republished by Blog Post Promoter

Ọdún Ẹgbã-lemẹ̃dogun wọlé, ọdún á yabo o – Year 2015 is here, may the year be peaceful

Ọdún tuntun Ẹgbã-lemẹ̃dogun wọlé dé.  Ilú Èkó fi tijó tayọ̀ gba ọdún tuntun wọlé, gbogbo àgbáyé naa fi tijó tayọ̀ gba ọdún wọlé.  A gbàdúrà pé ki ọdún yi tura fún gbogbo wa o (Àṣẹ).Governor Babatunde Fashola of Lagos State, members of the state executive council and the sponsors of the Lagos Countdown 2014 at the Lagos Countdown Festival of Light held on Monday at the Bar Beach, Lagos.

ENGLISH TRANSLATION

The New Year 2015 is here with us.  Lagos ushered in the New Year with dancing and joy, as the rest of the world received the New Year.  We pray that the New Year will be peaceful for all (Amen).

Share Button

Originally posted 2015-01-03 00:16:00. Republished by Blog Post Promoter

Bί a bá ránni ni iṣẹ ẹrú: One sent on a slavish errand (on man’s inhumanity to man)


The Mido Macia Story courtesy of NEWSY reporting from multiple sources and giving a broader view


Yorὺbá nί “Bί a bá ránni nί iṣẹ ẹrú, a fi tọmọ jẹ”.  Ọlọpa tί o yẹ ki o dãbo bo ará àti ẹrú nί ìlú, nhuwa ìkà sί àwọn tί o yẹ ki wọn ṣọ.  Ọlọpa South Africa so ọdọmọkunrin ọmọ ọdún mẹta dinlọgbọn – Mido Gracia, mọ ọk`ọ ọlọpa, wọ larin ìgboro, lu, lẹhin gbogbo eleyi, ju si àtìm`ọle tίtί o fi kú.  Ọlọpa wọnyi hὺ ìwà ìkà yί nίgbangba lai bìkίtà pe aye ti lujára. Eleyi fi “Ìwà ìkà ọmọ enia sί ọmọ enia han”.   Ọlọpa South Africa ṣi àṣẹ ti wọn nί lὸ, wọn rán wọn niṣe ẹrú, wọn o fi tọmọ jẹ.  Sὺnre o Mido Macia.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba proverb says that, “One sent on a slavish errand, should deliver the message with the discretion of an heir”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-02 00:25:30. Republished by Blog Post Promoter

“Ohun ti ó ntán lọdún eégún” – Kérésìmesì ọdún Ẹgbã-lé-mẹ́rìnlà ti lọ̀ – “Masquerade Festival sure has an end” – Christmas 2014 has gone

Christmas Gifts

Bàbá-Kérésì – Father Christmas

Ìwà alajẹtan ti bori iránti ohun ti Kérésìmesì wà fún.  Ọ̀pọ̀ kò ti ẹ̀ ránti pé iránti ọjọ́ ibi Jesu ni Ìjọba ṣe fún ará ilú ni ọjọ́ ìsimi ni ọjọ́ karun-din-lọgbọn oṣù kejila ni ọdọ-ọdún.  Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni Òkè-Òkun ti ẹ rò pé “Bàbá-Kérésì dára ju Jesu” nitori Bàbá-Kérésì fún àwọn ni ẹ̀bùn ṣùgbọ́n ó kù si ọwọ́ òbi àti àwọn  Onigbàgbọ́ lati tẹra mọ́ àlàyé ohun ti ọdún Kérésìmesì wà fún.

Kò yẹ ki Kérésìmesì sún èniyàn si igbèsè tàbi fa irònú.  Àwọn ti ó wà ni Òkè-Òkun, ìwà-alẹjẹtan ti sún ọ̀pọ̀ si igbèsè, tàbi irònú nitori wọn kò ni owó lati ra ẹ̀bùn àti ohun tuntun ti wọn polówó tantan lóri ẹrọ-isọ̀rọ̀ igbàlódé bi ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán, ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ori ayélujára.

Òwe Yorùbá ni “Ohun ti ó ntán lọdún eégún”, eyi túmọ̀ si pé, “Ohun ti ó ni ibẹ̀rẹ̀, ni òpin”.  Kérésìmesì ọdún yi ti wá, ó ti lọ, fún àwọn ti ó jẹ igbèsè nitori ọdún, ó ku igbèsè lati san wọ ọdún tuntun.  Ni àsikò ìpalẹ̀mọ́ ọdún tuntun yi, ó yẹ ki èniyàn ṣe ipinu lati ṣe bi o ti mọ.

Ọdún tuntun á bá wa láyọ̀ o.

ENGLISH TRANSLATION

Consumerism has nearly overtaken the purpose of Christmas.  Most people no longer remember that the annual public holiday for every twenty-fifth of December is dedicated to the Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-26 16:44:40. Republished by Blog Post Promoter

Àjùmòbí kò kan tãnu… Same parentage does not compel compassion…

Ajumomobi o ko ti anu

Same parentage does not compel compassion.

Òwe Yorùbá ní “Àjùmòbí kò kan tãnu, ẹni Olúwa  bá rán síni ló nṣeni lõre”.  Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l’Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé.

Yorùbá ní “Òṣìṣẹ́ wa lõrun, abáni náwó wà níbòji”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí wọnyi, ma mba ẹni tí o nṣiṣẹ ka owó lai rò wípé ẹni tí ó nṣiṣẹ yi, nlãgun lati rí owó.  Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l’Ókè-Òkun/Ìlú-Òyìnbó nṣe nínú òtútù.  Fún àpẹrẹ: níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ̃bẹ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l’Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn.

Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba.  Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí.  Ẹbí tóní owó tàbí gbé Òkè-òkun lè fi ojú ãnu ṣe ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ki ṣe iṣẹ́ ẹni bẹ̃ lati gbé ẹrù ẹlẹ́rù.   Ẹjẹ́ ká rántí òwe yi wípé “Àjùmọ̀bí kò kan tãnu, ẹni Olúwa bá rán síni ló nṣeni lõre”, nítorí aladugbo, àjòjì, ọ̀rẹ́, àti bẹ̃bẹ lọ, lè ṣeni lãnu bí Olúwa bá rán wọn.

ENGLISH TRANSLATION

A Yoruba saying goes that “same parentage does not compel compassion, only those sent by God show compassion”.  This proverb can be used to advice those dependent on family member.  Many dependents think it is a right for rich or family members living abroad to carry their responsibilities. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-18 18:00:26. Republished by Blog Post Promoter