Ayẹyẹ Aadọrun ọjọ́ ibi Alhaji Lateef Káyọ̀dé Jakande, Gómìnà Alágbádá Àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Èkó – Celebration of 90th Birthday of Alhaji Jakande, first Executive Governor of Lagos State

Èkó jẹ́ Olú-Ilú Nigeria fún ọdún mẹ́tàdinlọ́gọrin, ṣùgbọ́n idikọ fún òwò àti ọrọ̀ ajé lati ẹgbẹgbẹ̀run ọdún sẹhin titi di ọjọ́ oni.  “Ta ló lè mọ ori ọlọ́là lágbo?”  Gbogbo àgbáyé ló nwá lati ṣe ọrọ̀ ajé ni ilú Èkó, òbí Gómìnà Jakande kò yàtọ̀ nitori wọ́n wá lati Òmù-Àrán, ti ó wà ni ìpínlẹ Kwara lati wá ṣe òwò ni Eko bi ti gbogbo èrò lai mọ wi pé ọmọ ọkùnrin ti Ọlọrun fi ta wọ́n lọ́rẹ ni ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje ọdún Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàlémọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹ́hin ni agbègbè Ẹ̀pẹ́tẹ̀dó ni Ìsàlẹ̀-Èkó, yio di Gómìnà Alágbádá Àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọjọ́ kan.

Àwọn Gómìnà Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan pẹ̀lú– Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Olóri- Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan
Apá-òsi si ọ̀tún: Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ambrose Ali – Ìpínlẹ̀ Bendel; Olóògbé Pa Adékúnlé Ajáṣin – Ìpínlẹ̀ Ondó, Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ – Olóri- Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan, Olóògbé Olóyè Bisi Ọnabanjọ – Ìpínlẹ̀ Ògùn, Alhaji Lateef Jakande – Ìpínlẹ̀ Eko àti Olóògbé Olóyè Bọ́lá Ìgè

 

Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni ki èniyàn dàgbà darúgbó di aadọrun ọdún láyé.  Ki ṣe pi pẹ́ láyé lásán, ṣùgbọ́n ki a  lo àsìkò, ẹ̀bùn àti ẹ̀kọ́ ti a bá ni lati sin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bi Alhaji Lateef Jakande ti fi ipò Òṣèlú tirẹ̀ sin Ìpínlẹ̀ Èkó.  Kò si ẹni ti ó ńgbé ni Ìpínlẹ̀ Èkó ti kò jẹ ninú iṣẹ́ ribiribi, ti Alhaji Jakande ṣe si Ìpínlẹ̀ Èkó. Lára àwọn iṣẹ́ ná à ni:

 

Ìjọba Gómìnà Jakande ni igbà tirẹ̀ dá:

Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ilé-iṣẹ́ amóhùn-máwòrán sile,

Ki kọ́ Ilé-ìwé ọ̀fẹ́ ti o sọ ilé-iwe li lọ lati iṣipo mẹta lójúmọ́ di ìgbà kan fún gbogbo ọmọ ilé-ìwé

Di dá Ilé-iwe giga Ipinle àkọ́kọ́ ni Orilẹ̀-èdè Nigeria sílẹ̀

Bi bẹ̀rẹ̀ Ọkọ̀ ojú-irin igbàlódé ti àwọn ijọba ológun dá dúro

Ki kọ́ Ile-iwòsàn àpapọ̀ si gbogbo agbègbè

Ki kọ́ ẹgbẹgbẹ̀rún ibùgbé àrọ́wọ́tó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ

Gbogbo ẹgbẹ́ Olùkọ̀wé à̀ti Olùdarí gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ lóri ayélujára bá ẹbi, ará àti gbogbo èrò Èkó dúpẹ́ lọ́wọ́ Èdùmàrè ti o dá ẹmi Alhaji Lateef Kayode Jakande si.

ENGLISH TRANSLATION

Lagos was the capital of Nigeria for seventy seven years (1914 to 1991), but for thousands of years has been and still remains the nerve centre of commerce and trade.   According to Yoruba adage “Who can identify the head of the wealthy in crowd?  People from all over the world have been coming for trade and commerce in Lagos, parents of Alhaji Jakande were no exception as they left their community in Omu-Aran in present day Kwara State to trade without realizing that their gift of God, a baby boy, born on the twenty-third of July, 1929 would one day, become the first Executive Governor of Lagos State.

It is a gift of God for one to reach adulthood to the age of ninety years.  It is not enough to live long but the use of one’s time, gift or talent and knowledge to serve others as Alhaji Jakande has used his political position to serve all Lagosian.

The Government of Alhaji Jakande established the following:

Lagos Radio and TV

Free education – Building of many schools to eliminate the three tier shift at Schools

Establishing the first State University – Lagos State University

Began Metro rail that was truncated by the Military Government

Building of General Hospitals in different zones of Lagos

Building of thousands of affordable housing estates etc.

 

The publisher and editorial team of The Yoruba Blog (an online publication) join the family, friends and all Lagosian to thank the Almighty for sparing Alhaji Lateef Kayode Jakande’s life.

Share Button

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.