Originally posted 2013-06-21 22:30:27. Republished by Blog Post Promoter
Category Archives: Yoruba for the young
Ẹ̀̀ya orí ni èdè Yorùbá – Parts of Head in Yoruba Language
Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀. Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè. A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò.
ENGLISH TRANSLATION
It is important to be familiar with the names of parts of the body in learning a language because it is often embedded in conversation. Understanding these names would enhance the knowledge of Yoruba by those who love to learn the language. We hope that the pictures and the Yoruba pronunciation on these slides would be useful.
Originally posted 2013-07-16 01:52:39. Republished by Blog Post Promoter
Bíbẹ Èkó wo fún Ọ̀sẹ̀ kan – Ọjọ́ kẹta: Visiting Lagos for one week – Day 3 (Yoruba Conversation)
Apá Kinni – Part One
You can also download the conversation by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 3(mp3)
Continue reading
Originally posted 2013-06-04 17:09:30. Republished by Blog Post Promoter
Orúkọ Gbogbo Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá – Names of part of Human Body in Yoruba
Nitotọ àti ṣe ẹ̀yà orí tẹlẹ ṣugbọn a lérò wípé orúkọ gbogbo ẹ̀yà ara lati orí dé ẹsẹ á wúlò fún kíkà.
Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá and the English Translation of names of part of the body
Though the names of parts of the head had earlier been published but we think the readers will find the names of the whole body from head to toe will be useful for reading
View more presentations or Upload your own.
Originally posted 2016-08-01 12:05:50. Republished by Blog Post Promoter
“Ilé làbọ̀sinmi oko” – “Home is for rest after the farm or hard day’s work”.
Bi ènìà lówó tàbi bi kò ni, àwọn ohun kan ṣe pàtàki lati wà ni ílé ki a tó lè pẽ ibẹ̀ ni ilé. Fún àpẹrẹ: ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé; àdìrò àti àdògán; omi: Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ.
Yorùbá ni “ilé làbọ̀sinmi oko”, lẹhin iṣẹ́ õjọ, ó ṣe pàtàkì lati ni ilé ti ènìà yio darí si. Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi.
ENGLISH LANGUAGE
Whether a person is rich or poor, there are some basic things that are important in a house before it can be called a home. For example: A house with a roof, door and windows; kitchen and cooking utensils; water: either pipe borne water, rain water or a well and food are all very important in a home.
Yoruba adage said “Home is for rest after the farm or a hard day’s work, hence it is important to have a house for a person to return to. Check out the names and pictures of many household items on this page.
Originally posted 2013-08-13 11:20:51. Republished by Blog Post Promoter
Àwòrán àti pi pè orúkọ ẹ̀yà ara lati ori dé ọrùn – Pictures and pronunciation of parts of the body from head to neck
You can also download the Parts of the body in Yoruba by right clicking this link: Parts of the body in Yoruba – head to neck (mp3)
ORÍ DÉ ỌRÙN | HEAD TO NECK |
Orí | Head |
Irun | Hair |
Iwájú orí | Forehead |
Ìpàkọ́ | back of the head |
Ojú | Eye |
Imú | Nose |
Etí | Ear |
Ẹnu | Mouth |
Ahán | Tongue |
Eyín | Teeth |
Ẹ̀kẹ́ | Cheek |
Àgbọ̀n | Chin |
Ọrùn | Neck |
Originally posted 2015-11-13 10:53:10. Republished by Blog Post Promoter
ATỌ́NÀ LÉDÈ YORÙBÁ – Cardinal Directions in Yoruba
Originally posted 2013-04-16 19:01:07. Republished by Blog Post Promoter
OHUN TÍ́ A LÈRÍ NÍNÚ ÀTI ÀYÍKÁ ILÉ – BASIC YORUBA HOUSEHOLD ITEMS
YORÙBÁ | ENGLISH | YORÙBÁ | ENGLISH |
Àwo pẹrẹsẹ | Plates | Ṣíbí | Spoon |
Abọ́ | Dish | Ọ̀bẹ | Knife |
Ago | Cup | Ìgò Omi | Water Bottle |
Aago | Clock | Ìkòkò Omi | Water Pot |
Aṣọ | Clothes | Omi | Water |
Oúnjẹ | Food | Ibi Ìdáná | Kitchen |
Ilẹ̀kùn | Door | Igi Ìdáná | Firewood |
Fèrèsé | Window | Yàrá | Room |
Ijoko | Seat | Gbàngán | Living Room |
Àga | Chair | Ilẹ̀ilé | Floor |
Àga Tábìlì | Table | Òkèàjà | Ceiling |
Pẹpẹ | Shelf | Ọgbà | Compound |
Òrùlé | Roof | Iléìwẹ̀ | Bathroom |
Àpótí Aṣọ | Boxes | Iléìtọ̀/Iléìgbẹ́ | Toilet |
Originally posted 2013-05-07 23:58:38. Republished by Blog Post Promoter
Ìbà Àkọ́dá – Reverence to the First Being
Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá
Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ
Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ
Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ
Alápáńlá tó so’lé ayé ró
Ṣe àtúntò ayé mi
Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ
Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀
Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ
Ìbà! ìbà!!
Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú
Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ
Ọmọ onínúure a má a pọ́njú
Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ
Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́
Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o
Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé
Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere
Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́
Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ
Ìbà! ìbà!!
Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò
ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú
ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu
Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú!
ọ̀rẹ́ kan tí mo ní
Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù!
Ìbà! ìbà!!
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-10-02 19:50:39. Republished by Blog Post Promoter