Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pataki àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́ lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko. Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nitori adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ. Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé (Nigeria), ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nitori dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná.
Ó ṣeni lãnu pé “oko” ninu àlàyé yi (òkè-òkun/ìlú-oyinbo) sàn ju “ilé” Èkó. Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, “kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si”. Ni totọ, àwọn Oní-ṣòwò ni orílẹ̀ èdè Nigeria ǹgbìyànjú, nitori kò rọrùn lati ṣòwò ni ìlú ti ohun amáyé-dẹrùn ti ìgbàlódé bi iná mona-mona, òpópónà tó dára, omi mimu, àbò, àti bẹbẹ̃ lọ, kò ti ṣe dẽde. A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pataki ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀. Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko.
A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n “omi pọ̀ ju ọkà lọ”. Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú. “Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe”, nitori eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pataki ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2013-11-15 21:57:48. Republished by Blog Post Promoter