Category Archives: Yoruba Culture

Iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́ – Hard-work is a cure for poverty

Ẹ ṣe àyẹ̀wò ìwé akéwì-orin ni èdè Yorùbá ti àwọn ọmọ ilé-ìwé n kọ́ sórí ni ilé-ìwé ilẹ̀ Yorùbá ni ayé àtijọ:

Iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, múra si iṣẹ́ rẹ ọ̀rẹ́ mi, iṣẹ́ ni a fi i di ẹni gíga
Bí a kò bá rẹ́ni fẹ̀hìn tì, bí ọ̀lẹ là á rí
Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé, à á tẹra mọ iṣẹ́ ẹni
Ìyá rẹ lè lówó lọ́wọ́, Bàbá si lè lẹ́ṣin leekan
Bí o bá́ gbójú lé wọn, o tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ
Ohun ti a kò bá jìyà fún kì í lè tọ́jọ́
Ohun ti á fara ṣiṣẹ́ fún ní í pẹ́ lọ́wọ́ ẹni
Apá lará, ìgunpá niyèkan
Bí ayé n fẹ́ ọ loni, bí o bá lówó lọ́wọ́, ni wọn má a fẹ́ ọ lọla
Tàbí tí o bá wà ní ipò àtàtà, ayé a yẹ́ ọ sí tẹ̀rín-tẹ̀rín
Jẹ́ kí o di ẹni n rágó, kí o ri bí ayé ti n yínmú sí ọ
Ẹ̀kọ́ sì tún n sọni dọ̀gá, mú́ra kí o kọ dáradára
Bí o sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí wọn fi ẹ̀kọ́ ṣe ẹ̀rín rín
Dákun má ṣe fara wé wọn
Ìyà n bọ̀ fọ́mọ tí kò gbọ́n, ẹkún n bẹ fọ́mọ tó n sá kiri
Má fòwúrọ̀ ṣeré, ọ̀rẹ́ mi, múra sí iṣẹ́ ọjọ́ n lọ

ENGLISH TRANSLATION

Work is the antidote for poverty, work hard, my friend
Attaining higher height is largely dependent on hard work
If there is no one to depend on, we simply work harder
Your mother may be wealthy, your father may have a ranch of horses
If you depend on their wealth, you may end up in disgrace, I tell you
Gains not earned through hard work, may not last
Whatever is earned through hard work, often last in one’s hand
The arm is a relative, the elbow remain a sibling
The world may love you today, it is only when you are relevant that you will be loved tomorrow
Or when you are in a position of authority, the world will honour you with cheers
Wait till you are poor and you will see how all will grimace at you
Education do contribute to making one relevant, ensure you acquire solid education
And if you see people mocking education,
Please do not emulate them
Suffering is lying in wait for irresponsible children, sorrow lies ahead for truants
Do not waste your early years, my friend, work harder, time waits for no one.

 

Share Button

Originally posted 2017-01-17 12:00:35. Republished by Blog Post Promoter

Obinrin kò ṣe e jánípò si ìdí Àdìrò nikan, Obinrin ló ni gbogbo Ilé – Women cannot be relegated to the kitchen, women are in charge of the entire home

Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá  bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri.  Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára.  Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’.  Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ.

Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe.  Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí).  Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’.  Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin.

Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó  wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé.   Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó  kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin.  Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-10-25 21:42:34. Republished by Blog Post Promoter

Òjò nrọ̀ si kòtò, gegele mbinú – The rain is filling up the gully to the annoyance of the hill

Ójò rẹpẹtẹ – Heavy rain

Ójò rẹpẹtẹ – Heavy rain

Bi inú ọpọ ti ndùn, ni inú ẹlòmíràn mbàjẹ́ ni àsikò òjò.  Yorùbá ni orin fún igbà ti kò ba si òjò, igbà ti òjò bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si rọ̀, tàbi ti ó bá nrọ̀ lọ́wọ́ àti bi òjò bá pọ̀jù.  Ẹ gbọ́ àwọn orin wọnyi pàtàki bi àwọn ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ti nkọ orin òjò.

Ọmọdé nṣeré ninú òjò – Children playing in the rain

Ọmọdé nṣeré ninú òjò – Children playing in the rain

 

ENGLISH TRANSLATION

As many are happy, so are many sad during the raining season.  Yoruba has various songs to depict, requesting for rain, or when the rain has just begun, or when the rain is affecting outdoor activities particularly for children or when the rain is too much.  Listen to some of the songs for the rain that Primary School children often sing.

Òjò rọ̀ ki ilẹ̀ tutù
Ọlọrun eji ò

Òjò má a rọ̀, òjò má a rọ̀
Ìtura lo jẹ́,
Òjò má a rọ̀, òjò má a rọ̀
Ìtura lo jẹ́.

 

Òjò nrọ̀ ṣeré ninú ilé
Má wọnú òjò
Ki aṣọ rẹ̀ má bà tutù
Ki òtútù má bà mú ẹ

Ójò dá kúrò́
Pada wá lọjọ́ míràn
Ọmọ kekere fẹ́ ṣèré

 

 

 

 

 

 

Share Button

Originally posted 2015-02-17 19:37:00. Republished by Blog Post Promoter

“Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra” – “The sky is wide enough for the birds to fly without bumping into each other”

Ẹ̀sìn ti wa láyé, ki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi tó dé.  Fún àpẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ ninú “Ọlọrun” ti Yorùbá mọ̀ si “Òrìṣà-òkè” tàbi “Eledumare”.  Bi Yorùbá ṣe ḿbá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ni ayé àtijọ́ ni ó yàtọ̀ si ti àwọn ẹlẹ́sìn igbàlódé.

Yorùbá ńlo “Ifá” lati ṣe iwadi lọ́dọ̀ “Ọlọrun”, ohun ti ó bá rú wọn lójú.  Yorùbá ma ńlo àwọn “Òrìṣà”  bi “Ògún”, “Olókun”, “Yemọja”, “Ọya”, “Ṣàngó” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “Onílàjà” larin èniyàn àti Eledumare.

Yorùbá ni “Ẹlẹkọ ò ni ki Alákàrà má tà”.  Ẹ̀sìn ti fa ijà ri, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, àti ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Onigbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ló ńṣe ẹ̀sìn wọn lai di ẹnikeji lọwọ.  Ni òkè-òkun, ẹni ti ó ni ẹ̀sìn àti ẹni ti kò ṣe ẹ̀sìn kankan ló ńṣe ti wọn lai di ara wọn lọ́wọ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán yi: Mùsùlùmi àti Onígbàgbọ́ ńṣe ìwàásu lẹgbẹ ara wọn.

Ó ṣe pàtàki ki ẹ ma jẹ ki àwọn Òṣèlú tàbi alai-mọ̀kan lo ẹ̀sìn lati fa ijà tàbi ogun, nitori “Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-05 13:05:43. Republished by Blog Post Promoter

Ìkini Ọdún Ẹgbàálélógún – 2020 Yoruba Season Greetings

Share Button

Originally posted 2020-01-02 02:46:36. Republished by Blog Post Promoter

Ìgbéyàwó Ìbílẹ́ Yorùbá: “Ọ̀gá Méji Kò Lè Gbé inú Ọkọ̀” – Yoruba Traditional Marriage Ceremony: “Two Masters cannot steer a ship”

Adarí Ètò Ijoko àti “Adarí Ètò Ìdúró – Traditional Master of Ceremony.  Courtesy: @theyorubablog

Adarí Ètò Ijoko àti “Adarí Ètò Ìdúró – Traditional Master of Ceremony. Courtesy: @theyorubablog

A ṣe àkíyèsí pé wn ti s iṣẹ́ ìyàwó-ilé di òwò nibi ìgbéyàwó ìbíl̀̀̀̀̀̀ẹ̀, pàtàki ni àwn ilú nlá, nítorí èyí “ó ju alaga méjì tó ngbe inú ọkọ̀ bẹ .  Wọn pè ìkan ni “Alaga Ìdúró” wọn pe ìkejì ni “Alaga Ijoko”.  Gẹgẹbi àṣà ilẹ Yorùbá, kòsí bí “Ìyàwó ilé ti lè jẹ “Alaga” lórí ẹbí ọkọ tàbí ẹbí ìyàwó ti a ngbe.  Ọkunrin ti o ti ṣe ìyàwó ti o yọri fún ọpọlọpọ ọdún, ti o si gbayí láwùjọ, yálà ni ìdílé ìyàwó tàbí ìdílé ọkọ ni a nfi si ipò “ALAGA” tàbí “OLÓRÍ ÀPÈJỌ.

Ìyàwó àgbà ni ìdílé ọkọ àti ti ìyàwó ni o ma nṣe aṣájú fún áwọn ìyàwó ilé yoku lati gbé tàbí gba igbá ìyàwó ni ibi ìgbéyàwó ìbílẹ.  Ni ayé òde oni, a ṣe àkíyèsí wipé, ìdílé ìyàwó àti ọkọ, a san owó rẹpẹtẹ lati gba àwọn ti o yẹ ki a pè ni “Adarí Ètò Ijoko” fún bi Ìyàwó àti “Adarí Ètò Ìdúró” fún bi Ọkọ-ìyàwó”.  Lẹhin ti àwọn obìnrin àjòjì yi ti gba owó iṣẹ́, wọn a sọ ara wọn di “Ọ̀GÁ”, wọn a ma pàṣe, wọn a ma ṣe bí ó ti wù wọn lati tún rí owó gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí mejeeji.  Nípa ìwà yí, wọn a ma fi àkókò ṣòfò.  Yorùbá ni “Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọ́n”.

“Ṣe bí wọn ti nṣe, ki o ba le ri bi o ṣe nri”,   o yẹ ki  á ti ọẃọ àṣàkasà yi  bọlẹ̀.  Ko ba àṣà mu lati sọ “Aṣojú awọn ìyàwó-Ilé” di “ALAGA”.  Ipò méjèjì yàtọ sira, ó dẹ y ki o dúró bẹ nítorí ọ̀gá méjì kò lè gbé inú ọkọ̀ kan.

ENGLISH TRANSLATION

It can easily be observed that Traditional marriages have turned largely commercial in nature and as a result of this there are more than two captains in such a ship.  One is called “SEATING IN CHAIRMAN” while the second is called “STANDING IN CHAIRMAN”.  In Yoruba culture, “a Housewife” cannot be made the CHAIRMAN over her husband’s family in either the Bride or the Groom’s Family.  The Chairman in the Traditional Marriage is often an honourable man with many years of married life, carefully chosen from either the Bride or Groom’s family. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-24 23:25:22. Republished by Blog Post Promoter

Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà – Contentment is the Father of Character

Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló bí gbogbo ìwà burúkú bi:  irọ́ pípa, olè jíjà, àgbèrè, ojúkòkòrò àti bẹ̃bẹ lọ.

Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló wà ni ìdí àwọn Oṣèlú àti Olórí Ìjọ ti o nlo owó ìlú tàbi owó ìjọ fún ara wọn dipò ki wọn lõ fún ìlú àti ìjọ.   Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú̀ ilẹ̀ Nigeria á fi ọ̀nà ẹ̀rú wá ipò nítorí àti kó owó ìlú jẹ, wọn ki wúlò fún ìlú ṣùgbọ́n fún ara wọn.  Èyí tó ṣeni lãnu jù ni wípé kò sí owó ti wọn ji tí ó tó, nítorí wípé wọn a ji owó àti ohun ti wọn kò ní lò títí di ọjọ́ ikú àti kó èyí tí wọ́n rò wípé ọmọ wọn kò ní ná tán.

Ibi tí àìní ìtẹ́lọ́rùn burú dé ni orílẹ̀ èdè wa, o ràn àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olórí Ìjọ tí ó yẹ ki o wãsu èrè ìtẹ́lọ́rùn fún àwọn Òṣèlú, ará ìlú àti ọmọ Ìjọ.  Ó ṣeni lãnu wípé ojúkòkòrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olórí Ìjọ ju ti Òṣèlú, ọmọ Ìjọ àti àwọn ẹlẹ́tàn lọ nítorí wọ́n du ipò àti ohun ayé.

Il̀ú á dára si ti àwọn ènia bá lè mú òwe Yorùbá tí ó wípé “Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà” yí lò.

ENGLISH TRANSLATION

Lack of contentment is the root cause of bad character like: lying, prostitution, covetousness etc.

Lack of contentment is behind the source of Politicians and Church Leaders embezzling public fund and congregation’s tithes and offering for their own personal use.  Many Nigerian Politicians would use every crooked means to be elected to any position in politics in order to be in a position to have access to public fund and afterward, they are often useless to their electorate but for themselves.  The most pitiable thing is that they steal the money and things they will never need to their dying day as well as storing up what they think their children would never be able to finish.

The worst side of lack of contentment in our country, there is no difference between the Church Leaders who are supposed to be preaching about the reward of contentment to the Politicians, the people and fraudsters.  It is unfortunate that many Church Leaders are more covetous than Politicians, Church Congregants and Fraudsters, as a result of competing for position and mundane things.

The Country will be better off if the Yoruba adage that said “Contentment is the Father of Character” can be applied.

Share Button

Originally posted 2013-06-25 19:40:35. Republished by Blog Post Promoter

“Bi a bá tori ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere” – “If one goes blind to avoid bad people, one would miss the opportunity of seeing the good ones”: Danger of Stereotype or Racial Profiling

Kò si ilú, ẹ̀yà tàbi àwọ̀ ti kò ni ẹni burúkú tàbi ẹni rere.  Àti ẹni burúkú àti ẹni rere ló wà ninú ẹbi, ilú, àti gbogbo ẹ̀yà àgbáyé ninú èniyàn dúdú àti funfun, ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti àgbà.

Bi èniyàn bá pàdé ẹni kan tàbi meji ni àkọ́kọ́, ti ó ti ẹ̀yà tàbi ilú kan jade, ti ó si hùwà rere, ni ọ̀pọ̀ igbà, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ará ilú bẹ́ ẹ̀ ló dára, ni ida keji, ti irú ẹni bẹ́ ẹ̀ ba hùwà burúkú, ó wọ́pọ̀ lati rò wi pé gbogbo ẹni ti ó ti irú ẹ̀yà yi jade ni ẹni burúkú.

Bi a bá tori ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere - Racial Profiling. Courtesy: @theyorubablog

Courtesy: @theyorubablog

Ọ̀pọ̀ igbà, lai pàdé enia ri, ẹlòmiràn lè ni lọ́kàn pe ẹni burúkú tàbi ẹni rere ni ohun pàdé nitori itàn ti ó ti gbọ́.  Itàn yi lè nipá lóri irú iwà ti èniyàn yio hu si ẹni ti a bá pàdé.  Fún àpẹrẹ, wọn a ni Ìjẹ̀bú fẹ́ràn owó ju ẹmi lọ, Ondó njẹ Ajá, Ọ̀yọ́ ‘ayọ́mọọ́lẹ̀’’, Èkìtì ni agidi, Ìjẹ̀shà – Òṣómàáló’ àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Ki ṣe gbogbo àwọn ará ilú wọnyi ló bá àpèjúwe yi mu.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fọ́jú nitori iwà burúkú ẹni kan tàbi itàn burúkú.  Ó wọ́pọ̀ laarin ẹbi ọkùnrin àti obinrin àfẹ́sọ́nà, ki obi kọ̀ ki wọn fẹ́ra nitori itàn pé idilé tàbi ilú ti ikan ninú ọkùnrin tàbi obinrin ti jade kò dára.  Lára ewu ti ó wà ninú ki èniyàn tori ẹni burúkú fọ́jú, ọ̀pọ̀ ti tàsé iyàwó tàbi ọkọ rere lai farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti ọmọ wọn mú wálé tàbi tàsé ẹni rere.  Nitori òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Bi a bá tori Ẹni burúkú fọ́jú, a kò ni ri ojú ri ẹni rere”, ó yẹ ki a farabalẹ̀ wo iwà ẹni ti a bá pàdé ju ki itàn tàbi iwà awọn diẹ ba gbogbo ẹni ti ó bá ti ẹbi, ilú tàbi ẹ̀yà kan jẹ́, ki á lè ri ojú ri ẹni rere.

ENGLISH TRANSLATION

There is no ethnic group or race without the bad and the good people.  Both the bad and good people exist in a family, towns and in all the nations of the world, either black or white, male, female, young and old.

At first meeting, if a person meets one or two people from the same ethnicity or town that behaved well, most times, it is common to assume that people from such places are good, on the other hand, if such person should behave wickedly, it is also common to think that people from their ethnicity are all bad.

Most times, without prior meeting, some are biased in determining whether the person is good or bad as a result of stories heard.  The story could influence the kind of character displayed at reception.  For example there are stereotype that Ijebu people value money than life, Ondo people love eating dogs, Oyo people are sneaky, Ekiti are very stubborn, Ijesha would not give their debtors breathing space etc.

Many have literarily gone blind because of one or two bad people or bad stories.  It is common for a marriage proposal to be rejected by the would-be bride or groom’s parents as a result of stories that either the family or people from such ethnic group are bad.  Part of the danger of profiling a group or going blind to avoid bad people, has caused many to miss a good wife or husband as a result of not being patient to study the character of the person involved.  As a result of the Yoruba proverb that said “If one goes blind to avoid bad people, one would miss the opportunity of seeing the good ones”, it is important to patiently observe the character of anyone met rather than relying on preconceived stereotype or bad action of few to judge a family, town or race, in order to notice the good ones.

Share Button

Originally posted 2015-11-03 21:19:40. Republished by Blog Post Promoter

“Ọgbọ́n àrékérekè sọ ìràwé inú aginjù di ilé fún Àjàpá” – Pípé là á pé gbọ́n, a ki pé gọ̀ – “Double dealing led to Tortoise homelessness” – We form complete association for wisdom, not for foolishness.

Ni ayé igbà kan, ọ̀gbẹlẹ̀ wa ni ilú àwọn ẹranko, nitori ọ̀dá òjò fún igbà pi pẹ́.  Ọ̀gbẹlẹ̀ yi fa ìyàn, wọn kò ri omi mu tàbi wẹ̀.  Eleyi mú ki gbogbo ẹranko (Kìnìún, Ẹkùn, Erin, Ẹfọ̀n, Àgbọ̀nrín, Òkété, Ehoro, Ọ̀kẹ́rẹ́, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Àjàpá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ) pé jọ lati kó ọgbọ́n pọ̀ bi àwọn yi o ṣe ri omi.  Wọn yan Kìnìún ni Alaga, Ẹkùn jẹ́ igbá keji, Erin jẹ́ Baálẹ̀.

Gbogbo ẹranko pé jọ - Complete gathering of animals

Gbogbo ẹranko pé jọ – Complete gathering of animals

Yorùbá sọ pé “A sọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú”, Àjàpá binú kúrò ni ìpàdé nitori wọn kò yan ohun si ipò Alaga.  Àwọn ẹranko yoku mba ìpàdé lọ, oníkálùkù mú ìmọ̀ràn wá, Àgbọ̀nrín ni ki wọn ṣe ètùtù si Òriṣà-Omi, Òkété ni ki wọn lo ọgbọ́n àti agbára ti Ọlọrun fún wọn, lati gbẹ́ ilẹ̀ jínjìn si ojú odò ti ó ti gbẹ.  Lẹhin àpérò, wọn gba ìmọ̀ràn ti Òkété múwá, wọn gbẹ́ ojú odò titi wọn fi ri omi.

Bi iroyin pé wọn ti ri omi ti kàn, Àjàpá ti kò bá wọn ṣiṣẹ́ nitori ibinú, o gbìmọ̀ bi ohun yi o ti ṣe ẹ̀rù ba àwọn ẹranko yoku ni idi odò, ki ohun lè ri àyè dá pọn omi.  Ó sọ ara rẹ di Ànjọ̀nú, ó so agbè púpọ̀ pẹ̀lú okùn ti yio fi pọn omi mọ́ gbogbo ara, ó ji lọ idi odò lati dá nikan pọn omi. Ó bẹ̀rẹ̀ si kọrin:

Bi mba bérin lódò ma tẹ ẹ …… Kàndú
Bi mo bẹ́fọ̀n lódò ma tẹ ẹ ……. Kàndú
Kan, kan, kan, kàndú Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-12 10:53:56. Republished by Blog Post Promoter

“Òjò tó rọ̀ ló mú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ wá”: Ìgbà Òjò dé – “It is the rain that fell that brought about much mud”: The Raining Season is here

Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ Òjò – Much Mud

Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ Òjò – Much Mud

“Òjò ibùkún lọ́dọ̀ ẹni kan, ni òjò ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ ẹlòmíràn”.  Lai si òjò, ọ̀gbẹlẹ̀ á wà, ọ̀gbẹlẹ̀ pi pẹ́ ló nfa iyàn.  Inú àgbẹ̀ ma ndun ni àsikò òjò nitori wọn mọ̀ pé ohun ọgbin wọn yio hù, oúnjẹ àti jẹ, àti tà yio pọ̀ si.  Ọmọdé àti àgbà ló fẹ́ràn òjò nitori ó mú ìtura wá, pàtàki ni igbà ooru.

Ni idà keji, òjò àrọ̀-irọ̀ dá lè fa ìbànújẹ́ fún àgbẹ̀ àti ará ilú, pàtàki fún; ẹni ti ilé rẹ njò, ẹni ti ó kọ́lé si ọ̀nà àgbàrá òjò, ó nfá ẹ̀fọn/yànmùyánmú eyi ti ó nfá ibà, àgbàrá lè gbá ohun ọ̀gbìn lọ, agbara lè yalé àti bẹ ́ẹ̀  bẹ́ ẹ̀ lọ.   Fún àpẹrẹ, irònú àti ibànújẹ́ ni ìgbà òjò jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ilú Èkó, nitori ọ̀nà fún àgbàrá kò tó, eyi ma njẹ ki àgbàrá ba ilé àti ọ̀nà jẹ́.  Ni Ibadan, irònú na a dé fún àwọn ti ó kọ́lé si ẹ̀gbẹ́ odò Ògùnpa nitori ìbẹ̀rù omi-yalé.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Òjò kò bẹni kan ṣọ̀tá, ẹni eji ri leji npa”. ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbà, òjò kò rọ̀ fún ìbànújẹ́ èniyàn pàtàki bi èniyàn bá palẹ̀mọ́ fún òjò nipa ti tú àyíká ṣe lai kó pàntí si ọ̀nà àti ojú àgbàrá àti gbi gbẹ́ ọ̀nà fún àgbàrá.   Òwe Yorùbá sọ wipé “Òjò tó rọ̀ ló mú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ wá”.  Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dára fún ohun ọ̀gbin bi ìrẹsì àti fún agbo Ẹlẹ́dẹ̀ ṣùgbọ́n kò yẹ ilú.  Bi Ìjọba bá ṣe ọ̀na fún ọkọ̀ àti ẹlẹ́sẹ̀, pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ á din kù.  Eyi ti ó ṣe pàtàki ni ki Ìjọba àti ará ilú sowọ́pọ̀ lati tú agbègbè àti àyíká ṣe lati lè lo òjò fún rere.

ENGLISH TRANSLATION

“What some regarded as rain of blessing can be regarded as rain of sorrow for others”.  Without the rain, there will be drought, long time drought leads to famine.  Farmers are happy during raining season because the crops will grow and this would lead to good harvest, plenty of food to eat and to sell.  Children and adults alike love the rain because it eases out the heat. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-09 13:56:48. Republished by Blog Post Promoter