Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Ẹni ti ó bá mọ inú rò, á mọ ọpẹ́ dá”: Whoever can think/reason will know how to give thanks

Ọmọ bibi ni ewu púpọ̀, nitori eyi ni Yorùbá fi ma nki “ìyá ọmọ kú ewu”.  Ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ tàbi ìkómọ, Bàbá, Ìyá, ẹbi àti ọ̀rẹ́ òbí ọmọ tuntun á fi ìdùnnú hàn nipa ṣíṣe ọpẹ́ pataki fún Ọlọrun

Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi ti òbí lò lati fi ẹmi imõre hàn.

ENGLISH TRANSLATION

Child birth is fraught with danger, as a result, Yoruba people often greet the mother of a new born, “well done for escaping the danger”.  On the day of the naming ceremony or child dedication, both the father, mother, family and friends of the new baby’s parent would show their gratitude by giving thanks to God.

See below some of the names that parents give to show their gratitude: Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-06-27 12:10:46. Republished by Blog Post Promoter

“Tani alãikàwé/alãimọ̀wé? Ẹnití ó lè kọ, tó lè kà Yorùbá kúrò ní alãikàwé/alãimọ̀wé bí o tilẹ̀ jẹ́ pe ko le kọ tàbí ka gẹ̀ẹ́sì” – “Who is an illiterate? Anyone who can read or write Yoruba cannot be termed an illiterate even though cannot read or write English”

Oriṣiriṣi ènìyàn miran tiki sọmọ Yorùbá pọ ni ìlú nla bi ti Èkó tàbí àwọn olú ìlù nla miran ni agbègbè ilẹ Yorùbá (fun àpẹrẹ:  Abéòkúta, Adó-Èkìtì, Akurẹ, Ibadan, Oṣogbo, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ). Gẹ́gẹ́bí Wikipedia ti kọ, ni orílẹ̀ èdè Nàíjírià, èdè oriṣiriṣi lé ni ẹ̃dẹgbẹta lélógún, meji ninu èdè wọ̀nyí ko si ẹni to nsọ wọn mọ, mẹsan ti parẹ́ pátápáta. Eleyi yẹ ko kọwa lọgbọn lati dura ki èdè Yorùbá maṣe parẹ.

Ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ - Private Primary School.  Courtesy: @theyorubablog

Ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ – Private Primary School. Courtesy: @theyorubablog

A ṣe àkíyèsí wipé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ ti ki ṣe ti Ìjọba, kò gba àwọn ọmọ láyè lati kọ tàbi sọ èdè Yorùbá ni ilé ìwè. Eleyi lo jẹ ikan ninu ìdí pípa èdè Yorùbá tàbi èdè abínibí yoku rẹ.  Bí àwọn ọmọ ba délé lati ilé ìwè, èdè gẹẹsi ni wọn  mba òbí sọ nítorí ìbẹrù Olùkọ wọn to ni ki wọn ma sọ èdè abínibí.  Bi òbí ba mba wọn sọ èdè Yorùbá (tàbí èdè abínibí) àwọn ọmọ yio ma dahun lédè gẹẹsi.   Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olùkọ́ ti o ni ki àwọn ọmọ ma sọ èdè Yorùbá wọnyi, èdè gẹ̀ẹ́sì ko ja gẽre lẹnu wọn, nítorí èyí àmúlùmálà ti wọn fi kọ́mọ, ni àwọn ọmọ wọnyi nsọ.  Kíkọ, kíkà èdè Yorùbá ko di ọmọ lọ́wọ́ lati ka ìwé dé ipò gíga.

Ọmọdé lo ma tètè gbọ èdè ti wọn si le yara kọ òbí. Ìjọ̀gbọ̀n ni èdè aiyede ma nda silẹ nitorina ẹ majẹ ki a di àwọn ọmọ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n, ka ran wọn lọ́wọ́ fún ìlọsíwájú èdè Yorùbá. Ó sàn ki gbogbo ọmọ tó parí ìwé mẹfa le kọ, ki wọn le kà Yorùbá tàbi èdè abínibí ju pé ki wọn ma le kọ, ki wọn ma lèkà rárá. Bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ oníṣé ọwọ́, oníṣòwò àti àgbẹ̀ bá lè kọ́ lati kọ àti lati ka èdè Yorùbá ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ àgbà tàbi lẹ́hìn ìwé-mẹ́fà, á wúlò fún ìlú. Fún àpẹrẹ, wọn a le kọ orúkọ ní Ilé Ìfowópamọ́, kọ ọjọ́ ìbí ọmọ wọn sílẹ̀, kọ nípa iṣẹ́ wọn sí ìwé àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Ẹnití o le kọ, tó lè kà Yorùbá kúrò ní alãikàwé/alãimọ̀wé bí o tilẹ̀ jẹ́ pe ko le kọ tàbí ka gẹ̀ẹ́sì.

ENGLISH TRANSLATION

There are many people who are not of Yoruba parentage in major cities like Lagos and other big Cities in Yoruba geographical areas (for example: Abeokuta, Ado-Ekiti, Akurẹ, Ibadan, Oṣogbo etc).  According to Wikipedia, there are more than 520 languages in Nigeria, 2 of these languages are no longer spoken by anyone, 9 is totally extinct.  This should teach us a lesson to struggle to ensure Yoruba does not go into extinction. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-30 22:40:42. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ Kú Ọwọ́ Lómi Là Nki Ọlọ́mọ Tuntun – Ìtọ́jú Ọmọ Tuntun ni Àtijọ́”: “Greetings to the Nursing Mothers whose hands are always wet – Yoruba Culture of Nursing a Baby in the Old Days”

Ni ayé àtijọ́, kò si itẹdi à lò sọnù bi ti ayé òde òni.   Bẹni wọn kò lo ìgò oúnjẹ lati fún ọmọ tuntun ni oúnjẹ.

Ri rọ ọmọ - Yoruba Traditional baby feeding. Courtesy:@theyorubablog

Ri rọ ọmọ – Yoruba Traditional baby feeding. Courtesy:@theyorubablog

Ọwọ́ ọlọ́mọ tuntun ki kúrò ni omi nitori omi ni wọn fi nto àgbo ti wọn nrọ ọmọ fún ìtọ́jú ọmọ tuntun.  Aṣọ àlòkù Bàbá, Ìyá àti ẹbi ni wọn nya si wẹ́wẹ́ lati ṣe itẹdi ọmọ nitori kò si itẹdi à lò sọnú bi ti ayé òde òni.

Ọmọ tuntun a ma ya ìgbẹ́ àti ìtọ̀ tó igbà mẹwa tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ ni ojúmọ́.  Ọmọ ki i sùn ni ọ̀tọ̀, ẹ̀gbẹ́ ìyá ọmọ ni wọn ntẹ́ ọmọ si.  Lẹhin ọsẹ̀ mẹ́fà tàbi ogoji ọjọ́ tàbi ó lé kan ti wọn ti bi ọmọ, ìyá àti ọmọ lè lọ òde, ìyá á pọn ọmọ lati jáde.

Nitori aṣọ ni itẹdi kò gba omi dúró, bi ọmọ bá tọ̀ tàbi ya ìgbẹ́, á yi aṣọ ìyá tàbi ẹni ti ó gbé ọmọ.  Kò si ẹ̀rọ ifọṣọ igbàlódé nitori na a, ó di dandan ki wọ́n fọ aṣọ ọmọ àti ẹni ti ó gbé ọmọ ni igbà gbogbo ni ilé ọlọ́mọ tuntun.  Eyi ni ó jẹ́ ki Yorùbá ma ki ẹni ti ó bá ntọ ọmọ lọ́wọ́ pé “Ẹ kú ọwọ lómi” nitori ọwọ́ ki kúrò ni omi aṣọ fí fọ̀.

 

 

ENGLISH TRANSLATION

In the old days, there were no disposable diaper as common as it has become in recent times. Also, babies were not bottle fed. Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-03-04 23:03:05. Republished by Blog Post Promoter

“A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, igbin yọjú”: “Talking of animals with horns, the snail appeared”.

Ẹfọ̀n – Buffalo

Ẹfọ̀n – Buffalo Courtesy: @theyorubablog

Ọ̀pọ̀ ẹranko ti ó ni ìwo lóri, ma nlo lati fi gbèjà ara wọ́n ti ewu bá dojú kọ wọ́n.  Ni ìdà keji, ìwo igbin wà fún lati fura ninú ewu, nitorina, bi igbin bá rò pé ewu wa ni àyíká́, igbin àti ìwo rẹ̀, a kó wọ karaun fún àbò. Fún ẹranko àti igbin, ìwo ti ó le ẹranko àti ìwo rírọ̀ igbin wà fún iṣẹ́ kan naa, mejeeji wà fún àbò ṣùgbọ́n fún iwúlò ọ̀tọ̀tọ̀.  O yẹ ki igbin mọ iwọn ara rẹ̀ lati mọ̀ pé irú ìwo ohun kò wà fún ohun ijà, lai si bẹ̃, wọ́n á tẹ igbin pa. A lè lo òwe Yorùbá ti ó ni “A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, ìgbín yọjú” yi fún àwọn ẹ̀kọ́ wọnyi: a lè fi bá ẹni ti ó bá jọ ara rẹ lójú wi; aimọ iwọn ara ẹni léwu; ọgbọ́n wà ninu mi mọ agbára àti àbùkù ara ẹni; ki á lo ohun ti a ni fún ohun ti ó yẹ – bi a bá  lo ìmọ̀ òṣìṣẹ́ fún irú iṣẹ́ ti wọn mọ̀, á din àkókò àti ìnáwó kù; àti bẹ̃bẹ lọ. 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-08-23 11:48:23. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí/ẹbi a má dani” – “It is not worth dwelling on a friend’s disappointment or deceit, as such do occur from siblings/family members”.

Kò si ibi ti ẹ̀tàn  tàbi ká dani kò ti lè wá.  Ẹni ti ó bá ni iwà burúkú bi: ojúkòkòrò, ìlara àti ìmọ-tara-ẹni nikan, lè dani tàbi tan-nijẹ. Ọmọ lè tan bàbá tàbi ìyá, ìyá tàbi bàbá lè tan ọmọ, ọkọ lè da aya, ọmọ-ìyá tàbi ẹbi ẹni lè tan ni jẹ, tàbi dani, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà, èniyàn ki reti irú iwà yi lati ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́.  Nitori ifi ọkàn tàn si ọ̀rẹ́, ìbànújẹ́ tàbi ẹ̀dùn ọkàn gidi ni fún èniyàn ti ọ̀rẹ́ bá da tàbi tàn jẹ.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, “Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí/ẹbi a má dani”.  Òwe yi fihàn pé kò si ẹni ti kò lè dani tàbi tan ni jẹ, nitori “Àgbẹ́kẹ̀lé enia, asán ló jẹ́”.  A lè fi òwe yi ṣe ìtùnú fún ẹni ti irònú bá nitori ọ̀rẹ́ da a, tàbi ti ó sọ ohun ribiribi nù nitori ẹ̀tàn ọ̀rẹ́.

ENGLISH TRANSLATION

Disappointment or deception can come from anyone or anywhere.  Anyone with bad character such as: Greed, envy and selfishness, can disappoint or deceive others.  Disappointment or deceit could come from children to parents, mother or father to children, husband to wife or vice versa, or from siblings or family members, but most times, people never expected such from friends.  As a result of placing great confidence in a friend, it often causes sorrow or depression for people that are disappointed or deceived.

According to the Yoruba adage that said “It is not worth dwelling on a friend’s disappointment or deceit, as such do occur from siblings/family members”. This proverb showed that anyone could disappoint or deceive because “Trust/confidence in people is vanity”.   The adage can be used to console or comfort those that are depressed as a result of friend’s disappointment or those who have incurred losses as a result of a friend’s deceit.

Share Button

Originally posted 2014-10-28 19:45:27. Republished by Blog Post Promoter

Ohun gbogbo ki i tó olè: Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú – Nothing ever satisfies the thief: African Leaders/Politicians

Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú African Union leaders

Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú African Union leaders

Kò si oye ọdún ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lè lò ni ipò ti wọn lè gbà lẹ́rọ̀ lati kúrò.  Bi àyè bá gbà wọn, wọn fẹ kú si ori oyè.  Bi a bá ṣe akiyesi ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Òkè-Òkun, bi àwọn ará ilú bá ti dibò pé wọn kò fẹ́ wọn nipa yin yan ẹlòmíràn, wọn yio gbà lẹ́rọ̀, lati gbé Ìjọba fún ẹni tuntun ti ará ilú yan, ṣùgbọ́n kò ri bẹ ẹ ni Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú.

Ohun ti ó jẹ́ ki àwọn Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fẹ́ kú si ipò pọ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olóri Òṣèlú Nigeria, ki ba jẹ ti Ìjọba Ológun tàbi Alágbádá, kò si ẹni tó mọ bàbá wọn ni ilú, ṣùgbọ́n wọn kò kọ́ ọgbọ́n pé ọ̀pọ̀ ọmọ ti wọn mọ bàbá wọn ni àwùjọ kò dé ipó nla ti àwọn dé.  Ó ṣe é ṣe ki ó jẹ́ wipé ìbẹ̀rù iṣẹ́ ti ó ṣẹ́ wọn ni kékeré ló jẹ́ ki wọn ni ojúkòkòrò lati fi ipò wọn ji owó ilú pamọ́ fún ara wọn, ọmọ àti aya wọn nitori ìbẹ̀rù iṣẹ́.  Kò si oye owó ti wọn ji pamọ́ ti ó lè tẹ́ wọn lọ́rùn, eyi ló fa ìbẹ̀rù à ti kúrò ni ipò agbára.  Ìbẹ̀rù ki ẹni ti ó bá má a gba ipò lọ́wọ́ wọn, ma ṣe ṣe iwadi wọn na a pẹ̀lú, nitori wọn ò mọ̀ bóyá yio bá wọn ṣe ẹjọ́ lati gba owó ilú ti wọn ji kó padà.

Kàkà ki ilú gbérí, ṣe ni ọlá ilú nrẹ̀hìn.  Bi Òsèlú bá ji owó, wọn a ko ọ̀pọ̀ owó bẹ́ ẹ̀ lọ si Òkè-Òkun tàbi ki wọn ri irú owó bẹ́ ẹ̀ mọ́lẹ̀ lóri ki kọ ilé ọ̀kẹ́ aimoye ti ẹni kan kò gbé.  Ọ̀pọ̀ owó epo-rọ̀bì ló wọlé, ṣùgbọ́n àwọn Òṣèlú àti àwọn olè bi ti wọn njẹ ìgbádùn nigbati ará ilú njìyà.   Lára ìpalára ti ji ja ilú ni olè fa, ni owó Nigeria (Naira) ti ó di yẹpẹrẹ, àwọn ọdọ kò ri iṣẹ́ ṣe, àwọn ohun amáyé-dẹrùn ti bàjẹ́ tán, oúnjẹ wọn gógó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ohun gbogbo ki i tó olè” fi àlébù ojúkòkòrò, ifẹ́ owó, àti à ṣi lò agbára han ni ilú, pàtàki ni Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-20 09:15:08. Republished by Blog Post Promoter

“A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” – “One does not acknowledge one’s child husband and also acknowledge her illicit affair”

Igbéyàwó ibilẹ̀ - Traditional marriage

Igbéyàwó ibilẹ̀ – Traditional marriage

Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nitori Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò.  Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn.  Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún meji-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé.

Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ̃ han òbi.  Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá?  Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-08 23:02:45. Republished by Blog Post Promoter

“Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó gun Ori Oyè ilu Àkúrẹ́” – “New Deji of Akure ascends the Throne”

Déjì Àkúrẹ́ Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó pari gbogbo ètùtù ibilẹ ti Ọba Àkúrẹ́ ma nṣe lati gori oyè ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, lati di Ọba Kejidinlãdọta ilú Àkúrẹ́ ni ipinlẹ̀ Ondó ti ila-oorun orilẹ̀ èdè Nigeria.

img_20150708_221218-resized-800

Ọba Àkúrẹ́ gun Òkiti Ọmọlóre – The New King of Akure completed the traditional rites

 

 

 

 

 

 

 

 

Kí kí Ọba ni èdè Àkúrẹ́ – Congratulatory message to the new King in Akure Dialect

Kábiyèsi, Ọba Aláyélúà, wo kú ori ire o
Ẹbọ á fín o Àbá
Adé á pẹ́ lóri, bàtà á pẹ́ lọ́sẹ̀ o
Ùgbà rẹ á tu ùlú Àkúrẹ́ lára (Àṣẹ)

ENGLISH TRANSLATION

The Monarch of Akure, Deji Aladelusi Ogunlade-Aladetoyinbo has completed the all the traditional rites required to ascend the throne and was crowned on Wednesday, July eight, Two Thousand and Fifteen to become the forty eight Monarch of the Ancient City of Akure, Ondo State in Western Nigeria.

The Yoruba Blog Team sent Congratulatory Message in Akure dialect.

 

Share Button

Originally posted 2015-07-14 20:44:41. Republished by Blog Post Promoter

Iwé-àkọ-ránṣẹ́ ni èdè Yorùbá – Letter writing in Yoruba Language

Ni àtijọ́, àwọn ọmọ ilé-iwé ló ńran àgbàlagbà ti kò lọ ilé-iwé lọ́wọ́ lati kọ iwé, pataki ni èdè abínibí.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn iwé-àkọ-ránṣẹ́ wọnyi ni ojú iwé yi:

Ìwé ti Ìyá kọ sí ọmọ

Èsì iwé ti ọmọ kọ si iyá

Iwé ti ọkọ kọ si iyàwó

Èsi iwé ti aya kọ si ọkọ

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-03-11 01:14:25. Republished by Blog Post Promoter

A Dúpẹ́ fún Ẹyin Àyànfẹ́ tó Bẹ̀rẹ̀ sí Tẹ̀léwa ní Twitter: Thank You to Our New Twitter Followers

Twitter followers

Twitter followers

Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì: Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION

Watch out weekly for postings on: application of Yoruba Proverbs, posts to help you learn Yoruba, folklore, news that we can learn lessons from, stories about the Yoruba community and food in London, New York, Chicago, Orlando etc.  Join us to ensure that the Yoruba language is not extinct by writing and reading Yoruba on the Internet.

Thanks so much, The Yoruba language will not be destroyed by the power of God and our collective efforts (Amen).

 

Share Button

Originally posted 2013-05-17 02:06:24. Republished by Blog Post Promoter