Category Archives: Yoruba Folklore

Kò si ọgbọ́n to lè dá, kò si ìwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn – Ìtàn Bàbá Oní-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́: “No amount of wisdom or character displayed can please the world.

Oni - kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́  - The Horseman & his son

Oni – kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ – The Horseman & his son

Ni aiyé àtijọ́, ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló dàbi ọkọ̀ igbàlódé ti wọn ńpè ni mọ́tò.  Ẹni ti ó jẹ́ ọlọ́rọ̀, ló lè ni ẹsin tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ńrin irin àjò.

Ìtàn yi dá ló̀ri Bàbá àti ọmọ rẹ ti wọn ńsin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Wọn múra lati rin irin àjò.  Gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá lati bu ọ̀wọ̀ fún àgbà, Bàbá ló gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ si rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn enia ti o ri wọn ni “Bàbá, iwọ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ńrin ni ilẹ̀”.  Nitori ọ̀rọ̀ yi, Bàbá bọ́ silẹ̀, ó gbé ọmọ rẹ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn aiyé tún ri wọn ni “Bàbá ńrin nilẹ̀, ọmọ ńgun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́”.  kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ti dàgbà, ṣùgbọ́n tori ẹnu aiyé, Bàbá àti ọmọ bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.  Wọn ko ti rin jinà nigbati àwọn ti ó ri wọn tún ni “Ẹ wo Bàbá àti ọmọ tó fẹ́ pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́”.  Nitori àti tẹ́ aiyé lọ́run, Bàbá àti ọmọ bọ́ silẹ̀, wọn bẹ̀rẹ̀ si fi ẹsẹ̀ rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.  Àwọn arin irin àjò yókù tún ri wọn, wọn ni “Ẹrú aiyé ni àwọn eleyi, bawo ni wọn ṣe lè ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ki wọn ma fi ẹsẹ̀ rin?”

Nigbati Bàbá ti gbìyànjú titi, ti kò mọ ohun ti ó tún lè ṣe mọ́, lati tẹ́ aiyé lọ́rùn ni ó ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni “Kò si ọgbọ́n ti o lè dá, kò si iwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn”.

Yorùbá ni “Ẹni à ḿbá ra ọjà là ńwò, a ki wó ariwo ọjà̀”.  Lára nkan ti itàn yi kọ́ wa ni pé: ohun ani là ńlò; ibi ti à ńlọ ni ká dojú kọ lai wo ariwo ọjà àti pé enia ni lati ni ọkàn tirẹ̀ nitori kò si ẹni ti ó lè tẹ́ aiyé lọ́rùn.

Ẹ gbọ bi ògúná gbòngbò ninú àwọn ọ̀gá ninú olórin ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú – “Chief Ebenezer Fabiyi” ti a mọ si “Olóyè Adarí” ti fi itàn yi kọrin.

Ebenezer Obey – The Horse, The Man and The Son

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-04-15 22:41:38. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn àròsọ bi obinrin ti sọ Àmọ̀tékùn di alábàwọ́n: The Folklore on how a woman turned the Leopard to a spotted animal.

Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ õjọ́ rẹ lọ.  Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje.  O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ.

Yorùbá ni “Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò”.  Nigbati obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù.  Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni.  (Ẹ ka itàn àròsọ yi ninu iwé ti M.I. Ogumefu kọ ni èdè Gẹ̀ẹ́si).

Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́.  Yorùbá ni “Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́”, nitori eyi ẹ̀kọ́ pàtàki ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-31 18:08:54. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀rù ló sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò/Ológìní tó fi di ” Ẹran-àmúsìn – Ọdẹ peku-peku” – “It is fear that turned the Tiger’s cub to the cat, that became a “domesticated – Rat Hunter”

Ni igbà àtijọ́, ẹranko ti wọn pè ni Ẹkùn jẹ alágbára ẹranko, bẹni Kìnìún si jẹ́ alágbára ẹranko.  Bi Kìnìún ti lágbára tó ninú igbó, bi ó bá bú ramúramù, ohun gbogbo ninú igbó á pa kẹ́kẹ́ titi dé ori ẹranko yoku. Ti Ẹkùn nikan ló yàtọ̀, nitori Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn igbóyà, idi niyi ti a fi ńpè ni “Baba Ẹranko”, ti a ńpè Kìnìún ni “Ọlọ́là Ijù”.

Ni ọjọ́ kan, Ẹkùn gbéra lọ sinú igbó lati lọ wa oúnjẹ fún àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọ ẹ kéré wọn kò lè yára bi iyá wọn.  Ó fún wọn ni imọ̀ràn pe ki wọn kó ara pọ̀ si ibi òkiti-ọ̀gán ti ohun ti lè tètè ri wọn, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù fún ohunkóhun tàbi ẹranko ti ó bá wá si sàkáni wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Kìnìún àti Ẹkùn, ọ̀gá ni onikálùkù láyé ara wọn, wọn ki ja.  Ibi ti Kìnìún bá wà Ẹkùn kò ni dé ibẹ̀, ibi ti Ẹkùn bá wà Kìnìún ò ni dé ibẹ̀.  Nitori èyi ni Yorùbá fi npa lowe pé “Kàkà ki Kìnìún ṣe akápò Ẹkùn, onikálùkù yio má ba ọdẹ rẹ̀ lọ”.

Lai fà ọ̀rọ̀ gùn àwọn ọmọ Ẹkùn gbọ́ igbe Kìnìún, wọn ri ti ó ré kọja, àwọn ọmọ Ẹkùn ti ẹ̀rù ba ti kò ṣe bi iyá wọn ti ṣe ìkìlọ̀, ìjáyà bá wọn, wọ́n sá.  Nigbati Ẹkùn dé ibùdó rẹ lati fún àwọn ọmọ rẹ ni ẹran jẹ, àwọn ọmọ rẹ kò pé, ṣ̀ugbọ́n àwọn ọmọ ti ijáyà bá padà wá bá iyá wọn, nigbà yi ni iyá wọn rán wọn leti ikilọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jáyà.  Nitori èyi, ohun kọ̀ wọ́n lọ́mọ.

Nigbati iyá wọn kọ̀ wọ́n lọ́mọ, wọn kò lè ṣe ọdẹ inú igbó mọ́, wọn di ẹranko tó ńrágó, ti wọn ńsin ninú ilé, to ńpa eku kiri.  Idi èyi ni Yorùbá fi npa ni òwe pé “Ìjayà ló bá ọmọ Ẹkùn ti ó di Ológbò ti ó ńṣe ọde eku inú ilé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-03-29 10:45:48. Republished by Blog Post Promoter

Ìtán ti a fẹ́ kà loni dá lóri Bàbá tó kó gbogbo Ẹrù fún Ẹrú – The story of the day is about a father who bequeathed all his inheritance to his Chief Slave

Share Button

Originally posted 2017-12-06 00:23:08. Republished by Blog Post Promoter

“Ìtàn Ìjà laarin Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Asin – Ìgbẹ̀hìn Ìjà fún Asin àti òfófó fún Ìjàpá kò bímọ ire” – “The fight between the Squirrel and the Rat (with a long mouth) and the Consequence of Gossiping for the Tortoise”.

Ni ayé igbà kan ri, àwọn ẹranko ni ọjà ti wọn.  Ni ọjọ́ ọjà, Kìnìún, Ajá, Ìgalà, Ikõkò, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Erin, Ẹkùn,  Ìjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku gbé irè oko àti ẹrù fún títà wá si ọjà.  Erin ni Olóri ọjà, Kìnìún ni igbá keji.  Gbogbo ẹranko mọ àlébù ara wọn.  Wọn mọ̀ pé Asin fẹ́ràn ijà, bẹni òfófó àti àtojúbọ̀ ni àlébù Ìjàpá.

Àjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku - Tortoise and other animals.

Àjàpá, Ọ̀kẹ́rẹ́, Eku-Asin, àti àwọn ẹranko yoku – Tortoise and other animals.

Ni ọjọ́ kan, ijà bẹ́ silẹ̀ laarin Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Asin.  Ki ṣe pé àwọn ẹranko yoku kò lè làjà yi, ṣùgbọ́n wọn rò pé Asin ti tún gbé iṣe rẹ̀ dé nitori ó fẹ́ràn ijà, nitori eyi, wọn kò dá si ijà.  Ìjàpá fi ìsọ̀ rẹ̀ silẹ̀, ó sá lọ wòran ijà.  Nigbati ó dé ibi ijà, ó rò pé Asin lágbára ju Ọ̀kẹ́rẹ́ lọ, ó kó si wọn laarin.  Eku-Asin kò fẹ́ràn Ìjàpá nitori ki gbọ tara ẹ, nitori eyi, inú bi i, ó fi Ọ̀kẹ́rẹ́ silẹ̀, ó kọjú ijà si Ìjàpá.  Ó fi ibinú gé imú Ìjàpá jẹ.  Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ si ké igbe pẹ̀lú orin yi nitoÌri ki àwọn ẹranko yoku lè gba ohun lọwọ Asin:

Asín tòhun Ọ̀kẹ́rẹ́ —————– jo mi jo
Àwọn ló jọ njà ———————- jo mi jo
Ìjà ré mo wá là ———————-jo mi jo
Asín wá fi mí ni mú jẹ ———— jo mi jo
Ẹ gbà mí lọwọ́ rẹ̀ —————— jo mi jo
Àwò mí mbẹ lọ́jà ——————-jo mi jo

Àwọn ẹranko yoku kọ̀ lati gba Ìjàpá lọwọ Asin, dipò ki wọn làjà gẹ́gẹ́ bi orin arò Ìjàpá, yẹ̀yẹ́ ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe, pé Ìjàpá ri ẹ̀san òfófó.  Nigbati Ìjàpá ri pé àwọn ẹranko yoku kò ṣetán lati gba ohun, ó lo ọgbọ́n inú rẹ̀ lati tu ara rẹ̀ silẹ̀.  Ó fa imú rẹ àti ẹnu Asin wọ inú ikarawun rẹ, ó pa ikarawun dé mọ ẹnu Ọ̀kẹ́rẹ́.  Asin bẹ̀rẹ̀ si jà pàtàpàtà lati tú ẹnu rẹ̀ silẹ̀. Bi ó ti dura bẹni ẹnu rẹ̀ gùn si titi ó fi já.  Ìjà yi ló sọ Asin di ẹlẹ́nu gígùn, ti ó sọ  Ìjàpá di onímú kékeré titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé kò si èrè rere ninú ijà tàbi iwà òfófó nitori igbẹhin àlébù wọnyi ki i dára.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-01 06:30:37. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn ti a o kà loni dá lórí ìdí ti ọmọ Ẹkùn fi di Ológbò – The Yoruba story being read is on “how a Tiger Cub became a Cat”

Yorùbá ma npa ìtàn lati fi ṣe à ri kọ́gbọ́n tàbi fún ìkìlọ̀.  Ẹ ṣọ́ra lati fi ìbẹ̀rù àti ojo bẹ̀rẹ̀ ọdún nitori a ma a géni kúrú. Lára ẹ̀kọ́ ti a lè ri fi kọ́ ọgbọ́n ni ìtàn ti a ka yi ni wi pé, onikálukú ni Ọlọrun fún ni ẹ̀bùn àti àyè ti rẹ̀ ni ayé.  Ohun ti ó dára ni ìṣọ̀kan, ẹ̀kọ́ wa lati kọ́ lára bi ẹranko ti ó ni agbára ṣe mba ara wọ́n gbé, ó dára ki a gba ìkìlọ̀ àgbà tàbi ẹni ti ó bá ṣe nkan ṣáájú àti pé ìjayà tàbi ìbẹ̀rù lè gé ènìà kúrú bi o ti sọ ọmọ Ẹkùn di Ológbò.

Ẹ ka ìtàn yi ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ojú ewé Yorùbá lóri ayélujára ti a kọ ni ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún, oṣù kẹta, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n.

ENGLISH TRANSLATION

In Yoruba Culture stories are told to learn from example or to warn.  Be careful on stepping into the New Year with fear, because fear reduces one’s potential.  Some of the lessons that can be Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-01-19 00:47:17. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá rẹ Erin sílẹ̀ – “Ìjàlọ ò lè jà, ó lè bọ́ ṣòkòtò ni idi òmìrán”: The Tortoise humbled the Elephant – “Soldier ant cannot fight, but can cause the giant to remove pant”.

Erin jẹ ẹranko ti Ọlọrun da lọ́lá pẹlu titobi rẹ ninu igbo.  Yorùbá ni “Koríko ti Erin bá ti tẹ̀, àtẹ̀gbé ni láyé”, oko ti Erin bá wọ̀, olóko bẹ wọ igbèsè tori ibajẹ ti o ma ṣẹlẹ̀ si irú oko bẹ.  Gbogbo ẹranko bọ̀wọ̀ fún Erin, nitori Kìnìún ọlọ́là ijù kò lè pa Erin.

Bi Erin ti tóbi tó, ni ó gọ̀ tó.  Ni ọjọ́ kan, gbogbo ẹranko pe ìpàdé lati pari ìjà fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Kìnìún.  Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni bi ohun ba pa ẹran, Kìnìún a fi ògbójú gba ẹran yi jẹ.  Kàkà ki Erin da ẹjọ́ pẹ̀lú òye, ṣe ló tún dá kun.  Ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga ni àwùjọ yi bi awọn ẹranko yoku ninu.  O bi Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ninu to bẹ gẹ ti kò lè fọhùn.  Àjàpá nikan lo dide lati fún Erin ni èsì ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹranko yoku bú si ẹ̀rín nitori wọn fi ojú di Àjàpá.  Dipo ki Àjàpá panumọ́, ó pe erin níjà.

Ni ọjọ́ ìjà, Erin kò múra nitori ó mọ̀ pé bi Àjàpá ti kéré tó, bi ohun bá gbé ẹsẹ̀ le, ọ̀run lèrọ̀. Àjàpa mọ̀ pé ohun ko ni agbára, nitori eyi, ó dá ọgbọ́n ti yio fi bá Erin jà lai di èrò ọ̀run.  Àjàpá ti pèsè, agbè mẹta pẹlu ìgbẹ́, osùn àti ẹfun ti yio dà lé Erin lóri lati dójú ti.  Ó tọ́jú awọn agbè yi si ori igi nitosi ibi  ti wọn ti fẹ́ jà, ó mọ̀ pé pẹ̀lú ibinu erin á jà dé idi ibi ti yio dà le lori.

Awọn ẹranko péjọ lati wòran ijà lãrin Àjàpá àti Erin.  Àjàpá mọ̀ pe bi erin bá subú kò lè dide, nigbati ti ijà bẹ̀rẹ̀, ẹhin ni Àjàpá wà ti o ti nsọ òkò ọ̀rọ̀ si erin lati dá inú bi.  Pẹ̀lú ibinú, ki ó tó yípadà dé ibi ti Àjàpá wa, Àjàpá a ti kósi lábẹ́, eleyi dá awọn ẹranko lára yá.

Yorùbá ni “Bi ìyà nla ba gbeni ṣánlẹ̀, kékeré á gorí ẹni” ni ikẹhin, Àjàpá bori erin pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ẹranko gbé Àjàpá sókè pẹ̀lú ìdùnnú gun ori ibi ti erin wó si.

Ìtàn Yorùbá yi fihan pé kò si ẹni ti a lè fi ojú di.  Ti a bá fẹ́ ka ìtàn yi ni ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni èdè Gẹẹsi, ẹ ṣe àyẹ̀wò rẹ ninu iwé “Yoruba Trickster Tales” ti Oyekan Owomoyela kọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-25 17:02:09. Republished by Blog Post Promoter

“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.  Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.  Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter

“Olúróhunbí jẹ́ ẹ̀jẹ́ ohun ti kò lè san”: “Olurohunbi made a vow/covenant she could not keep”

Yorùbá ka ọmọ bibi si ohun pàtàki fún ìdílé, nitori èyi, tijó tayọ̀ ni Yorùbá ma fi nki ọmọ titun káàbọ̀ si ayé.  Gẹ́gẹ́bí Ọ̀gá ninu Olórin ilẹ̀-aláwọ̀ dúdú, Olóyè Ebenezer Obey ti kọ́ “Ẹ̀bùn pàtàki ni ọmọ bibi…”.  Ìlú ti igbe ọmọ titun kò bá dún, ìlú naa ́a kan gógó.  Eleyi lo ṣẹlẹ̀ ni ìlú Olúróhunbí.

Fún ìgbà pípẹ́, àwọn obinrin ìlú kò ri ọmọ bi, nitorina, gbogbo wọn lọ si ọ̀dọ̀ Òrìṣà Ìrókò lati lọ tọrọ ọmọ.  Oníkálukú wọn jẹjẹ oriṣiriṣi ohun ti wọn ma fún Ìrókò ti wọ́n bá lè ri ọmọ bi.  Ẹlòmiràn jẹ ẹ̀jẹ́ Ewúrẹ́, òmíràn Àgùntàn tàbi ohun ọ̀gbìn.  Yorùbá ni “Ẹyin lohùn, bi ó bá balẹ̀ ko ṣẽ ko”, kàkà ki Olurohunbi, ìyàwó Gbẹ́nàgbẹ́nà, jẹ ẹ̀jẹ́ ohun ọ̀sìn tàbi ohun àtọwọ́dá, o jẹ ẹ̀jẹ́ lọ́dọ̀ Ìrókò pé ti ohun bá lè bi ọmọ, ohun yio fún Ìrókò lọ́mọ naa.

Lai pẹ́, àwọn obinrin ìlú bẹ̀rẹ̀ si bimọ.  Oníkálukú pada si ọ̀dọ̀ Ìrókò lati lọ san ẹ̀jẹ́ wọn, ṣùgbọ́n Olúróhunbí kò jẹ́ mú ọmọ rẹ̀ silẹ lati san ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́. 

Òwe Yorùbá ni  “Bi ojú bá sé  ojú, ki ohun má yẹ̀ ohun”, ṣùgbọ́n

Ọmọ titun – a baby
Ọmọ titun – a baby Courtesy: @theyorubablog

 Olúróhunbí ti gbàgbé ẹ̀jẹ́ ti ó jẹ́. 

Ni ọjọ́ kan, Olúróhunbí dágbére fún ọkọ rẹ̀ pé ohun fẹ́ lọ si oko ẹgàn/igbó, ó bá gba abẹ́ igi Ìrókò kọjá.  Bi ó ti dé abẹ́ igi Ìrókò, Ìrókò gbamú, ó bá sọ di ẹyẹ.  Ẹyẹ Olúróhunbí bẹ̀rẹ̀ si kọ orin lóri igi Ìrókò bayi:

 

Oníkálukú jẹ̀jẹ́ Ewúrẹ́, Ewúrẹ́
Ònìkàlùkú jẹjẹ Àgùntàn, Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀
Olúróhunbí jẹ̀jẹ́ ọmọ rẹ̀, ọmọ rẹ̀ a pọ́n bí epo,
Olúróhunbí o, jain jain, Ìrókó jaini (2ce)

Nigbati, ọkọ Olúróhunbí reti iyàwó rẹ titi, ó bá pe ẹbi àti ará lati wa.  Wọn wa Olúróhunbí titi, wọn kò ri, ṣùgbọ́n nigbati ọkọ rẹ̀ kọjá lábẹ́ igi Ìrókò to gbọ́ orin ti ẹyẹ yi kọ, ó mọ̀ pe ìyàwó ohun ló ti di ẹyẹ.

Gẹgẹbi iṣẹ́ rẹ (Gbénàgbénà), ó gbẹ́ èrè bi ọmọ, ó múrá fún, ó gbe lọ si abẹ́ igi Ìrókò.  Òrìṣà inú igi Ìrókò, ri ère ọmọ yi, o gbã, ó sọ Olúróhunbí padà si ènìà.

Ìtàn yi kọ́ wa pé: igbèsè ni ẹ̀jẹ́, ti a bá dá ẹ̀jẹ́, ki á gbìyànjú lati san; ki a má da ẹ̀jẹ́ ti a kò lè san àti ki á jẹ́ ki ọ̀rọ̀ wa jẹ ọ̀rọ̀ wa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-27 09:20:46. Republished by Blog Post Promoter

“Ìtàn bi Ìjàpá ti fa Àkóbá fún Ọ̀bọ: Ẹ Ṣọ́ra fún Ọ̀rẹ́ Burúkú” – “The Story of how the Tortoise caused the Monkey an unprovoked trouble: Be careful with a bad Friend”

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé.

Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, “Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́”, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra.  Ìjàpá  pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nitori wọn jọ ngbé àdúgbò.  Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nitori eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe.

Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé “Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri”, Ọ̀bọ kò ṣe “Àmin àdúrà” nitori ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn.  Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.

Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ.  Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa.  Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ. Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ.  Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn.  Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun.  Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá.  Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi.  Ẹkùn gbàgbọ́, nitori ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ - Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ – Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun.  Gẹ́rẹ́ ti Ọ̀bọ sún mọ́ Ẹkùn, o fã lati gba ikùn rẹ gẹ́gẹ́ bi Ìjàpá ti sọ, ki ó lè ṣu di dùn fún òhun.  Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀.  Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji.  Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ.  Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun.  Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe “Amin”, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.  Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe “Àmin” lai dúró.  Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi “Àmin” titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó mã funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-16 22:39:59. Republished by Blog Post Promoter