Category Archives: Yoruba Proverbs

Discussing as many Yoruba proverbs as possible and relating them to day to day life…

ÌHÀ TI AWỌN ÒBÍ NI ILẸ̀ KAARỌ OOJIRE KỌ SI ÈDÈ YORÙBÁ: THE ATTITUDE OF PARENTS IN YORUBA LAND TOWARDS YORUBA LANGUAGE

A sọ wipe ọmọ kò gbọ́ èdè, tani kó kọ̃? Àwa òbí nii ṣe púpọ ni bi àwọn ọmọ wa ṣe mú èdè
abi-nibi wọn. Àwa òbí lati yi ìhà ti a kọ si èdè Yorùbá padá, ti a kò bá fẹ́ ki o pòórá.
Òwe Yorùbá kan tilẹ sọ wípé, “Onígbá Io npe igbá rẹ ni pankara, ti a fi nbaa fi kolẹ’.
Gẹ́gẹ́ bi òbí, ohun ti a bá fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa lati ìgbà èwe ni wọn yio gbọ́njú mọ,
ti wọn yio si dìmú.

Ṣugbọn kini a nfi lélẹ̀? ‘Ẹ̀kọ́ Àjòjì’! Eyi yi ni Èdè Gẹẹsi. Àwa òbí papa, ti a rò
pé a ti lajú ju pé kaa mã fi èdè abínibí wa maa ba àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nílé lọ. Àti kàwé, a si
ti bọ́ si ipele tó ga ju èyi ti a bi wa si lọ, nitori na, èdè wa di ohun ìtìjú àti àbùkù, ti kò yẹ
ipò ti a wà.

Ẹ jẹ́ ki a kọ́ ọgbọ́n lára àwọn Ìgbò, Hausa, Oyinbo, China àti India,ki a si fi won ṣe àwòkọ́ṣe. Kò si ibi ti àwọn wọnyi wà, yálà nílé tabi lóko, èdè wọn, ni wọn maa ba awọn ọmọ sọ. Àwọn Oyinbo gbé èdè wọn ni arugẹ, ni ó mú ki idaji gbogbo enia ni àgbáyé ki ó maa lo èdè wọn. Àwọn ará ìlú China, ẹ̀wẹ̀, kò fi èdè wọn ṣeré rárá, tó bẹ̃ ti odindi ìlú America,  àti àwọn kan ni ilẹ̀ adúláwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ awọn ọmọ ilé-ìwé wọn  ni Mandarin, ẹ̀yà èdè China. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-08 18:36:55. Republished by Blog Post Promoter

“Obinrin ti kò ni orogún, kò ti mọ àrùn ara rẹ̀”: A woman who has no co-wife cannot yet identify her disease

Òwe yi fi ara han ni itan iyàwó Aṣojú-ọba, ti a ò pè ni Tinumi pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ọkùnrin ti a mọ̀ si Mofẹ́.  Mofẹ́ dàgbà lati fẹ obinrin.  Ó̀ yan obinrin ti à ńpè ni Àyànfẹ́ ni iyàwó àfẹ́sọ́nà.  Nigbati ó mú Àyànfẹ́ lọ han àwọn òbi rẹ, Bàbá Mofẹ́ gba Àyànfẹ́ tọwọ́-tẹsẹ̀, ṣùgbọ́n iyá Mofẹ́ fi àáké kọ́ri pé ọmọ ohun kò ni fẹ́ Àyànfẹ́.  Wọn bẹ̀rẹ̀ idi ti kò ṣe fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ ẹni ti ó múwá, Tinumi kò ri àlàyé ṣe ju pé ohun kò fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ́ “Àtọ̀hún rin wa – ọmọ ti kò ni iran”.  Ọmọ rẹ naa fi àáké kòri pé ẹni ti ohun ma fẹ ni Àyànfẹ́.

Tinumi sọ àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ di orogún, gbogbo ibi ti ó bá ti pàdé Àyànfẹ ni ibi àjoṣe ẹbi ni ó ti ḿbajà pé ki ó dẹ̀hin lẹhin ọmọ ohun.  Àyànfẹ́ lé ọmọ rẹ titi ṣùgbọ́n ó kọ̀ lati dẹhin.

Lẹhin ọdún marun ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ti ńṣe ọ̀rẹ́, iwé jade pé wọn gbé Bàbá Mofẹ́.  Gẹgẹ bi Aṣojú-Ọba lọ si Òkè-òkun.  Bàbá ṣètò bi ọmọ àti iyàwó ti ma tẹ̀lé ohun.  Ọmọ kọ̀ pé ohun kò lọ pẹ̀lú òbi ohun ti àfẹ́sọ́nà ohun kò bá ni tẹ̀lé àwọn lọ.  Bàbá gbà pé ọmọ ohun ti tó fẹ́ iyàwó, wọn ṣe ètò igbéyàwó fún Mofẹ́ àti àfẹ́sọ́nà̀ rẹ.  Lẹhin ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ṣe iyàwó tán, wọn tẹ̀lé Bàbá àti Ìyá wọn lọ si Òkè-okun lati má jọ gbé.

Àrùn ara Tinumi, aya Aṣojú-ọba bẹ̀rẹ̀ si han nitori ó sọ iyàwó ọmọ rẹ di orogún.  Nigbati ọkọ rẹ ri àlébù yi, ó pinu lati wa orogún fun Tinumi nitori ai ni orogún ni ó ṣe sọ aya ọmọ rẹ di orogún.  Gẹgẹ bi a ti mọ, igbéyàwó ibilẹ̀ kò ni ki ọkùnrin ma fẹ iyàwó keji.  Nigbati Bàbá Mofẹ́ fẹ́ iyàwó kékeré, ọmọ àti iyàwó kó kúrò lọ si ilé tiwọn, inú rẹ bàjẹ́ nigbati o kũ pẹ̀lú orogún rẹ.  Ó jẹ èrè iwà burúkú àti ìgbéraga.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-06-20 13:30:24. Republished by Blog Post Promoter

A ki yin lati Ilé – Greetings from Home

Ni ai pẹ yi, Olùkọ̀wé yi bẹ ilé wò fún bi ọ̀sẹ̀ mẹta.  A ṣe àwọn akiyesi wọnyi.  Ilú Èkó n fẹ̀ si, ṣùgbọ́n ọ̀nà kò fẹ̀ tó bi èrò àti ọkọ̀ ti pọ̀ tó, nitori eyi, sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki ará ilú gbádùn.  Àwọn ti ó nlọ si ibi iṣẹ́ agogo mẹjọ ni lati kúrò ni ilé ki agogo marun tó lù, wọn yio si wọlé ni agogo mẹwa lẹhin ti wọn bá pari iṣẹ́ ni agogo marun.  Ó kéré jù, òṣìṣẹ́ yio lo wákàtí mẹfa lati lọ àti bọ ni ibi iṣẹ́ nitori sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀.

Sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ - Traffic Jam.  Cpurtesy: @theyorubablog

Sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ – Traffic Jam. Cpurtesy: @theyorubablog

Ìjọba ko ti i ṣe ìpèsè omi ẹ̀rọ, ọ̀nà àdúgbò àti ohun amáyédẹrùn igbàlódé pàtàki ni àwọn agbègbè tuntun.  Iná mọ̀nàmọ́ná ti dára di ẹ̀ si, nitori iná kò lọ púpọ̀ mọ́ bi ti tẹ́lẹ̀.

Ni àwọn olú ilú ilẹ̀ Yorùbá yókù bi Ìbàdàn, Òṣogbo, Abẹ́òkúta, Àkúrẹ́ àti Adó-Èkìtì, kò si sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ bi ti Èkó ṣùgbọ́n iná mọ̀nàmọ́ná kò ṣe déédé bi ti ilú Èkó.  Ọ̀wọ́n epo-ọkọ̀ ti ó gbòde ni igbà ọdún Kérésìmesì ti ó kọjá àti ni ibẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti lọ ṣùgbọ́n epo-ọkọ̀ wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé epo ni àwọn olú ilú yókù ju ti Èkó.  Gbogbo ohun tita ló ti wọ́n si.

Ó ṣòro lati lo ayélujára nitori ai ṣe déédé iná mọ̀nàmọ́ná àti ayélujára, pàtàki bi enia ba jade kúrò ni ilú Èkó, ṣùgbọ́n ó sàn ju ti àtẹ̀hin wá lọ.  Ni àpapọ̀, ọyẹ́ jẹ́ ki ẹni ti ó bá nti Òkè-Òkun bọ̀ gbádùn nitori ooru din kù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-09 22:16:55. Republished by Blog Post Promoter

‘Gómìnà Ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ pèsè omi mi mun fún ará ilú ki wọ́n yé gbẹ́lẹ̀ kiri bi Òkété’ – ‘Yoruba Governors, provide your people safe water to prevent the digging of holes like Bush Rats’

Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ni abẹ́ Olóògbé Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi, da gbogbo ipinlẹ̀ pọ si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀.  Ki wọ́n tó dá àwọn ipinlẹ̀ pọ̀, àwọn ipinlẹ̀ ndàgbà sókè gẹ́gẹ́ bi ohun ti ó ṣe kókó fún wọn.  Ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, ti ẹ̀yà Yorùbá ngbé, ni ìgbéga ni abẹ́ Olóri Òṣèlú Ipinlẹ̀, Olóògbé́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti ẹgbẹ́ Òṣèlú rẹ.  Wọ́n pèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé bi ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, ọ̀nà gidi, omi mi mun, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ ẹ̀  bẹ́ ẹ̀ lọ ni gbogbo agbègbè ilẹ́ Yorùbá.  Eleyi jẹ ki Yorùbá ri ohun mu yangàn.

Yàtọ̀ si Ìjọba Ológun lábẹ́ Ọ̀gágun Yakubu Gowon, ti ó lo ọ̀pọ̀ owó epo rọ̀bì dáradára lati pèsè ohun amáyédẹrùn ti igbàlódé ti ilú ngbádùn titi di ọjọ́ oni,  ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjọba Nigeria yókù ti ó ré kọjá lábẹ́ Ológun àti Òṣèlú kùnà nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn fún orilẹ̀ èdè nitori iwà ibàjẹ́.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó sọ wi pé “Ni ilú afọ́jú, olójú kan lọba”, laarin Ìjọba àpapọ̀, nitori iwà-ibàjẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a lè sọ wi pé àwọn ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́ ṣe dáradára nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn.  Àmọ́, ‘ilọsiwájú’ yi kò tó nkankan lára ogún ti Olóògbé Olóyè Awólọ́wọ̀ ṣe silẹ̀.  Kò si ipèsè ohun amáyédẹrùn pàtàki omi mi mun ni àwọn agbègbè tuntun lai yọ àdúgbò ọlọ́rọ̀ silẹ̀.  Eleyi ló sọ gbi gbẹ́ ihò fún omi àti kànga lati wá omi fún mi mun di àṣà.

Àwọn ipinlẹ̀ Yorùbá́ ti gbádùn ohun amáyédẹrùn igbàlódé fún ọjọ́ ti pẹ́, nitori èyi ni a ṣe mbẹ̀ àwọn Gómìnà ipinlẹ̀ Yorùbá pé ki wọn pèsè ‘’omi mi mun’ fún ará ilú gẹ́gẹ́ bi ẹ̀tọ́ lati dá àṣà gbi gbẹ́ ilẹ̀ bi ti Òkété lati wa omi ti kò ṣe e mu ni ọ̀pọ̀ igbà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-09-02 19:00:18. Republished by Blog Post Promoter

Ódìgbóse Àgbà Òṣère Olóyè Jimoh Aliu (Àwòrò)– Tribute to Chief Jimoh Aliu (Aworo)

Ìròyìn kàn ni ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kẹsan ọdún Ẹgbàalélógún pé àgbà òṣèré Olóyè Jimoh Aliu (ti a mọ̀ si Àwòrò ninú eré) di olóògbé.  Olóyè Jimoh Aliu pé bi ọdún marunlélọgọ́rin ki wọn tó dágbére fún ayé lẹhin àìsàn ránpẹ́. 

Olóyè Jimoh Aliu (Àwòrò)
Olóyè Jimoh Aliu (Àwòrò)

Olóògbé Jimoh Aliu gbé èdè àti àṣà Yorùbá ga gidigidi pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré orí ìtàgé àti lóri ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.  Eré ti opolopo gbádùn jù ni ori amóhùnmáwòrán ni “Yánpanyánrin” nitori Jimoh Aliu ti ó ṣe Àwòrò, ìyàwó Jimoh Aliu ti ó ṣe Òrìṣàbùnmi àti Òjó Arówóṣafẹ́ ti ó ṣe Fádèyí Olóró. 

Gẹ́gẹ́bi ẹ̀sin àti iṣe àwọn Mùsùlúmi, wọn o sin òkú ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kejidinlógún, oṣù kẹsan ọdún Ẹgbàalélógún.   

Olóyè Jimoh Aliu sùn re o.

ENGLISH TRANSLATION

On Thursday, September seventeen, year 2020, news of the death of a very prominent Yoruba Actor, Chief Jimoh Aliu (stage name Aworo) was announced.   Late Jimoh Aliu aged eighty-five passed on after a brief illness.

Continue reading
Share Button

Originally posted 2020-09-18 02:36:48. Republished by Blog Post Promoter

“Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”: “A borrowed trouser/pant, if it is not too loose on the legs, it is too tight at the thigh”.

Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá.

Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀.  Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú.  Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru.  Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù.

Èdè ẹnu wọn kò jọ Oyinbo, kò jọ Yorùbá nitori àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”.  Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni.  Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa.  Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nitori aṣọ àlòkù/òkèrè ti àwọn ọdọ kó owó lé .  A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nitori èdè Gẹẹsi wi.  Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun/Ìlú-Oyinbo lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-13 16:33:18. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹni tó Lórí kò ní Fìlà, Ẹni tó ní Fìlà kò Lórí”: “The one who has a Head has no Cap, the one who has a Cap has no Head”

Fìlà Aṣọ Òfì

Fìlà Aṣọ Òfì – Traditional Yoruba Cap
Courtesy: @theyorubablog.com

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ní “Ẹni tó Lórí kò ní Fìlà, Ẹni tó ní Fìlà kò Lórí”.

Tani eni “Ẹni tó Lórí ti kò ní Fila”?  Enití gbogbo àyè wà fún lati ṣe nkan nla bi ka kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ lati pèsè àyè à́ti ohun améyédẹrùn fún ìlú àti ará ìlú tí kò ló àyè yi.

Tani “Ẹni tí ó ni Fìlà tí kò Lórí”? Eni tí ìlú tàbí òbí ti pèsè àyè àti gbogbo ohun améyédẹrùn fún láti lè kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ ṣùgbọ́n tó kọ̀ láti kọ ẹ̀kọ́ tàbi kó kọ́ iṣẹ́ ọwọ..

Kò sí ẹni tó le ni fìlà lai lórí, nítorí Ọlọrun dá Orí fún gbogbo ẹ̀dá alàyè, ṣùgbọ́n ènìà lè̀ lóri, kó má ni fìlà tí ó jẹ́ àtọwọ́dá ọmọ ènìà.  Nítorí ìdí èyi, “Ẹni tó lórí yẹ kó ní Fìlà”, nípa lí lo orí lati pèsè àyè àti ohun amáyéderùn.  Fún àpẹrẹ, ai lo orí lati pèse ohun améyédẹrùn ló fa sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ ni ìlú Èkó nítorí bi Èkó bá lo ọkọ ojú omi, ọkọ̀ Ojúirin pẹ̀lú ọkọ̀ Orí ilẹ̀ lati kó ènìà àti ẹru lati ibìkan dé ibìkejì, sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ á dín kù gidigidi àti wípé a dín ìyà àti àsìkò ti àwọn èrò nlo lójú ọ̀nà lójojúmọ́ kù.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba adage that said “The One who has a Head has no Cap, the One who has a Cap has no Head”.

“Who can be described as having a head without a Cap”?   Anyone that has failed to utilize the opportunity available to him/her and the community.

“Who can be described as having a cap without a head”?  This is the one who has no opportunity, despite his/her potentials to become responsible to him/herself and for the Society by refusing to acquire education or skill.

In the true sense, “No one can have a Cap without a Head”, because God created every living thing with a “Head”, but “One can have a Head without a Cap”, because Cap is manmade.  As a result, “Anyone with a Head should have a Cap” by using the Head to create the Cap, which in this case is the opportunity and the infrastructure.  For example, most often not using the Head to create the infrastructure is the bane of heavy traffic gridlock in Lagos because if Boats are used for Sea/Water Transportation as well as Train and Vehicular Transportation, this would reduce the unnecessary daily loss of time and the suffering of the commuters.

Share Button

Originally posted 2013-05-24 22:46:31. Republished by Blog Post Promoter

Welcome to the Yoruba Blog…

The home of all things Yoruba… news, commentary, proverbs, food. Keeping the Yoruba culture alive.

Share Button

Originally posted 2013-01-24 21:03:41. Republished by Blog Post Promoter

Bi Egúngún/Eégún bá ńlé ni ki a má rọ́jú, bi ó ṣe ńrẹ ará ayé, ló ńrẹ ará Ọrun – “If one is being pursued by the Yoruba Masquerade, one should persevere, as the living do get tired, so also are the spirits”

Yorùbá ma ńṣe ọdún Egúngún/Eégún ni ọdọ-dún lati ṣe iranti Bàbánlá/Ìyánlá wọn ti ó ti di olóògbé nitori wọn ni iṣẹ́ lati ṣe laarin alàyè lati rán ará ilú leti pé ki wọn di àjogúnbá ẹ̀kọ́ iwà rere mú.  Yorùbá má ńpe Egúngún/Eégún ni “Ará Ọ̀run”.

Egúngún/Eégún ma ńgbé ọ̀pá tàbi ẹgba lati na ẹni ti ó bá hu iwà burúkú ni àwùjọ.  Fún àpẹrẹ, obinrin ti kò múra dáradára tàbi ẹni ti ó bá wọ bàtà, Eégún á le lati naa.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi Egúngún/Eégún bá ńlé ni ki a má rọ́jú, bi ó ṣe ńrẹ ará ayé, ló ńrẹ ará Ọrun”, ṣe gba ẹni ti ó bá wà ninú ìṣòro ni ìyànjú pé, ìṣòro yi ki ṣe ohun ti kò ni tán tàbi ni òpin.  Èyi tùmọ́ si pé, ìṣòro yi á ré kọjá bi enia bá lè rọ́jú.

ENGLISH TRANSLATION

ọdún Egúngún/Eégún – Yoruba Masquerade Festival

Yoruba Masquerade Festival is held annually in memory of the Ancestors that have passed on, because they have responsibility among the living to remind them to continue with the moral ethics left by the Ancestors.  Yoruba Masquerades are regarded as “Spirits or Alien”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-08-07 03:30:43. Republished by Blog Post Promoter

“Ìfura loògùn àgbà, àgbà ti kò sọnú, á sọnù”: “Suspicion is the medicine of the elder, an unthoughtful elder will be lost”

Ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni ó lè fún àgbà ni ọgbọ́n àti òye lati lè sọnú.  Oriṣiriṣi ọ̀nà ni a lè fi gbà kọ́ ẹ̀kọ́, ṣugbọn ni ayé òde òni, ohun gbogbo ni a lè ri kọ́ ni orí ayélujára.

Bi ayélujára ti sọ ayé di ẹ̀rọ̀ tó bẹ̃ ló tún bayé jẹ́ si.  Àwọn ọmọ ìgbàlódé mọ èlò ẹ̀rọ ayélujára ju àgbàlagbà lọ.  Àgbà ti kò bá ni ìfura, ki o si kọ ẹ̀kọ́ lilo ẹ̀rọ ayélujára á sọnù.

Ki ṣe orí ẹ̀rọ ayélujára nikan ni ó ti yẹ ki àgbà ma fura ki o ma ba sọnù.  Àgbà ni lati ṣe akiyesi àwọn ohun wọnyi: ṣọ́ra fún àwọn Òṣèlú nipa ṣi ṣọ́ ìbò ti a di dáradára;  owó ni ilé ifowó-pamọ́; wi wo àyíká fún amin ewu ti o le wa ni àyíká; ṣi ṣọ irú ounjẹ ti o yẹ ki a jẹ; àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-09 10:30:49. Republished by Blog Post Promoter