Category Archives: Yoruba Proverbs

Discussing as many Yoruba proverbs as possible and relating them to day to day life…

ỌRỌ ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE): Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ

R ÌYÀNJÙ (WORD OF ADVICE)

Ẹyin ọmọ Odùduwà ẹjẹ ki a ran rawa létí wípé “Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ”.  Mo bẹ yin  ẹ maṣe jẹki  a tara wa  lọpọ nitorina ẹ maṣe jẹki èdè Yorùbà parẹ. Èdè ti a kọ silẹ, ti a ko sọ, ti a ko fi kọ ọmọ wa, piparẹ ni yio parẹ.  Ẹjẹ ki a gbiyanju lati ṣe atunṣe nipa sísọ èdè Yorùbà botiyẹ kasọ lai si idaru idapọ pẹlu  èdè miran.

Yorùbá lọkunrin ati lobirin ẹ ranti wipe “Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe”   Lágbára Ọlọrun, aoni tajo sọnu sajo o, ao kere oko délé o (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-01-31 20:18:56. Republished by Blog Post Promoter

“Bi a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” – “If one lives long enough, one will consume as much meat as an elephant”

Erin - Elephant

Erin – Elephant

Erin jẹ ẹran ti ó tóbi ju gbogbo ẹranko ti a mọ̀ si ẹran inú igbó àti ẹran-àmúsìn, ti a mọ̀ ni ayé òde òni.  Bi a bá ṣe àyẹ̀wò bi Yorùbá ti ńgé ẹran ọbẹ̀, ó ṣòro lati ro oye ẹran ti enia yio jẹ ki ó tó Erin.

Isọ̀  Eran – Meat Stall. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Bawo ni òwe Yorùbá ti ó ni “Bi  a bá pẹ́ láyé, a ó jẹ ẹran ti o ́tó Erin” ti wúlò fún ẹni ti ki jẹ ẹran ti a mọ̀ si “Ajẹ̀fọ́”?  Àti Ajẹ̀fọ́ àti Ajẹran ni òwe yi ṣe gbà ni iyànjú pé “Ohun ti kò tó, ḿbọ̀ wá ṣẹ́ kù”. Fún àpẹrẹ, bi enia bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nibi kékeré, bi ó bá tẹramọ́, yi o di ọ̀gá, yio si lè ṣe ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ibi giga ṣe.  Bi enia bá ni oreọ̀fẹ́ lati pẹ́ láyé, ti ó dúró tàbi ni sùúrù, yio ri pé ohun jẹ ẹran ti ó tó Erin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-12 18:29:05. Republished by Blog Post Promoter

Àjùmòbí kò kan tãnu… Same parentage does not compel compassion…

Ajumomobi o ko ti anu

Same parentage does not compel compassion.

Òwe Yorùbá ní “Àjùmòbí kò kan tãnu, ẹni Olúwa  bá rán síni ló nṣeni lõre”.  Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l’Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé.

Yorùbá ní “Òṣìṣẹ́ wa lõrun, abáni náwó wà níbòji”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí wọnyi, ma mba ẹni tí o nṣiṣẹ ka owó lai rò wípé ẹni tí ó nṣiṣẹ yi, nlãgun lati rí owó.  Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l’Ókè-Òkun/Ìlú-Òyìnbó nṣe nínú òtútù.  Fún àpẹrẹ: níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ̃bẹ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l’Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn.

Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba.  Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí.  Ẹbí tóní owó tàbí gbé Òkè-òkun lè fi ojú ãnu ṣe ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ki ṣe iṣẹ́ ẹni bẹ̃ lati gbé ẹrù ẹlẹ́rù.   Ẹjẹ́ ká rántí òwe yi wípé “Àjùmọ̀bí kò kan tãnu, ẹni Olúwa bá rán síni ló nṣeni lõre”, nítorí aladugbo, àjòjì, ọ̀rẹ́, àti bẹ̃bẹ lọ, lè ṣeni lãnu bí Olúwa bá rán wọn.

ENGLISH TRANSLATION

A Yoruba saying goes that “same parentage does not compel compassion, only those sent by God show compassion”.  This proverb can be used to advice those dependent on family member.  Many dependents think it is a right for rich or family members living abroad to carry their responsibilities. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-18 18:00:26. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi: ìyànjú fún àwọn omidan” – “There are two hundred and one suitors to a spinster, only one would make a good husband: Caution for ladies”

Ni ayé àtijọ́, òbi si òbi àti ẹbi si ẹbi ló nṣe ètò iyàwó fi fẹ́ fún ọmọ ọkùnrin ti ó bá ti bàláágà, ti wọn rò pé ó lè tọ́jú iyàwó.  Obinrin ki tètè bàláágà, nitori ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ṣe nkan oṣù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin ma ndàgbà tó bi ọdún mẹrin-din-lógún tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ.  Gẹgẹ bi wọn ti ma nsọ ni igbà igbéyàwó ibilẹ “òdòdó kán wà lágbàlá ti a fẹ́ já”, bi òbi tàbi ẹbi bá ṣe akiyesi ọmọ obinrin ti ó wù wọn lati fẹ́ fún ọmọ ọkunrin wọn, yálà idilé si idilé tàbi ni agbègbè ni ibi “ọdún omidan”, wọn yio lọ bá òbi/ẹbi obinrin na a lati bẹ̀rẹ̀ ètò bi wọn yio ti fẹ fún ọmọ wọn. Ni ayé igbàlódé, obinrin yára lati bàláágà, nitori omiran a bẹ̀rẹ̀ nkan oṣú ni bi ọmọ ọdún mọ́kànlá.  Obinrin ki yára fẹ́ ọkọ mọ nitori ilé-iwé àti pé ki ṣe òbi àti ẹbi ló nfẹ́ obinrin fún ọmọ ọkùnrin mọ.

Yorùbá ma nlò ọ̀rọ̀ ti ó sọ pé “Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi” lati la obinrin lóye pé ki ṣe gbogbo ọkunrin ti ó bá wá bá obinrin lati sọ̀rọ̀ ifẹ́ ló ṣe tán lati fẹ́ iyàwó, gbogbo wọn kọ́ si ni “ọkọ gidi”.  Kò yẹ ki obinrin kanra tàbi lé ọkùnrin ti ó bá kọ ẹnu ifẹ́ si wọn pẹ̀lú èébú, nitori Yorùbá sọ wipé, “A kì í kí aya-ọba kó di oyún” ṣùgbọ́n ki wọn farabalẹ̀ lati mọ irú ẹni ti ọkùnrin na a jẹ.  Li lé ọkùnrin nigbati ọ̀pọ̀ ọkùnrin bá fẹ́ yan obinrin lọrẹ, pàtàki ni igba ti obinrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bàláágà, lè fa ki obinrin ṣe àṣimú ni igba ti wọn bá ṣe tán lati fẹ́ ọkọ, nitori ó ti lè bọ́ si àsikò ikánjú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-03 21:50:24. Republished by Blog Post Promoter

“Ni ilú Afọ́jú, Olójú kan Lọba”: Ìjọba Òṣèlú tuntun gba Ìjọba ni Orilẹ̀-èdè Nigeria – “In the Country of the Blind, One-eyed person is the King”: Transfer of Democratic Power from the incumbent to the Elected in Nigeria

Ọjọ́ itàn ni ọjọ́ kọkàndinlógún, oṣù karun, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún jẹ fun orilẹ̀ èdè Nigeria àti gbogbo ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.  Kò wọ́pọ̀ ki Ìjọba Ológun tàbi Ẹgbẹ́ Òṣèlú gbà lati gbé Ìjọba silẹ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú  nitori eyi àwọn Olóri Òṣèlú lati orilẹ̀ èdè bi mẹrinléladọta pé jọ si Abuja, olú-ilú Nigeria lati ṣe ẹlẹri gbi gbé Ìjọba lati ọ̀dọ̀ Olóri kan si ekeji.

Goodluck Ebele Jonathan gbé Ìjọba fún  Muhammadu Buhari - Handing over

Goodluck Ebele Jonathan gbé Ìjọba fún Muhammadu Buhari – Handing over

Yorùbá sọ wi pé “Melo la ó kà leyin Adépèlé”, a ó ṣe àyẹ̀wò di ẹ̀ ninú àpẹrẹ àwọn Olóri Òṣèlú Aláwọ̀dúdú tó jẹ Oyè “Akintọ́lá ta kú”: Ọ̀gágun Olóògbé Muammar Gaddafi ti Libya ṣe titi wọn fi pa si ori oyè lẹhin ọdún méjilélogóji; Hosni Mubarak ti Egypt wà lóri oyè titi ará ilú fi le kúrò lẹhin ọgbọ̀n ọdún; ará ilú gbiyànjú ṣùgbọ́n wọn ó ri Bàbá Robert Mugabe (arúgbó ọdún mọ́kànlélãdọrun) ti Zimbabwe lé kúrò lati ọ̀rùndinlógóji ọdún; Paul Biya ti Cameroon ti ṣe Olóri Òṣèlú lati ogóji ọdún; Omar al-Bashir ti Sudan ti wà lóri oyè fún ọdún méjilélógún.  Àwọn ọ̀dọ́ ti a lérò wi pé yio tun yi iwà padà kò yàtọ̀ bi wọn bá ti dé ipò.  Pierre Nkurunziza ti Burundi gbà ki àwọn ará ilú kú, ju ki ó ma gbe àpóti ibò ni igbà kẹta lẹhin ọdún mẹwa;  Joseph Kabila – Olóri Òṣèlú Congo lati ọdún mẹrinla; Olóri Òṣèlú Togo Faure Gnassingbé ti wà lóri oyè fún ọdún mẹwa lehin iku Bàbá rẹ, kò dẹ̀ fẹ́ kúrò àti ọ̀pọ̀ tó ti kú si ori oyè.

Yorùbá sọ wi pé “Ni ilú Afọ́jú, Olójú kan Lọba”, ọ̀rọ̀ yi gbà ọpẹ́ fún orilẹ̀-èdè Nigeria, nitori Olóri Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan, gbà lati gbé Ìjọba fún Olóri Ogun Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ́ míràn lai si ìjà.  Irú eyi ṣọ̀wọ́n, pàtàki ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.  Ẹgbẹ́ Òṣèlú Alágboòrùn ti ṣe Ìjọba fún ọdún mẹ́rindinlógún ki ilú tó fi ibò gbé wọn kúrò ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olóri àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú, ọdún mẹ́rindinlógún kéré.   Ká ni Olóri Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan bá kọ̀ lati ki ẹni ti ilú yàn Olóri-ogun Muhammadu Buhari ku ori ire ni idije idibo, ijà ki ba ti bẹ́.  Eleyi fi hàn pé Ọlọrun ni ifẹ Nigeria, ó ku ka ni ìfẹ́ ara. A lérò wi pé àwọn Olóri àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú yoku yio fi eyi kọ́gbọ́n

A ki Òṣèlú Goodluck Ebele Jonathan ti ó gbé Ìjọba fún Olóri-ogun Muhammadu Buhari ti ilú fi ibò yàn, àwọn ọmọ Nigeria ti ó dibò fún àyipadà àti gbogbo ọmọ Nigeria ni ilé lóko kú ori ire ọjọ́ pàtàki yi ni itàn orilẹ̀ èdè Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-29 15:28:02. Republished by Blog Post Promoter

ẸNITÍ ỌLỌRU KÒ DÙN NÍNÚ TÓ NLA ṢÚGÀ, JẸ̀DÍJẸ̀DÍ LÓ MA PÁ: WHOEVER GOD HAS NOT MADE GLAD THAT IS LICKING SUGAR WILL DIE OF PILE”

Yorùbá ní “Ẹnití Ọlọrun kò dùn nínú, tó nla ṣúgà (iyọ̀ ìrèké), jẹ̀díjẹdí ló ma pá”.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ṣ̀e àtìlẹhìn fún iwadi tó fihàn wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ìrẹ̀wẹ̀sì mbaja ma mu ọtí àti jẹ oúnje ọlọra, ti iyọja tàbí tí iyọ̀ ìrèké pọ̀ nínú rẹ.  Ó ṣeni lãnu wípé, kàka ki ẹni bẹ͂ jade nínú ìrẹ̀wẹ̀sì, oúnje tó kún fún ọ̀rá, iyọ̀ àti iyọ̀ ìrèké (ṣúgà) mã dákún àìsàn míràn bi: jẹ̀díjẹdí, ẹ̀jẹ̀ ríru àti oniruuru àìsàn míràn.

Oúnje dídùn àti ọtí mímu kò lè mú ìrẹ̀wẹ̀sì kúrò tàbí fa ìdùnnú, ṣùgbọ́n àyípadà ọkàn sí ìwà rere àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun ló lè mú inú dùn.

Ẹkú ọdún Ajinde o, ẹ ma jẹ́un ju, Jesu ku fun ẹlẹ́sẹ̀ àti aláìní, nítorí nã ti ẹ ba ri jẹ, ẹ rántí áwọn ti ko ri.  Yorùbá ni “ajọjẹ kò dùn bẹni kan o ri”.

ENGLISH TRANSLATION

The Yoruba adage that “Whoever has not been made glad by God that is licking sugar will die of pile” is in support of the research that showed that most people drink and eat more fatty, salty and sugary food when they are depressed.  Unfortunately, instead of coming out of depression, bad diet containing too much fat, salt and sugar will only add more health complications such as pile, hypertension and a host of other diseases.

Tasty food or alcoholic drink would not lift anyone out of depression or gladness of spirit, but only positive attitude and trust in God.

Happy Easter, do not over feed, Jesus died for the sinners and the poor, as a result if you have, remember those who have none.  Youruba said “Eating together is not sweet, if one person is left out”.

Share Button

Originally posted 2013-03-30 00:03:05. Republished by Blog Post Promoter

“Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” – “Poverty is lonesome while success has many siblings”

Ni ayé igbà kan, bi èniyàn bá jẹ́ alágbára, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, ti ó si tún ni iwà ọmọlúwàbí, iyi wà fun bi kò ti ẹ ni owó, ju olówó rẹpẹtẹ ti kò si ẹni ti ó mọ idi owó rẹ ni áwùjọ tàbi ti kò hùwà ọmọlúwàbí.  Ni ayé òde òni, ọ̀wọ̀ wà fún olówó lai mọ idi ọrọ̀, eyi ló njẹ ki irú àwọn bẹ́ ẹ̀ dé ipò Òsèlú, Olóri Ìjọ tàbi gba oyè ti kò tọ́ si wọn.

Ìbẹ̀rù òṣì lè jẹ́ ki èniyàn tẹpá-mọ́ṣẹ́, bẹ ló tún lè jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fi ipá wá owó.  Ìfẹ́ owó tó gba òde kan láyé òde òni njẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ jalè tàbi wá ipò agbára ti ó lè mú ki wọn ni owó ni ọ̀nà ti kò tọ́.  Òṣèlú ki fẹ́ gbé ipò silẹ̀ nitori ìbẹ̀rù pé bi agbára bá ti bọ́, ìṣẹ́ dé.  Àpẹrẹ tani mọ̀ ẹ́ ri pọ̀ lára àwọn Òsèlú ti agbára bọ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba ti ipò rẹ bọ́, Olóri Ìjọ ti ó kó ọrọ̀ jọ ni orúkọ Ọlọrun ló nri idá mẹwa gbà ju Olóri Ìjọ ti kò ni owó.

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” fi hàn pé owó dára lati ni, ṣùgbọ́n kò dára lati fi ipá wá ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.  Kò yẹ ki èniyàn fi ojú pa ẹni ti kò ni rẹ́ tàbi sá fún ẹbi ti kò ni, nitori igbà layé, igb̀a kan nlọ, igbà kan mbọ̀, ẹni ti ó ni owó loni lè di òtòṣì ni ọ̀la, ẹni ti kò ni loni lè ni a ni ṣẹ́ kù bi ó di ọ̀la.  Nitori eyi, iwà ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ki i ṣe owó tàbi ipò.

ENGLISH TRANSLATION

In time past, if a person is strong, hard working with good moral character, such person is honoured even though he/she may not be rich rather than a very rich person whose source of Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-19 15:23:07. Republished by Blog Post Promoter

“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”

Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́.  Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara.    Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi.  Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.

Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo  èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò.  Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku.  Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni.  Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.

A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ.  Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter

“Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà” – “Headship of a Family is the Father of Responsibilities”

Olóri Ẹbi - Head of the Family connotes responsibiliies.  Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi – Head of the Family connotes responsibiliies. Courtesy: @theyorubablog

Olóri Ẹbi jẹ àkọ́bi ọkùnrin ni idilé.  Bi àkọ́bi bá kú, ọkùnrin ti ó bá tẹ̀le yio bọ si ipò.  Iṣẹ́ olóri ẹbi ni lati kó ẹbi jọ fún ilọsiwájú ẹbi, nipa pi pari ijà, ijoko àgbà ni ibi igbéyàwó, ìsìnkú, pi pin ogún, ìsọmọ-lórúkọ, ọdún ìbílẹ̀ àti ayẹyẹ yoku.

Ni ayé òde òni, wọn ti fi owó dipò ipò àgbà, nitori ki wọn tó pe olóri ẹbi ti ó wà ni ìtòsí, wọn yio pe ẹni ti ó ni owó ninú ẹbi ti ó wà ni òkèrè pàtàki ti ó bá wà ni Èkó àti àwọn ilú nla miran tàbi Ilú-Òyinbó/Òkè-Òkun. Ai ṣe ojúṣe Ìjọba nipa ipèsè ilé-iwòsàn ti ó péye, Ilé-iwé, omi mimu àti ohun amáyédẹrùn yoku jẹ ki iṣẹ́ pọ fún olóri ẹbi.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ wi pé “Olóri Ẹbi, Baba Bùkátà”, iṣẹ́ nla ni lati jẹ Olóri Ẹbi, ó gba ọgbọ́n, òye àti ìnáwó lati kó ẹbi jọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-02-12 10:30:05. Republished by Blog Post Promoter

Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ – If the Hunter thinks of the suffering in the wild, he would not share his kill with anyone.

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ - Hunter

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ – Hunter

Láyé àtijọ́, iṣẹ́ Ọdẹ jẹ ikan ninú iṣẹ gidi ni ile Yorùbá.  Ògbójú Ọdẹ ló npa ẹranko bi Erin, Ẹkùn, Kìnìún àti Ẹfòn, Ìmàdò, Ikõkò, nígbàtí àwọn to nṣe Ọdẹ etílé npa ẹranko ìtòsí ilé bi Ọ̀kẹ́rẹ́, Òkété, Ọ̀bọ àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹran ìgbẹ bi Ìgalà, Àgbọ̀nrín àti , ẹran ọ̀sìn bi Àgùntàn, Ewurẹ, Òbúkọ, Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ ẹran tí o wọ́pọ̀ fún jíjẹ ni ayé àtijọ dípò ẹran Mãlu tí ó wá wọpọ láyé òde òní.

Àwọn ẹranko bi Ẹfọ̀n, Erin, Kìnìún, Ẹkùn ti dínkù nígbàtí ẹranko bi Àgbánreré ti parẹ́ ni ilẹ̀ Yorùbá.

A lè fi ò̀we Yorùbá “Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ” wé ìyá ti àwọn ti ó wà ni Ìlúọba/Ò̀kèòkun njẹ nínú òtútù lati pa owó.  Nínú owó yi, wọn a ronú àti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti wọn gbìyànjú lati ràn lọ́wọ́, ki i wo ìya ti ojú wọn rí.

Ẹ rántí wípé ẹni ti o bá laanu ló lè ronú lati ran ẹlòmíràn lọ́wọ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-23 10:15:07. Republished by Blog Post Promoter