Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Ìtàn bi Ìjàpá ti fa Àkóbá fún Ọ̀bọ: Ẹ Ṣọ́ra fún Ọ̀rẹ́ Burúkú” – “The Story of how the Tortoise caused the Monkey an unprovoked trouble: Be careful with a bad Friend”

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé.

Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, “Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́”, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra.  Ìjàpá  pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nitori wọn jọ ngbé àdúgbò.  Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nitori eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe.

Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé “Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri”, Ọ̀bọ kò ṣe “Àmin àdúrà” nitori ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn.  Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.

Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ.  Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa.  Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ. Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ.  Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn.  Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun.  Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá.  Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi.  Ẹkùn gbàgbọ́, nitori ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ - Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ – Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun.  Gẹ́rẹ́ ti Ọ̀bọ sún mọ́ Ẹkùn, o fã lati gba ikùn rẹ gẹ́gẹ́ bi Ìjàpá ti sọ, ki ó lè ṣu di dùn fún òhun.  Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀.  Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji.  Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ.  Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun.  Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe “Amin”, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.  Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe “Àmin” lai dúró.  Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi “Àmin” titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó mã funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-16 22:39:59. Republished by Blog Post Promoter

Wi wé Gèlè Aṣọ Òfì/Òkè – How to tie Yoruba Traditional Woven Fabric

Aṣọ-Òfì tàbi Aṣọ-Òkè jẹ́ aṣọ ilẹ̀ Yorùbá.  Aṣọ òde ni, nitori kò ṣe gbé wọ lójojúmọ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Aṣọ-Òfì/Òkè wúwo, ṣùgbọ́n ti ìgbàlódé ti bẹ̀rẹ̀ si fúyẹ́ nitori òwú igbalode.  Yorùbá ma nlo Aso-Oke fún Igbéyàwó, Ìkómọ, Òkú ṣi ṣe, Oyè ji jẹ, àti ayẹyẹ ìbílẹ̀ yoku.  Ó dùn lati wé, ó si yẹ ni.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò wi wé gèlè Aṣọ-Òkè ninú àwòrán àti àpèjúwe ojú iwé yi:

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba traditional woven clothes is indigenous to the Yoruba people.  It is an occasional wear, as it cannot be worn as a daily casual wear.  Many of these traditional fabrics are heavy, but the modern ones are light because it is woven with the modern light weight threads.  It is often used during traditional marriage, Naming Ceremony, Burial, Chieftaincy Celebration and during other traditional festivals.  It is easy to tie and it is very befitting.  Check out the video on how to tie the traditional woven clothes as head tie on the video on this page.

 

Share Button

Originally posted 2015-07-10 10:15:04. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé làbọ̀sinmi oko” – “Home is for rest after the farm or hard day’s work”.

Bi ènìà lówó tàbi bi kò ni, àwọn ohun kan ṣe pàtàki lati wà ni ílé ki a tó lè pẽ ibẹ̀ ni ilé.  Fún àpẹrẹ: ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé; àdìrò àti àdògán; omi: Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ.

Yorùbá ni “ilé làbọ̀sinmi oko”, lẹhin iṣẹ́ õjọ, ó ṣe pàtàkì lati ni ilé ti ènìà yio darí si.  Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi.

ENGLISH LANGUAGE

Whether a person is rich or poor, there are some basic things that are important in a house before it can be called a home.  For example: A house with a roof, door and windows; kitchen and cooking utensils; water: either pipe borne water, rain water or a well and food are all very important in a home.

Yoruba adage said “Home is for rest after the farm or a hard day’s work, hence it is important to have a house for a person to return to.  Check out the names and pictures of many household items on this page.

 

 

Share Button

Originally posted 2013-08-13 11:20:51. Republished by Blog Post Promoter

“Ti ibi, ti ire la wá ilé ayé” – Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Ìgboro ni Èkó: “We came into the world with good and bad” – Street Talk and Activities in Lagos

Èkó jẹ́ olú ìlú Nigeria fún ọpọlọpọ ọdún, ki wọn tó sọ Abuja di olú ìlú Nigeria, ṣùgbọ́n Èkó ṣi jẹ́ olú ìlú fún iṣẹ ọrọ̀ gbogbo Nigeria.  Nitori eyi, gbogbo ẹ̀yà Nigeria àti àwọn ará ìlú miran titi dé òkè-òkun/ìlú-òyinbó ló wà ni Èkó.

Yorùbá ni èdè ti wọn nsọ ni ìgboro Èkó, ṣùgbọ́n ọpọlọpọ gbọ èdè Gẹẹsi, pataki àwọn ti ki ṣé ọmọ Yorùbá.  Ẹ wo díẹ̀ ni àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ ni ìgboro Èkó:

ENGLISH TRANSLATION

Lagos was the capital of Nigeria for many years before the capital was moved to Abuja, but Lagos remains the commercial capital of Nigeria.  As a result, every ethnic group in Nigeria and people from abroad/Europe are present in Lagos.

Share Button

Originally posted 2013-09-24 19:43:17. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá àti Ọmọdé Mẹta – “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́” – The Tortoise and the three playful children “A mouth that will not stay shut, the lips that will not stay closed, invites trouble for the cheek”

Ni abúlé Yorùbá nigbati ko ti si ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì tabi ẹ̀rọ amú-òhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ ayélujára, àwọn ọmọdé má nkó ara jọ lati ṣe eré lẹhin iṣẹ́ oojọ Bàbá àti Ìyá wọn.  Pataki, ni igba ọ̀gbẹlẹ̀ nigbati iṣẹ́ oko din kù.

Ọmọdé Mẹta - 3 young boys playing.  Courtesy: @theyorubablog

Ọmọdé Mẹta – 3 young boys playing. Courtesy: @theyorubablog

Àwọn ọmọdé kunrin mẹta bẹ̀rẹ̀ si ṣe eré ìdárayá leti òkun lai bikità ohun ti ó nlọ ni àyíká.  Ọmọ kini lérí pé ohun lè gun igi ọ̀pẹ pẹ̀lu ọwọ́ lásá̀n, ekeji ni ohun lè wẹ òkun yi já, ẹni kẹta ni ohun lè ta ọfà si ọ̀run.  Àjàpá gbọ́ gbogbo ìlérí àwọn mẹta yi ṣe, ó gbé ìròyìn lọ fún Ọba, pé ohun ti ri àwọn ti ó lè ṣe nkan ti ẹni kan kò ṣerí.  Ọba àti àgbà ìlú kò fẹ́ gba ohun ti Àjàpá wi gbọ́ nitori ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n o ni ki Ọba ṣe ohun ti ó bá fẹ́ fún ohun ti ìròyìn ti ohun mú wá kò bá ṣẹ.

Ọba ránṣẹ́ pé àwọn ọmọdé kunrin mẹta yi, pé ki wọn wa ṣe ohun ti wọn ṣèlérí pé wọn lè ṣe.  Yorùbá ni “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́”.  Ìbẹ̀rù ba àwọn ọmọ yi, ẹbí wọn bẹ Ọba pe eré ọmọdé lásán ni àwọn ọmọ yi fi sọ gbogbo ohun ti wọn sọ, ṣùgbọ́n ẹ̀pa ò bóró mọ́ gbogbo ará ìlú (àti Àjàpá) ti pé jọ lati wòran.  Àwọn ọmọde mẹta yi bẹ̀rẹ̀ si kọ orin arò bayi:

 

Ọmọdé mẹ́ta nṣère

Éré o, érè ayọ̀ 2ce

Ọ̀kán lóhun yó gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun yó wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun ó tafà sọ́run,

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀tàfa, ọ̀tàfa, ọ̀tàfa

Éré o, érè ayọ̀.

Èyi ti ó ni ohun lè gun ọ̀pẹ, dé ìdí ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹkún.  O gun lẹ̃ kini, ó ṣubú, o gun lẹ̃ keji kọjá ibi tó dé ni àkọ́kọ́ ki ó tó ṣubú.  Èyi jẹ ki àwọn ará ìlú bẹ̀rẹ̀ si pàtẹ́wọ́ lati ki láyà, ó bá mú ọ̀pẹ gùn ni ẹ̃kẹta, ó́ gun dé orí.  Ariwo sọ, inú ará ìlú dùn.  Nigbati ọmọdé keji ti o ni ohun lè wẹ́ òkun ja, gbọ́ ariwo ìdùn nú yi, eleyi ki láyà.  Bi ti ẹni àkọ́kọ́, ọmọdé keji ti ó ni ohun lè wẹ òkun já, o wẹ dé odi keji, nibiti wọn ti fi ijó àti ayọ̀ pàdé rẹ.  Eleyi ló fún ọmọdé kẹta ni ìgboiyà pe ohun na lè ṣe ohun ti ohun ti ṣe ìlérí rẹ.  Ó ta ọfà lẹ̃ kini, ọfà na, kò rin jinà ki o to wálẹ̀.  O tã lẹ̃ keji, ọfà yi lọ bi ẹni pé kòní padà̀ si ilẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún wálẹ̀ .  Ni igbà kẹta ọfà na lọ sókè ọ̀run lai padà.  Ariwo sọ, ṣùgbọ́n ìtìjú bo Àjàpá. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-20 22:16:26. Republished by Blog Post Promoter

“Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe: Olè ki ṣe Orúkọ Rere lati fi Jogún” – “Remember the Child of Whom you are: Being labelled a ‘Thief’ is Not a Good Legacy”

Oriṣiriṣi òwe ni Yorùbá ni lati fihàn pé iwà rere ló ni ayé.  Iwà ni Yorùbá kàsí ni ayé àtijọ́ ju owó ti gbogbo ilú bẹ̀rẹ̀ si bọ ni ayé òde òni.  Fún àpẹrẹ, Yorùbá ni “Ẹni bá jalè ló bọmọ jẹ́”, lati gba òṣiṣẹ́ ni ìyànjú pé ki wọn tẹpámọ́ṣẹ́, ki wọn má jalè.

Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe - Leave a good legacy.  Courtesy: @theyorubablog

Ránti Ọmọ Ẹni ti Iwọ Nṣe – Leave a good legacy. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé òde òni, owó ti dipò iwà.  Olóri Ijọ, Olóri ilú àti Òṣèlú ti ó ja Ijọ àti ilú ni olè ni ará ilú bẹ̀rẹ̀ si i bọ ju àwọn Olóri ti kò lo ipò lati kó owó ijọ àti ilú fún ara wọn.  Owó ti ó yẹ ki Olóri Ijọ fi tọ́jú aláìní, tàbi ki Òṣèlú fi pèsè ohun amáyédẹrùn bi omi mimu, ọ̀nà tó dára, ilé ìwòsàn, ilé-iwé, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ ẹ bẹ ẹ lọ ni wọn kó si àpò, ti wọn nná èérún rẹ fún ijọ tàbi ará ilú ti ó bá sún mọ́ wọn.  Ará ilú ki ronú wi pé “Alaaru tó njẹ́ búrẹ́dì, awọ ori ẹ̀ ló njẹ ti kò mọ̀”.

Owé Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ránti ọmọ Ẹni ti iwọ nṣe ” pin si ọ̀nà méji.  Ni apá kan, inú ọmọ ẹni ti ó hu iwà rere ni àwùjọ á dùn lati ránti ọmọ ẹni ti ó nṣe, ṣùgbọ́n inú ọmọ “Olè”, apànìyàn, àjẹ́, àti oniwà burúkú yoku, kò lè dùn lati ránti ọmọ ẹni ti wọn nṣe.  Nitori eyi, ki èniyàn hu iwà rere.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-09 15:29:50. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi nya igi oko: Ìbò ni ipinlẹ Ọ̀ṣun” – “There is strength in numbers: Osun State Election”

Ninú Ẹ̀yà mẹrin-din-logoji orilẹ̀ èdè Nigeria, ẹ̀yà mẹ́fà ni o wa ni ipinlẹ Yorùbá lápapọ̀.  Àwọn ẹ̀yà wọnyi ni: Èkó – ti olú ilú rẹ jẹ Ìkẹjà; Èkiti – ti olú ilú rẹ jẹ Adó-Èkiti; Ò̀gùn – ti olú ilú rẹ jẹ Abẹ́òkúta; Ondo – ti olú ilú rẹ jẹ Àkúrẹ́; Ọ̀ṣun – ti olú ilú rẹ jẹ Òṣogbo àti Ọyọ – ti olú ilú rẹ jẹ Ìbàdàn.

ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn - Osun voters voted and protected their votes

ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn – Osun voters voted and protected their votes

Ni Òkè-Òkun, bi enia ba ni ẹjọ́ ni ilé-ẹjọ́, tàbi ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ri, tàbi hùwà àbùkù miran, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè gbé àpóti ibò ṣùgbọ́n, ti kò bá ni itiju, ti ó gbé àpóti ibò, ọ̀pọ̀ àwọn èrò ilú kò ni dibò fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.  Eyi kò ri béè ni orilẹ-èdè Nigeria, nitori, ẹlẹ́wòn, eleru, olè, apànìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ti ó di olówó ojiji ló ńgbé àpóti ibò nitori wọn mọ̀ pé àwọn lè fi èrú dé ipò.

Àwọn èrò ẹ̀yà Ọ̀ṣun fi òwe Yorùbá ti o ni “Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi ńya igi oko” hàn ni idibò ti ó kọjá ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ, ọdún Ẹgbẹlemẹrinla, wọn kò bẹ̀rù bi Ìjọba àpapọ̀ Nigeria ti kó Ológun àti ohun ijà ti àwọn ará ilú lati da ẹ̀rù bà wọn.  Wọn tú jáde lati fi ọ̀pọ̀ dibò àti bójú tó ibò wọn lati gbé Góminà Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá padà.

ENGLISH TRANSLATION

Out of the thirty-six States in Nigeria, six are in Yoruba land altogether.  These States are: Lagos – State capital Ikeja; Ekiti – State capital at Ado-Ekiti; Ogun – State capital at Abeokuta; Ondo – State capital at Akure; Osun – State capital at Osogbo and Oyo with the State capital at Ibadan.

In the developed world/abroad, if a person has a pending law suit in the Court, or has once been in prison, or has behaved in a disgraceful manner, such person cannot vie for a Political position, but even if such a person has no sense of shame, and decided to vie, many of the masses would not vote for such.  This is not the case in Nigeria, because a prisoner, fraudster, thief, killers/assassin etc with their ill-gotten wealth/money could vie for political position since they know they could win through fraudulent means.

The people of Osun State reflected the application of the Yoruba proverb that said “It is by means of their numbers that Locusts could tear down a tree” during the Governorship Election held on Saturday, ninth August, 2014, when they defied the Federal might as Soldiers and armoured tanks were drafted to intimidate the people.  They trooped out in their numbers to vote and protect their votes to re-elect Governor (Mr) Rauf Aregbesola.

Share Button

Originally posted 2014-08-15 22:49:34. Republished by Blog Post Promoter

Jọ mi, Jọ mi, Òkúrorò/Ìkanra ló ndà – Insisting on people doing things one’s way, would turn one to an ill-tempered or peevish person

Yorùbá ni “Bi Ọmọdé ba ṣubú á wo iwájú, bi àgbà ba ṣubú á wo ẹ̀hìn”.  Bi enia bá dé ipò àgbà, pàtàki gẹ́gẹ́ bi òbí, àgbà ìdílé tàbi ọ̀gá ilé iṣẹ́, ẹni ti ó bá ni ìfẹ́ kò ni fẹ́ ki àwọn ti ó mbọ̀ lẹhin ṣubú tàbi ki wọn kùnà.

Ẹni ti ó bá fẹ ìlọsíwájú ẹnikeji pàtàki, ọmọ ẹni, aya tabi oko eni, ẹ̀gbọ́n, àbúro, ọmọ-iṣẹ, ọmọ ilé-iwé, aládúgbò, ẹbi, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti ará, a má a tẹnu mọ ìbáwí lati kìlọ̀ fún àwọn ti ó mbọ̀ lẹhin ki wọn ma ba a ṣìnà.  Eleyi lè jẹ ki irú àgbà bẹ́ẹ̀ dàbi onikọnra lójú ẹni ti nwọn báwí.  Fún àpẹrẹ ni ayé òde òní, bi òbí ba nsọ fún ọmọdé nígbà gbogbo pé ki ó ma joko si ori ayélujára lati má a ṣeré, ki ó lè sùn ni àsikò tàbi ki ó ma ba fi àkókò ti ó yẹ kó ka iwé ṣeré lóri ayélujára, bi oníkọnra ni òbí ńrí, ṣùgbọ́n iyẹn kò ni ki òbí ma ṣe ohun ti ó yẹ lati ṣe fún di dára ọmọ.

Yorùbá sọ wi pé, “Ajá ti ó bá ma sọnù, ki gbọ́ fèrè Ọdẹ”.  Ki ènìyàn ma ba di oníkọran, kò si ẹni ti ó lè jọ ẹnikeji tán, àwọn ibeji pàápàá kò jọra.  Bi ọkọ tàbi aya bá ni dandan ni ki aya tàbi ọkọ ṣe nkan bi òhun ti fẹ́ ni ìgbà gbogbo, ìkanra ló ńdà. Nitori èyi, bi enia bá ti ṣe ìkìlọ̀, ki ó mú ẹnu kúrò ti ó bá ri wi pé ẹni ti òhun ti báwí kò fẹ́ gbọ́.

ENGLISH TRANSLATION

According to a Yoruba adage, “When a child falls, he/she looks ahead, when an elder falls, he/she reflects on the past”.  When one reaches the position of an elder, particularly as a parent, family leader, a big boss, or a benevolent person would not want those coming behind or less experienced go astray or make the same mistake one has made in the past. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-07-24 21:38:33. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan – Ayé Móoru” – “Heaven is collapsing, is not a problem peculiar to one person – Global Warming”

Ọ̀run nyabọ̀ – Nature’s fury

Ọ̀run nyabọ̀ – Nature’s fury

Ìbẹ̀rù tó gbòde ayé òde òni ni pé “Ayé Móoru”, nitori iṣẹ̀lẹ̀ ti o nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé bi òjò àrọ̀ irọ̀ dá ni ilú kan, ilẹ̀-riru ni òmìràn, ọ̀gbẹlẹ̀, omíyalé, ijà iná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Eleyi dá ìbẹ̀rù silẹ̀ ni àgbáyé pàtàki ni àwọn ilú Òkè-Òkun bi Àmẹ́ríkà ti ó ka àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyi si àfọwọ́fà ọmọ ẹda.  Wọn kilọ̀ pé bi wọn kò bá wá nkan ṣe si Ayé Móoru yi, ayé yio parẹ́.

Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé “Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan”, ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri amin pé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn.  Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ ni tootọ.   Elòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré.  Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wí pé àwọn sá fún.  Fún àpẹrẹ, nigbati iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹwa sẹhin.  Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wí pé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó “kú sílẹ̀ de ikú”. Bi èniyàn bẹ̀rù á kú, bi kò bẹ̀rù á kú, nitori gẹ́gẹ́ bi itàn àdáyébá, gbogbo ohun ti ó nṣẹlẹ̀ láyé òde òni ló ti ṣẹlẹ̀ ri.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-19 08:30:59. Republished by Blog Post Promoter

“Òjò nrọ̀, Orò nké, atọ́kùn àlùgbè ti ò láṣọ méji a sùn ihòhò – Owó epo rọ̀bì fọ́”: “The rain is falling and the call of the secret cult is sounding loudly outside, the shuttle that lacks a change of clothing will sleep naked – Crude Oil price crashed”

Ìgbà tàbi àsikò mèji ló wà ni ọ̀pọ̀ ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú, ìgbà òjò àti ẹ̀rùn.  Ni ayé àtijọ́, òjò ni ará ilú gbójúlé lati pọn omi silẹ̀ fún ọ̀gbẹlẹ̀.  Àsikò òjò ṣe pàtàki fún iṣẹ́-àgbẹ̀, omi pi pọn pamọ́ fún li lò, àti fún ìtura lọ́wọ́ ooru.

Ẹ̀rọ wi wa epo rọ̀bì - Crude Oil Rig

Ẹ̀rọ wi wa epo rọ̀bì – Crude Oil Rig. Oil Price Drop Deepens Nigeria Economy Concerns

A lè fi ìgbà òjò wé ìgbà ti orilẹ̀ èdè Nigeria pa owó rẹpẹtẹ lori epo rọ̀bì lai fi owó pamọ́.  Lati ìgbà ti epo rọ̀bì ti gbòde, ilú ko kọ ara si iṣẹ́ àgbẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ miran ti ó lè pa owó wọlé.  Àwọn Ìjọba Ológun àti Alágbádá, bẹ̀rẹ̀ si ná owó bi ẹni pé ìgbà ẹ̀rùn kò ni dé.  Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti ji jà ilú ni olè, kò jẹ ki òjò owó epo rọ̀bì rọ̀ kári.  Pẹ̀lú gbogbo owó epo rọ̀bì rẹpẹtẹ, iwà ibàjẹ́ pọ̀ si, kò si ọ̀nà ti ó dára, ilé-iwé bàjẹ́ si, ilé-iwòsàn kò ni ẹ̀rọ igbàlódé, ilú wà ni òkùnkùn nitori dákú-dáji iná-mọ̀nàmọ́ná àti ìnira yoku.

Òwe Yorùbá sọ wipé “Òjò nrọ̀, Orò nké, atọ́kùn àlùgbè ti ò láṣọ méji a sùn ihòho”  Ìtumọ̀ òwe yi ni pé “Ẹni ti kò bá pọn omi de òùngbẹ nigbà òjò , a jẹ ìyà rẹ ni ìgbà ẹ̀rùn”. A lè fi òwe yi ṣe ikilọ fún àwọn Òṣèlú Alágbádá ti ó nkéde fún ibò ni lọ́wọ́lọ́wọ́ pé àtúnṣe ṣi wà lati rán aṣọ kọjá méji fún ará ilú.  Ni àsikò ẹ̀rùn ti owó epo rọ̀bì fọ́ yi, ó yẹ ki àwọn Òṣèlú lè ronú ohun ti wọn lè ṣe lati yi ìwà padà kúrò ni inákuná àti lati ronú ohun ti wọn lè ṣe lati pa owó wọlé kún owó epo rọ̀bì, ki ilú lè rọgbọ lọ́jọ́ iwájú.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-06 09:30:04. Republished by Blog Post Promoter