Category Archives: Learning Yoruba

Ìbà Àkọ́dá – Reverence to the First Being

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá - A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá – A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá
Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ
Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ
Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ
Alápáńlá tó so’lé ayé ró
Ṣe àtúntò ayé mi
Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ
Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀
Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ

Ìbà! ìbà!!

Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú
Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ
Ọmọ onínúure a má a pọ́njú
Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ
Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́
Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o
Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé
Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere
Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́
Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ

Ìbà! ìbà!!

Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò
ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú
ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu
Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú!
ọ̀rẹ́ kan tí mo ní
Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù!

Ìbà! ìbà!!

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-02 19:50:39. Republished by Blog Post Promoter