Category Archives: Yoruba Community

Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó: “Before Yam becomes Pounded Yam it is pounded in a mortar”

Gẹ́gẹ́bí Ọba nínú Olórin ti ógbé àṣà àti orin Yorùbá lárugẹ lagbaaye (Ọba orin Sunny Ade) ti kọ wípé: “Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó”, òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ni lati gún iṣu lódó kí ó tó di Iyán, ṣùgbọ́n fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó ní ìfẹ́ oúnje abínibí tí ó wà ni Ìlúọba/Òkèòkun, a ò gún iṣu lódó mọ, a ro lórí iná bí ìgbà ti a ro Èlùbọ́ to di Àmàlà ni.

Ìyàtọ̀ tó wà laarin Èlùbọ́ tó di Àmàlà àti iṣu tó di Iyán tí a rò nínú ìkòkò ni wípé, Àmàlà dúdú, Iyán funfun, ṣùgbọ́n Àmàlà fẹ́lẹ́ ju Iyán lọ.  A ní lati ṣe àlàyé fún àjòjì wípeí ara iṣu ni Èlùbọ́ tó di Àmàlà ti jáde gẹ́gẹ́bi Iyán ti jáde lára Iṣu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-17 09:20:09. Republished by Blog Post Promoter

ÈLÒ ỌBẸ̀ YORÙBÁ: YORUBA SAUCE/STEW/SOUP INGREDIENT

Yorùbá English Yorùbá English
Èlò bẹ̀ Soup/Stew/Stew Ingredients Elo Obe Soup/Stew/Stew Ingredients
Ẹja Fish Ẹyẹlé Pigeon
Ẹja Gbígbẹ Dry Fish Epo pupa Palm Oil
Akàn Crab Òróró Vegetable Oil
Edé pupa Prawns Òróró ẹ̀̀gúsí Melon oil
Edé funfun Crayfish Òróró ẹ̀pà Groundnut Oil
Ẹran Meat Àlùbọ́sà Onion
Ògúfe Ram Meat Iyọ̀ Salt
Ẹran Ẹlẹ́dẹ̀ Pork Meat Irú Locost Beans
Ẹran Mal̃ũ Cow Meat/Beef Àjó Tumeric
Ẹran ìgbẹ́ Bush Meat Ata ilẹ̀ Ginger
Ẹran Ewúrẹ́ Goat Meat Ilá Okra
Ẹran gbígbẹ Dry Meat Efirin Mint leaf
Ṣàkì Tripe Ẹ̀fọ́ Vegetable
Ẹ̀dọ̀ Liver Ẹ̀fọ́ Ewúro Bitterleaf
Pọ̀nmọ́ Cow Skin Ẹ̀fọ́ Tẹ̀tẹ̀ Green
Panla Stockfish Gbúre Spinach
Bọ̀kọ́tọ̀/Ẹsẹ̀ Ẹran Cow leg Ẹ̀gúsí Melon
Ìgbín Snail Atarodo Habanero pepper
Adìyẹ Chicken Tàtàṣé Paprika
Ẹyin Egg Tìmátì Tomatoes
Pẹ́pẹ́yẹ Duck Ewédú Corchorus/Crain Crain
Tòlótòló Turkey Àpọ̀n Dried wild mango seed powder
Awó Guinea-Fowl Osun Mushroom
Share Button

Originally posted 2013-05-01 03:06:44. Republished by Blog Post Promoter

“Ibi ti à ńgbé là ńṣe…” – Ìfi ìdí kalẹ̀ ni Ìlú-Ọba – One should live according to the custom and fashion of the place where one find oneself in…” – Settling down in the United Kingdom

 Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni enia lè ri kọ́ ni irin àjò.  A lè rin irin àjò fún ìgbà díẹ̀ tàbi pípẹ́ lati bẹ ilú nã wò tàbi lati lọ tẹ̀dó si àjò.

wọ ọkọ̀ òfũrufu – Boarding Aeroplane. Courtesy: @theyorubablog

Oriṣiriṣi ọ̀nà ni enia lè gbà dé àjò, ṣùgbọ́n eyi ti ó wọ́pò jù láyé òde òni ni lati wọ ọkọ̀ òfũrufú, bóyá lati lọ kọ́ ẹ̀kọ si, lati ṣe ìbẹ̀wò, lati lọ ṣiṣẹ́ tàbi lati lọ bá ẹbi gbé (fún àpẹrẹ: ìyàwó lọ bá ọkọ, ọkọ lọ bá ìyàwó, ìyá/bàbá lọ bá ọmọ tàbi ọmọ lọ bá bàbá). Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba.

Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nitori eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pataki àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ.  A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù.  Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn.

Òwe Yorùbá ni “Ibi ti a ngbe la nse; bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù”, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe: Ki ka ìwé nipa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára; wiwa ibùgbé; lọ si Ilé-Ìjọ́sìn; Ọjà; Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ̃bẹ lọ.

Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-03 23:45:42. Republished by Blog Post Promoter

Aṣọ nla, Kọ́ lènìyàn nla – Wèrè ti wọ Àṣà Aṣọ Ẹbí: The hood does not make the Monk – the madness of Family Uniform

Àṣà ilẹ̀ Yorùbá títí di àsìkò yi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ma nni iyawo pupọ́ wọn si ma mbi ọmọ púpọ̀, wíwọ irú aṣọ kan naa fun ṣíṣe ma nfi ẹbi han.  Aṣọ ẹbí bẹ̀rẹ̀ nípa ki ọkọ àti ìyàwó dá irú aṣọ kan nigba ìgbéyàwó àti wíwọ irú aṣọ kan naa lẹhin ìgbéyàwó lati fi han wípé wọn ti di ara kan.   Bàbá ma nra aṣọ  irú kan naa fun àwọn ọmọ nítorí ó dín ìnáwó kù láti ra irú aṣọ kan naa fún ọmọ púpọ̀ nípa ríra ìgàn aṣọ ju ríra ni ọ̀pá.   Aṣọ ẹbí tún wa fún ẹbí àti ọmọ oloku, ìyàwó ṣíṣe, ẹgbẹ́ ìlú àti bẹ̃bẹ lọ.

Nígbàtí wèrè ko ti wọ àṣà aṣọ ẹbí, ẹnití o ṣe ìyàwó, ṣe òkú, sọ ọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku ma npe aṣọ ni.  Kò kan dandan ki ènìá ra aṣọ tuntun fún gbogbo ṣíṣe, fún àpẹrẹ, aṣọ funfun ni wọn ma sọ wípé ki àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọ̀ fún òkú ṣíṣe, aṣọ ibilẹ̀ bi aṣọ òfi àti àdìrẹ fún ìgbéyàwó. Ẹbí ìyàwó le sọ wípé ki ẹgbẹ́ wọ aṣọ aláwọ ewé lati ba ohun yọ ayọ ìgbéyàwó, ki ẹbí ọkọ ni ki àwọn ẹgbẹ́ wọ àdìrẹ ti wọn  ti ra tẹ́lẹ̀ fún ìgbéyàwó.

Lati bi ogoji ọdun sẹhin, lẹhin ti ìlú ti bẹ̀rẹ̀ si naa owó epo, àṣejù ti wọ àṣà aṣọ ẹbí rírà.  Àṣà aṣọ ẹbí ti káári ìlú kọjá ile Yorùbá si gbogbo Nigeria.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ a ma jẹ gbèsè nítorí àti ra aṣọ ẹbí, pàtàkì ni Ìlúọba ti àwọn miran ti nṣiṣẹ àṣekú lati kó irú owó bẹẹ si aṣọ ẹbí, àwọn miran á kó owó oúnjẹ àti owó ilé ìwé lórí aṣọ ẹbí.

Ìlú nbajẹ si, kò síná, kò sómi, ìṣẹ́ pọ, aṣọ ẹbí ko le mu ìṣẹ́ kúrò tàbi sọ ẹnití o jẹ gbèsè láti ra aṣọ ẹbí di ènìyàn nla nítorí “Aṣọ nla, kọ lènìyàn nla – Yorùbá ni ilé lóko, ẹ dín wèrè aṣọ ẹbí kù.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba culture up till now, many men are engaged in “Polygamy” with children from many women, so to buy the same clothes is cheaper for the many wives and children for various festivities.  Family uniform are also used during Burial, Wedding, Naming and other ceremonial events.

When family uniform madness has not started, those preparing for burial, marriage and other traditional events normally call “colour code” of dressing or for invitees to wear one of the previous Family Uniforms, rather than buy new clothes for every event. Those days, those preparing for burial would ask families and friends to wear white attire, while the bride’s family could ask friends to wear green while the groom’s family would request for other locally produced fabrics.  Things were moderately done.

It is observed that since the oil boom about forty years ago, there has been a lot of excesses in the so called “Family Uniform” and this culture has spread beyond the Yoruba to other parts of Nigeria. The Nigerian’s abroad are also not excluded in spite of working to death with no time for family lives only to spend such income that could have been spent on education, food and other necessities on such frivolities as “Family Uniform”.

In the midst of decaying infrastructure and poverty, spending so much on “Family Uniform” would not make our nation great.  “The hood does not make the Monk, Yoruba at home and abroad should reduce the madness on “Family Uniform”.

Share Button

Originally posted 2013-05-31 22:53:11. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ Jọ̀wọ́ Darapọ̀ Mọ́ Wa lati kọ nipa Àṣà àti Ìtàn Àdáyébá ni Agbègbè Yin – Please Join The Yoruba Blog to Submit for Publication Your Community Cultural Events and Ancient Folklores

Gbogbo olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá ti ó tẹ̀lé wa ni àwọn ọdún ti ó kọjá, a ki yin fún ọdún tuntun ti ó wọlé.  Èdùmàrè á jẹ́ ki ọdún na a tura o.  Inú wa yio dùn ti ẹ bá lè darapọ̀ mọ́ wa lati kọ nipa àṣà ati itàn àdáyébá ni agbègbè yin ni ilẹ̀ Yorùbá fún àkọọ́lẹ̀ ki èdè àti àṣà Yorùbá ma ba parẹ́.

Èdè àti Àṣà Yorùbá kò ni parẹ́.

ENGLISH TRANSLATION

Season greetings to all the followers of The Yoruba Blog in the years past, congratulations on making it to the New Year.  It will be appreciated if you can team up with us to submit writings on the culture and ancient Folklores peculiar to your community in Yoruba land, in order to preserve Yoruba language and culture by documenting it.

Yoruba Language and Culture will not be obliterated.

Share Button

Originally posted 2016-01-05 10:30:24. Republished by Blog Post Promoter

Ewédú: Botanical Name Cochorus, Craincrain in Sierra Leone

Ewédú jẹ ikan nínú ọbẹ̀ Yorùbá tó wọpọ ni agbègbè Ọ̀yó, Ọ̀sun, Ògùn gẹ́gẹ́bi ilá ti wọ́pọ̀ ni agbègbè Ondo àti Èkìti.

Fún ẹni tó́ nkanju, ilá yára láti sè ju ewédú lọ, nítorí àsìkò lati tọ́ ewédú ati lati fi ìjábẹ̀ ja, pẹ ju rírẹ àti síse ilá lọ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ko ríra pe wọn nfi ìgbálẹ se ọbẹ̀ lai mọ wípé ìjábẹ̀ (ọwọ̀ kukuru tuntun ti o wa fún ewédú) kò wà fún ilẹ̀ gbígbá.  Ni ayé ìgbàlódé yi, dípò ìjábẹ̀, a le lọ ewédú nínú ẹ̀rọ ata ìgbàlode fún bi iṣeju kan, eleyi din àsìkò síse ewédú kù si bi ọgbọn ìṣéjú fún ewédú ọbẹ̀ enia mẹwa.

Ewédú̀ dùn pẹ̀lú gbẹ̀gìrì tàbi ọbẹ̀ ata lati fi jẹ Ẹ̀kọ, Àmàlà, Láfún àti ounjẹ òkèlè yókù bi Ẹ̀bà, Iyán àti bẹẹbẹ lọ.

English Translation: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-05-11 03:16:27. Republished by Blog Post Promoter

“Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá”: Idibò yan Òṣèlú ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún – “Escaping death by the whisker calls for gratitude”: Election of Twenty-fifteen

Ni igbà ipalẹ̀mọ́ idibò, ẹ̀rù ba ará ilú nitori wọn kò mọ ohun ti ó lè sẹlẹ̀.  Àwọn ti ó ndu ipò jade ni rẹpẹtẹ fún ètò-òṣèlú, eyi ti ó fa ki àwọn jàndùkú bẹ̀rẹ̀ ijà ti ó fa sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ pàtàki ni ilú Èkó, eleyi fa ibẹ̀rù pé ọjọ́ idibò yio burú.

Ẹgbẹ́ Onigbalẹ -  APC Logo

Ẹgbẹ́ Onigbalẹ – APC Logo

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ ki i mi ni ikùn àgbà” ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ mi ni ikùn Ọba Èkó, Ọba Rilwanu Akiolu nigbati ó ṣe ipàdé pẹ̀lú àwọn àgbà Ìgbò Èkó, pé ti wọn kò bá dibò fún ẹni ti ohun fẹ, wọn yio bá òkun lọ.  Ọ̀rọ̀ Ọba Rilwanu Akiolu bi ará ilé àti oko ninú.  Eleyi tún dá kún ibẹ̀rù pé ija yio bẹ́ ni ọjọ́ idibò, nitori eyi ọpọlọpọ ará ilú ko jade lati dibò.

Gbogbo àgbáyé ló mọ̀ wi pé àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ki i fẹ gbé Ìjọba silẹ.  Ki ṣe pe wọn ni ifẹ́ ilu,́ bi kò ṣe pé, ó gbà wọn láyè lati lo ipò wọn lati ji owó ilú fún ara àti ẹbi wọn.  Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá pe “Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá”, ikú tó fẹ́ pa ará ilú ti re kọja nitori ọjọ́ idibò lati yan Gómìnà àti Aṣòfin-ipinlẹ̀ ti lọ lai mú ogun dáni bi ará ilú ti rò.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò èsi idibò:

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-14 19:16:02. Republished by Blog Post Promoter

“Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pe“Àyípadà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”: The current slogan in Nigeria is “Change begins with me”

Ohun ti wọ́n bá fi ogún ọdún tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ kọ́, ṣe é bàjẹ́ ni iṣéjú akàn, ṣùgbọ́n lati ṣe àtúnṣe lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bakan na a.  Ó ṣe pataki ki gbogbo ọmọ ilú pinu ni ikan kan lati ṣe àtúnṣe lati bọ́ lọ́wọ́ ìnira ti ó wà ni ilú lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi - Change Begins with Me. Courtesy: @theyorubablog

Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi – Change Begins with Me. Courtesy: @theyorubablog

Àyípadà tàbi Àtúnṣe yẹ ki ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òṣiṣẹ́ Ìjọba, àwọn ti ó nta ọjà, ọ̀gá ilé-iwé àti àwọn ọmọ ilé-iwé, àwọn òṣiṣẹ́ ilé-ìwòsàn, ọmọdé àti àgbà ilú.  Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà àti àwọn iwà ibàjẹ́ ti ó ti gbilẹ̀ fún ọdún pi pẹ́ ti ba nkan jẹ ni orilẹ̀ èdè Nigeria.  Di ẹ ninú àwọn iwà burúkú wọnyi ni ki òṣiṣẹ́ ìjọba ji ẹrù àti owó Ìjọba fún ara wọn tàbi sọ ara wọn di alágbàtà ti o nsọ ọjà di ọ̀wọ́n nipa gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ.  Eleyi lo njẹ ki àwọn iṣẹ́ ti ìjọba bá gbé sita lati tú ọ̀nà ṣe, lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi àti ohun amáyédẹrùn miran wọn ju ti gbogbo àgbáyé lọ.  Nitori òṣiṣẹ́ Ìjọba ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ti ó gba iṣẹ́ lè ma ṣe iṣẹ́ tàbi ki wọn ṣe iṣẹ́ ti kò dára.   Ẹni ti ó nta ọjà á sọ̀rọ̀ si onibárà pẹ̀lú ẹ̀gàn, ojúkòkòrò, ìfẹ́ owó ki kó jọ ni ọ̀nà ẹ̀rú àti à ṣe hàn ló nfa iwà ibàjẹ́ àti olè jijà laarin àwọn Òṣèlú, olóri ẹ̀sìn, òṣiṣẹ́ Ìjọba, ọlọ́jà ti ó nkó ọjà pamọ́ lati fa ọ̀wọ́n, Olùkọ́ ilé iwé, ọmọ ilé-iwé kò ni itẹriba fún Olùko mọ́, àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀  lọ.

Ki àyipadà rere lè dé bá ilú, ó yẹ ki onikálukú yẹ ara rẹ̀ wò fún àtúnṣe kúrò ninú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà, iwà ibàjẹ́, ai ṣojú ṣe ẹni ninú ẹbi, ai bẹ̀rù àgbà, ji ja ilú lólè, ki kó owó ilú lọ si òkèèrè, ki kọ oúnjẹ ilú ẹni silẹ̀ fún oúnjẹ òkèèrè, ayẹyẹ àṣejù, ni ná owó ti èniyàn kò gbà àti ai ni ìtẹ́lọ́rùn.

Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pé “Àyípadà tàbi Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”.   Yorúbà sọ wi pé “Igi kan ki da a ṣe igbó”, eyi túmọ̀ si wi pé ki i ṣe Olóri Ìjọba Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú yoku nikan ni ó yẹ ki ó ṣe àtúnṣe ohun ti ó ti bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n gbogbo ọwọ́ ló yẹ ki ó ṣe àtúnṣe lati gbógun ti iwà ibàjẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-09-23 14:32:38. Republished by Blog Post Promoter

Ìpalẹ̀mọ́ Ìbò oṣù keji, ọjọ́ kẹrinla ọdún Ẹgbãlemẹ̃dogun – Wọn fi ẹ̀tẹ̀ silẹ̀ pa làpálàpá – Preparation for February 2015 Election – Leaving leprosy to cure ring-worm

Ibò ni gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria lati yan Olóri Òṣèlú àti Gómìnà fún agbègbè yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrinla, oṣù keji odun Ẹgbãlemẹ̃dogun.

Ki i ṣe ẹgbẹ́ Òṣèlú meji ló wà ṣùgbọ́n ninú ẹgbẹ́ bi mejidinlọgbọn, ẹgbẹ́ Alágboòrùn àti Onigbalẹ ló mókè jù ninú ẹgbẹ́ yoku.  Laarin ẹgbẹ́ meji yi, ibò lati yan Gómìnà fún àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá wọnyi yio wáyé ni: Èkó laarin Akinwunmi Ambọde àti Jimi Agbájé, Ògùn Gómìnà Ibikunle Amósùn àti Ọmọba Gbóyèga Nasir Isiaka, Ọ̀yọ́ laarin Gómìnà Aṣòfin-àgbà Abiọ́lá Ajimọbi àti Aṣòfin-àgbà Teslim Kọlawọle Isiaka.  Kò si ibò ni ìpínlẹ̀ Ọ̀sun nitori Gómìnà Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá gba ipò padà ni ọjọ́ kẹsan oṣù kẹjọ ọdún Ẹgbãlemẹrinla, nigbati Ekiti gba ipò lọ́wọ́ Gómìnà Olóye Káyọ̀dé Fayẹmi fún Gómìnà Ayọdele Fayoṣe ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kọkànlélogún ọdún Ẹgbãlemẹrinla.  Àsikò Gómìnà Olóye Olúṣẹ́gun Mimiko ti Ondo kò ni pari titi di ọdún Ẹgbãlemẹrindilogun. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-01-27 22:11:09. Republished by Blog Post Promoter

“Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú Ṣe pàtàki” pé Àwọ Lè Yàtọ̀, Ṣùgbọ́n Ẹ̀jẹ̀ Kò Yàtọ̀ – “BLACK LIVES MATTER”, Though Colour may be different Human Blood is not”

B;ack Lives Matter protesters

B;ack Lives Matter protesters

Ikú àwọn ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ọwọ́ Ọlọpa ni orilẹ̀ èdè Àméríkà pọ̀ ju pi pa àwọn aláwọ̀ funfun tàbi laarin àwọn ẹ̀yà kékeré miran.  Ọ̀sẹ̀ kini oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún ṣòro fún àwọn Àméríkà.

Ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti yin ibọn si ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ojú ọmọ àti aya nlọ lọ́wọ́ nigbati ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti pa okunrin Aláwọ̀-dúdú miran bi ẹni pa ẹran ti tún jáde.  Àwọn iroyin yi bi àwọn èrò ninú,  nitori èyi, aláwọ̀ dúdú àti funfun tú jáde lati fi ẹ̀dùn hàn pé “Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú ṣe pàtàki” pé àwọ lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ kò yàtọ̀.  Ó ṣe ni laanu pé Micah Johnson ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú, jagunjagun fun orile ede Àméríkà, ló pa Ọlọpa marun, ó si ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe nipa gbi gbé òfin si ọwọ́ ara rẹ pẹ̀lú ibinu.

Micah Johnson a 25 year old U.S. Army Veteran, the Cops shooter

Micah Johnson a 25 year old U.S. Army Veteran, the Cops shooter

Ìwà burúkú ti di ẹ̀ ninú àwọn Ọlọpa funfun yi hu ki ṣe ìwà ti ó wọ́pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọlọpa aláwọ̀ funfun tàbi gbogbo Ọlọpa ti wọn nṣe iṣẹ́ ribiribi lati dá àbò bo àwọn ará ilú.  Ó ṣe ni laanu pé àwọn Aláwọ̀-dúdú ni Ọlọpa nda dúró jù ni ojú ọ̀nà ọkọ̀, ti ó dẹ̀ n kú ni irú idá dúró bẹ́ ẹ̀.  Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, onidajọ ọ̀daràn kò ṣe idájọ òdodo fún Aláwọ̀-dúdú, èyi kò ran nkan lọ́wọ́.

A lérò wi pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ ti ó jẹ́ Olóri Òṣèlú ilẹ̀ Alawo dudu ti ó n ja ilú lólè lati kó irú, ọrọ̀ ilú lọ pamọ́ si àwọn ilú ti o ti dàgbà sókè yio ronú pìwàdà.  Èrò ti ó n kú ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nitori ọ̀nà ti kò dára, a i si ilé-ìwòsàn gidi, a i ni ohun amáyédẹrùn bi omi, iná mọ̀nàmọ́ná kò jẹ ki Aláwọ̀-dúdú Àméríkà lè fi orisun wọn yangàn.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-07-12 22:58:34. Republished by Blog Post Promoter